Oduduwa Republic: Ẹgbẹ́ YOVOLIB ní ìjọba kò gbọdọ̀ gbé Gani Adams àti Banji Akitoye

Awọn eeyan to n se iwọde

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki

Awọn eeyan to n pe fun idasilẹ orilẹede olominira Oduduwa ti kọ iwe ẹhonu lọ sọdọ ajọ isọkan agbaye, United Nations, UN.

Bakan naa ni wọn tun fi iwe naa sọwọ si ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, EU, ajọ isọkan ilẹ Afirika, Au, ijọba ilẹ Gẹẹsi , ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan atawọn gomina to wa nilẹ Yoruba pẹlu ipinlẹ Kogi ati Kwara.

Koko ohun ti wọn n beere fun ninu iwe ẹhonu naa ni pe ki aabo to peye wa lawọn ipinlẹ to wa nilẹ Kaarọ oojire.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan naa si lo wa labẹ aburada ẹgbẹ kan to n sọrọ fun ominira ilẹ Yoruba, ti wọn pe ni Yoruba Voice Liberation (YOVOLIB).

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki

Ẹgbẹ YOVOLIB wa fewe ọmọ mọ ijọba apapọ lorilẹede Naijiria leti lati mase gbe awọn asaaju to n ja fun ominira ilẹ Yoruba bii Aarẹ Ọna Kakanfo, Iba Gani Adams.

Bakan naa lo tun ni mimi kankan ko gbọdọ mi Aarẹ apapọ fun ọmọ Yoruba lagbaye, Yoruba World Congress, YWC, Ọjọgbọn Banji Akitoye pẹlu awọn eeyan miran.

Iwe ẹhonu naa ni ti ijọba Naijiria ba fi ọwọ kan awọn asaaju Oodua pẹrẹ, wọn yoo gburo awọn.

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki

Bakan naa ni wọn n ke si aarẹ Muhammadu Buhari lati se ohun mẹrin ti yoo mu ki Naijiria bọ lọwọ idẹyẹsi ati ifiyajẹni lagbaye.

Aarẹ ẹgbẹ YOVOLIB nilẹ United Kingdom, Ọmọwe Adekunle Ogunmola tun rọ awọn awujọ agbaye lati sọ fun ijọ Buhari pe ko ye lo ọta ibọn lati tako awọn eeyan to n se iwọde ni Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Yomi Fabiyi: Fíìmù ‘Owó orí ẹlẹ́wọ̀n’ jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà ìpọ́njú làá mọ ọ̀rẹ́

"O yẹ ki ijọba bọwọ fun ẹtọ araalu lati fi ero wọn han sita, ko si dẹkun hihu iwa ipa si awọn eeyan to ba n se iwọde.

Ojuse awọn agbofinro ni lati tọpinpin iwọde to ba n waye, ki wsn si ri pe alaafia jọba lasiko naa, amọ eyi ko ri bẹẹ ni Naijiria."

Olùwọ́de ogójì kó sí panpẹ́ ọlọ́pàá ní ìlú Eko

Ko din ni ogoji awọn oluwọde lati ẹgbẹ Save Nigeria Group to ti ko si panpẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko bayii lẹyin ti wọn tapa si aṣẹ kọmiṣona ọlọpaa ipinlẹ ọhun lodi iwọde.

Awọn agbofinro mu awọn oluwọde naa lagbegbe Ojota ati Maryland nigba ti wọn n gbiyanju lati tu awọn eeyan naa ka.

Ni agbegbe Maryland yii kan naa ni awọn ọlọpaa ti tu awọn olufẹhonuhan kan ka labẹ asia ẹgbẹ #RevolutionNow to n pe fun ayipada si iṣejọba Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni awọn agbofinro tu awọn to n ṣe iwọde pe ki ẹya Yoruba da yatọ ni Naijiria ka ni Alausa.

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti kọkọ fofin de iwọde ni ọjọ kini, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ninu atẹjade to fi ṣowọ si awọn akọroyin.

Ṣugbọn awọn eeyan ni kii ṣe akoko niyii lati fidi mọle nitori bi nnkan ṣe n lọ ni Naijiria ko dara to, ko si si ohun miran ti wọn lee ṣe ju ki wọn erongba lede fun ijọba nipa ifẹhonuhan.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Revolution Now: Ìwọde tó ń tako ìjọba gbérasọ nílúù Eko

Iwọde lati tako ipo ti Naijiria wa gbera nilu Eko

Ikọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan to n jẹ Revolution Now ti bẹrẹ iwọde kaakiri ilu Eko.

Iwọde naa lo gbera ni aago mẹwa aarọ, ti ọpọ ero si n wọ kiri oju popo.

Oniruuru akọle ni awọn oluwọde naa gbe lọwọ ninu eyi ti wọn ti n tabuku ijọba to wa lode ni orilẹede Naijiria.

Bakan naa ni wọn koro oju si iwa ijẹgaba, ifiyajẹni ati airisẹse awọn ọdọ ni Naijiria.

Oniruuru orin to tako ijọba ẹgbẹ oselu APC si ni wọn fi sẹnu, eyi to n tabuku ijọba ati oloselu Naijiria.

Ọpọ awọn oluwọde naa lo de fila alawọ ọsan, tii se awọ idamọ ẹgbẹ Revolution Now.

Koda, awọn oluwọde naa ko bẹru awọn agbofinro to duro go go go soju popo lati dena iwọde naa.

Awọn agbofinro naa si lo safihan pe awọn korira awọn ẹgbẹ oselu to wa ni Naijiria, nitori bi wọn se n kọrin eebu mọ awọn oloselu latinu ẹgbẹ APC, naa ni wọn ko yọ tẹgbẹ PDP silẹ.

Wọn ni gbogbo wọn ni wọn lọwọ si bi orilẹede Naijiria se wa yii.

Awọn oluwọde naa ni wọn ni awọn fẹ ayipada si awọn adari to n se ijọba lọwọ ni Naijiria, ti wọn si n fẹ ki iyipda wa.

Lara awọn adugbo ti wọn si se iwọde de ni adugbo Ojọta, Berger, Ikeja ati bẹẹ bẹẹ lọ.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.