Sunday Igboho: Sé èmi nìkan ló wà ní Nàíjíríà ni, ó lé ní 1m ọlọ́pàá tó yí ilé mi po

Àkọlé fídíò,

Yoruba Independence rally: Sunday Igboho ní àwọn àgbàgbà Yoruba dalẹ̀

Ẹ̀yin tẹ dà wá, tẹ sálọ fún ìwọ́de, ilẹ̀ Yorùbá yóò bi yín - Sunday Igboho bínú

Ilumọọka ajafẹtọ ẹni kan nilu Ibadan Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho se amusẹ ileri rẹ lati se iwọde lọjọ ominira.

Bẹẹ ba gbagbe, o ti to ọjọ mẹta bayii mẹta ti ikede ti n lọ pe Sunday Igboho yoo ko awọn eeyan kan sodi, lati se iwọde fun ominira ilẹ Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki

Ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan, lo se afihan Sunday Igboho ati awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ miran nilẹ Yoruba, ti wọn kora jọ siwaju ile Igboho, pẹlu asọ ẹgbẹ Yoruba ati akọle lọwọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nibẹ si ni wọn ti n pariwo pe awọn ọlọpaa atawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, n di awọn lọwọ lati se iwọde, bẹẹ ni awọn agbofinro naa n yẹ ara awọn eeyan to peju sibẹ wo, boya wọn gbe ohun ija oloro lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki

Nigba to n sọrọ nibi ipejọpọ naa, Sunday Igboho koro oju si bi ọpọ eeyan, to n leri leka tẹlẹ, se sa sẹyin lati bawọn peju se iwọde naa.

O ni o se oun laanu fun awọn ọmọ Yoruba pe, wọn ko le duro sori ọrọ ti wọn ba sọ lai jẹ è wọn wa ni oko ẹru.

"A ni a fẹ se iwọde alaafia lati beere ẹtọ wa lọwọ ijọba Naijiria, kii se pe a fẹ ja, kii se pe a fẹ da ilu ru tabi gba ijọba, wọn wa ko ọlọpaa bii miliọnu kan ati Sọja pẹlu ọtẹlẹmuyẹ si gbogbo ọna ile mi.

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki

Se emi nikan ni ọmọ Naijiria ni, se emi nikan ni ọmọ Yoruba ni? Gbogbo awọn ọmọ Yoruba yoku wa salọ.

Gbogbo ẹyin tẹ jẹ baba wa, tẹ wa lọ fi wa gba owo, gbogbo ẹyin tẹ jẹ ẹgbọn wa, ẹ salọ, o yẹ kẹ ronu ẹyin Yoruba, sugbọn awa fidi rẹ mulẹ pe, ọmọ ọkọ lawa.'

Sunday Igboho ni o yẹ kawọn baba Yoruba naa bẹru Ọlọrun, ilẹ Yoruba yoo si bi gbogbo wọn, awọn alalẹ yoo si bi gbogbo awọn to salọ.

Àkọlé fídíò,

Goitre Patients: Àwọn èèyàn tó ní àrùn gẹ̀gẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìkórira àti ìdẹ́yẹsí ní àwọn ń kojú

O ni oun ti se iwọn ti oun le se, amọ ti wọn ba setan fun irẹpọ Yoruba, ki wọn ke si oun, to si n beere pe se o dara bi awọn ajeji se n fi oju Yoruba gbolẹ nilẹ baba wọn.

Igboho wa fi ọwọ gbaya pe, bi okunkun pẹ titi, imọlẹ yoo tan, laipẹ laijinna, ominira yoo si tẹ ilẹ Yoruba lọwọ.

Àkọlé fídíò,

October 1 Celebrant: Atinuke Oladeru ni kẹ yé ṣépè fún Nàíjíríà mọ́, ẹ pa ohùn dà