Ondo Governorship Elections 2020: Ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta yìí ní yóò sọ ẹni tí yóò jáwé olúbori ninú ìdìbò Ondo

Ondo Governorship Elections 2020: Ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta yìí ní yóò sọ ẹni tó jáwé olúborin ninú ìdìbò Ondo

Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọjọ́ ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo yóò wáyé lọ́jọ́ Satide ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá ọdún 2020, ibi yìí ni àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà yóò fi ọwọ́ ara wọn yan ẹni tí yóò tún dári wọ́n fún ọdún mẹ́rin míran.

Àwọn olùdíje dùpò lábẹ́ ẹgbẹ̀ òṣèlú kọ̀ọ̀kan yẹ ki wọ́n ni ìbò tó jọju láti ìjọba ìbílẹ̀ méjìdílógún tó wà ni ìpińlẹ̀ náà ti yóò gbéwọn dé orí àléfà.

Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó wà ni ìpínlẹ̀ náà ni Akoko North East, Akoko North West, Akoko South East, Akoko South West, Akure North, Akure South, Ifedore, Ile Oluji/Okeigbo, Ondo East, Ondo West, Owo, Ilaje, Okitipupa, Ose, Odigbo, Ese Odo, Idanre àti Irele.

Ṣùgbọ́n ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta tó tóbi jù kan ni àwọn ènìyàn fójú sí nítorí ìtàn ìdìbò àgbègbè náà látẹ́yín wá. Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yìí ni yóò sọ ẹni ti yóò jáwé olúbóri.

Akure South

Ìjọba ìbílẹ̀ Akure South ló tóbi jùlọ ní ìbílẹ̀ Ondo tí wọ́n sì ní ènìyàn tó dín díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rùn okòó-lé-lẹẹ́dẹ̀gbẹ̀ta ti eniyàn oòkó-dín-lọ́ọ̀dúnrún si fọ́rúkọ sílẹ̀ fún ìdìbò.

Lásìkò ìdìbò ọdún 2016, ìjọba ìbílẹ̀ náà fún gómìnà tó wà lórí àléfà Rotimi Akeredolu ni ìbò tó dín díẹ̀ ni ẹgbẹ̀rún mẹ́rrìndílọ́gbọ̀n, èyí ló ga jùlọ ní gbogbo àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó kù.

Ní ọdún 2012, ìjọba ìbílẹ̀ yìí kan náà ló fún olùdíje dupò lábẹ́ ẹgb òṣèlú Labour Olusegun Mimiko láti wọlé fún sáà kejì, o rí ìbò tó dín díẹ̀ ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́ta.

Ní ọdún 2020, ìjóba ìbílẹ̀ yìí ni yóò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, ẹni ti yóò jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bi gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo

Ẹ̀wẹ́, ìjọba ìbílẹ̀ yìí gan ni olùdíje dupò lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party, (PDP) Eyitayo Jegede ti wá.

Àwọn ibudó ìdìbò ẹdẹ́gbẹ̀ta àtí mọ́rùndílógójì tó ti wà ni ìpińll Ondo láti ẹyìn wá ti fi hàn pé, PDP àti APC yóò jọ jàdu ìbò ní ìjọba ìbílẹ̀ yiìí ni.

Ondo West

Lẹ́yìn ìjọba ìbílẹ̀ Ilajẹ ìjọba ìbílẹ̀ Ondo West lo tún kan, èyí sí ni ìjọba ìbílẹ̀ kẹ̀ta to tóbi jùlọ ní ìpínlẹ̀ Ondo. Ènìyàn ẹgbẹ́rún lọ́nà ààdójọ ni olùdìbò tó ti fórúkọ sílẹ̀.

Àwọn ènìyàn ìjọba ìbílẹ̀ yìí pẹ̀lú jẹ ọkàn lára àwọn tí yóò sọ ẹni tíò jáwé olúborí.

Nínú ìtàn ìpińlẹ̀ yìí pẹ̀lú, wọ́n sábà má ń wò ó bóyá ọkàn lára àwọn olùdíje dupò wá láti ìjọba ìbílẹ̀ náà.

Ṣùgbọ́n ni àsìkò yìí ìjọba ìbílẹ̀ yìí ni Olusegun Mimiko ti wá tí ó sì wà lẹ́yìn ọkàn lára àwọn olùdíjẹ lábẹ́ Zenith Labour Party (ZLP) Agboola Ajayi.

Bóya àwọn ènìyàn wọ́nyìí yóò wá dúró sẹ́yìn ọmọ wọ́n ni sáá yií, àwọn náà yóò sọ ẹni ti yoo jáwé olúbori.

Ìjọba ìbílẹ Owo

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ìjọba ìbílẹ̀ Owo ló ni Gómìnà tó wà lórí àléfà nínú ọdún 2020.

Gómìnà Rotimi Akeredolu ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó tún jẹ gómìnà tó wà lórí oye jẹ́ ọmọ ìjọba ìbílẹ̀ náà.

Owo ni ibudó ìdìbò ìgbà àtí mẹ́rìnlélọ́gọ́ta tí wọ́n si ni ènìyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà dín díẹ̀ tó ti fi orúkọ sílẹ̀ fún ìdìbò tó n bọ.

Gbogbo ènìyàn ni yoo maa fi oju si ìjọba ìbílẹ̀ yìí lára nítori pé, ọ̀pọ̀ ló ní ìgbàgbọ́ pé, "ọmọ wa ni ẹ jẹ kó ṣee" ni wọ́n yoo fi ṣe.

Bí wọ́n ko bá wa dibo fun ọmọ wọ́n, ẹnikẹni ti ọ̀pọ̀ wọ́n bá gbà láti dibò fún ni yóò jáwé olúbori fún ìdìbò náà.

Ǹkan míràn tó tún lé yí ǹkan padà ni pé, tí gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mẹẹ̀dógún tó kù bá wá pinu láti gbárùkù tí ẹni kan nínú àwọn olùdíje yìí, láti bórí àwọn Ijọba ìbílẹ̀ mẹ́ta tó kù.

Ṣùgbọ́n ni ọ̀pọ̀ ìgbà ọwọ́ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta yìí ni ọ̀rọ̀ wà.

Ondo Governorship Elections 2020: INEC ní ìjọba ìbílẹ̀ Ilaje ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú jùlọ tí wáyé nínú ìbò 2016

Lára ìgbésẹ̀ ìjọba láti le ri i dájú pé ètò ìdìbò lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ondo, àjọ elétò ìdìbò (INEC) ní òun ti bèèrè fun