Nigeria Independence Day: Aráàlú fa ìbínú yọ lórí ọ̀rọ̀ tí Buhari sọ fún àyẹyẹ òmìnira

Awọn ipo ti ko dara ti Naijiria wa

Oríṣun àwòrán, @Xahraddeen_

Aarẹ Muhammadu Buhari tí bá àwọn ọmọ Naijiria sọrọ, bi orile-ede yii se n se ayẹyẹ ominira ọgọta ọdun.

O mẹnuba oniruuru awọn nnkan to n ba orile-ede yii fira to si pe fun ifaraji, ifẹ ọmọlakeji ati igbara ẹni niyanju láti máa ṣe nkan to tọ.

Lẹyin ti aarẹ Muhammadu sọrọ tan, ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti n fi ero wọn han lawọn oju opo ibaraẹnidọrẹpọ loju opo itakun agbaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Odeh ninu atejisẹ rẹ soju opo Twitter ni, ki aarẹ ranti pe ko si nkan iwuri kankan ninu ayẹyẹ ominira ọgọta ọdun ti Naijiria.

O ni ko si itẹsiwaju kan bikose pe nkan ń buru sii ni.

Ninu ọrọ tirẹ @fingertrickz ni ọna àbáyọ kan ṣoṣo to yẹ, ni kí ijọba din owo awọn ọmọ ile ìgbímọ asofin ku, ti awọn miran si n fẹdun ọkan wọn han lori ọrọ airiṣẹse, lẹyin ọpọ ọdun ti wọn ti jade ile iwe.

Lori ọrọ iye ti awọn orile-ede miran to ni epo rọbi n ta epo bẹtiro fun ara ilu aarẹ ni

Egypt ₦211

Saudi Arabia ₦168

Chad ₦362

Niger ₦346

Ghana si n ta ni ₦326, ti Naijiria si ti n taa ni ₦161 báyìí.

Àkọlé fídíò,

Goitre Patients: Àwọn èèyàn tó ní àrùn gẹ̀gẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìkórira àti ìdẹ́yẹsí ní àwọn ń kojú

Ọpọ ọmọ Naijiria lo gbana jẹ lori eyi pe, ko tọ ki aarẹ maa fi owo epo Saudi we tí Naijiria nitori anfani ti Saudi n jẹ lati ọdọ ijọba ko ni afiwe, si iya ti ijọba Naijiria fi n jẹ ara ilu .

Ẹlomiran tiẹ n beere pe elo ni owo osu osisẹ ni Naijiria ati ti Saudi, Ghana, Chad, Egypt.

Gbajugbaja akoroyin ni Naijiria, Fisayo Soyombo ni ibanujẹ ni ọjọ oni nitori ọrẹ oun ti awọn ajinigbe jigbe ti pe ọjọ meji ni akamọ wọn.

O ni o jẹ nkan itiju pe iru iṣẹlẹ yii n waye ni orile-ede to ti pe ọgọta ọdun, ijọba ko le pese nnkan tó ṣe koko lara nnkan ti ara ilu nilo, eyi to jẹ aabo to peye.

Ibeere ti Thomas Ibu ni tirẹ ni pe, ajọyọ kini Naijiria n ṣe gan-an?

Ṣe ti owo epo to wọn gogo ni? Tabi ti ọrọ ina mọnamọna to lọ soke ni? Ijinigbe gbogbo ati ipaniyan jakejado Naijiria, ṣe ti ainiṣẹ lọwọ awọn ọdọ ni abi kini gan-an.?

Ọpọ loju opo twitter lo ń beere ibere yii bakan naa pe, ki ayẹyẹ ti a n se gan-an?

Ẹnikan ni orile-ede ti a n ṣe ayẹyẹ rẹ yii, kii se eyi to yẹ wa.

Ọgọta ọdun, ikuna isejọba ati ajẹbanu.

Àkọlé fídíò,

October 1 Celebrant: Atinuke Oladeru ni kẹ yé ṣépè fún Nàíjíríà mọ́, ẹ pa ohùn dà

Ọgọta ọdun eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Ọgọta ọdun ninu gbigbọkan le epo rọọbi nikan ati aini isokan laarin awọn ẹya rẹ.

Buhari, iye owó oṣù tí wọ́n ń san ni Saudi kọ́ ní wọ́n ń san ní Naijiria, má fi wá wé ara - Femi Falana

Oríṣun àwòrán, @perlikspictures

Amofin agba ati ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana ti sọ fun BBC pe ominira ti Naijiria n ṣajọyọ rẹ kii ṣe ominira rara, bikoṣe omi inira.

Falana ni ọrọ ti Aarẹ Buhari sọ nipa owo epo nigba to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ ko bojumu to, ati pe ko lẹtọọ ki Aarẹ maa ṣafiwe igbe aye awọn ọmọ naijiria si ti awọn eeyan Saudi Arabia.

O ni "Ọrọ aje orilẹ-ede wa ko ṣe dede nitori awọn to n ṣelu ko gbọ eyii ti awọn ara ilu n ṣe bikoṣe eyii ti ajo IMF ati banki agbaye ba sọ."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amofin agba naa sọ pe itan ati afarawe iye ti wọn n ta epo ni Saudi Arabia ati Egypt ko kan awọn ara ilu lasiko yii, bikoṣe pe ki aijọba sọ fun wọn bi igbe aye wọn yoo ṣe gbe pẹẹli ju ti atẹyinwa lọ.

Falana ni ti Aarẹ Buhari ba fẹ ṣe afiwe, ni ṣe lo yẹ ko bẹrẹ lati owo oṣu to kere ju ti awọn ọmọ orilẹ-ede Saudi Arabia n gba si ti Naijiria ko to sọrọ nipa iye ti wọn n san fun owo epo.

O ni "Ọfẹ ni owo ile iwe ati eto ilera ni Saudi, bakan naa ni ile iwe Ghana dara ju ti Naijiria lọ, idi ree ti awọn ọmọ ilẹ yii ṣe n kẹkọọ lọhun.

Falana pari ọrọ rẹ pe o yẹ ki ijọba wo iru iya to n jẹ awọn ara ilu, ko si wa ọna abayọ sii ko to maa ṣafiwe iye owo epo.

Ẹwẹ, nigba to n da si ọrọ naa, akọwe ẹgbẹ Afenifere, Yinka Odumakin ni bo tilẹ jẹ pe o ti pe ọgọta ọdun ti Naijiria gba ominira kuro loko ẹru ijọba ilẹ Gẹẹsi, inu oko ẹru naa ṣi ni awọn ọmọ Naijiria wa sibẹ.

Oríṣun àwòrán, @TVCconnect

O ni bo tilẹ jẹ pe o ti pe ọgọta ọdun ti Naijiria gba ominira lọwọ ijọba amunisin oyinbo alawọ funfun, abẹ ijọba amunisin abẹ ile ni Naijiria wa sibẹ.

Odumakin sọ pe Naijiria ti di ilu to n ba aye awọn ọmọ onilu jẹ, eyii to mu ki ọpọ eeyan maa funrere pe ki Naijiria tu ka.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni Naijiria ko ni ilọsiwaju kankan to lamilaaka lati ọgọta ọdun sẹyin.

O tẹsiwaju pe "Ina Naijiria n jo ajorẹyin ni, nitori ko si olori tuntun kankan to jẹ nilẹ yii ti asiko rẹ ko buru ju ti ẹni to jẹ ṣaaju rẹ lọ."

Bo tilẹ jẹ pe Odumakin sọ pe Afẹnifẹre ko fẹ ki Naijiria tu ka, ṣugbọn o ni erongba ẹgbẹ ọhun ni ki atunto de ba eto ijọba Naijiria.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Buhari Independence Live Broadcast: Wo àwọn kókó tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí ààrẹ bá ọmọ Nàíjíríà sọ

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe, kii ṣe Naijiria ni epo rọbi ti wọn ju lagbaye nitori epo wọn ni awọn orilẹ-ede kan bii Ghana ati Niger ju Naijiria lọ.

Buhari lo kede bẹẹ nigba to n bawọn ọmọ Naijiria sọrọ laarọ ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, fun ajọyọ ọgọta ọdun ti Naijiria gba ominira lọwọ oyinbo alawọ funfun.

Bakan naa lo fi kun pe, owo epo Naijiria lo si dinwo julọ lẹkun iwọ oorun Afirika nitori N326 ni wọ́n ń ta jáálá epo ní Ghana, N211 ní Egypt, ní ìgbà tó jẹ́ N168 ní Saudi Arabia.

Aarẹ wa woye pe, kò mú ọpọlọ lọ́wọ́ kí owó epo bẹntiróòlù ní Nàìjíríà dinwo ju ti orilẹede Saudi Arabia lọ.

Oríṣun àwòrán, @misspetitenaija

Awọn koko to wa ninu ọrọ ti aarẹ Buhari bawọn ọmọ Naijiria sọ ree:

 • Afojusun ijọba mi ni lati ri pe abo wa lori ẹmi ati dukia awọn ọmọ Naijiria, ṣugbọn ijọba ko lee da iṣẹ naa ṣe, lai si atilẹyin awọn ara ilu.
 • Aarẹ Buhari rọ awọn ọmọ Naijiria lati fọwọ sowọpọ pẹlu ijọba fun iṣokan Naijiria
 • O ni "Naijiria kii ṣe orilẹ-ede fun Aarẹ tabi ẹgbẹ oṣelu to wa lori alefa nikan ṣoṣo, ṣugbọn o wa fun gbogbo wa lapapọ, nitori naa ni a ṣe gbọdọ fi imọ ṣọkan"
 • O ṣoro lati maa ṣafikun owo epo bẹntiro lasiko yii, koda epo awọn orilẹ-ede to yi wa ka bii Ghana ati Niger wọn ju tiwa lọ
 • Oriṣirisi eto ni a ti gbe kalẹ fun igbeleke eto ọrọ aje wa, bii Tradermoni ati Farmermoni, ounjẹ ọfẹ fun awọn ọmọ ile iwe, ipese iṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ
 • Gbogbo awọn to ti ba Naijiria jẹ lati ọdun 1999 si 2015, ko yẹ ko lẹnu ọrọ lati bu ẹnu atẹ lu akitiyan wa
 • Nitori pe owo epo ja silẹ ni iwọn ida ogoji, owo ti ijọba n ri loṣooṣu ti dinku ni ida ọgọta
 • Bakan naa ni adinku de ba owo ipamọ Naijiria nilẹ okeere ti a ni, nitori ajakalẹ arun Coronavirus to kọlu gbogbo agbaye
 • Gbogbo ọmọ Naijiria gbọdọ tẹle ofin nipa titapa si awọn iwa ọdaran ati iwa jẹgudujẹra
 • O dara ki orilẹ-ede yii wa ni iṣọkan, ju ki a pin yẹlẹyẹlẹ lọ nitori itan ti fi han wa pe, a jẹ eeyan to lee gbe papọ ni alaafia
 • Mo ni igbagbọ ninu eto idibo ti ko ni oju-ṣaaju ninu, gẹgẹ bi ẹyin naa ṣe ri i ninu isejọba mi bii Aarẹ alagbada
 • Awọn iṣoro ti a n koju ninu idibo wa lati ọwọ wa, nitori naa, a ni lati yii erongba wa pada lori bi eto idibo ṣe yẹ ko lọ
 • Ẹ jẹ ki a pinnu lati jọ maa gbe pọ gẹgẹ bi ọmọ iya kan
 • Ko si ijọba to kọja ṣẹyin, to tii ṣe iru aṣeyọri ti a ṣe yii pẹlu iwọnba owo perete ti a n ri
 • Lọwọ yii, N161 ni a n ta lita epo kan, N362 ni Chad n ta ti ẹ, N211 ni Egypt, ti Niger si n ta tirẹ ni N346
 • Ireti mi ni pe ti yoo ba fi di iwoyi ọdun to n bọ, inu wa yoo dun pe a pinnu lati jẹ oṣuṣu ọwọ
 • Ki Ọlọrun o bukun Naijiiria. Ẹṣe pupọ.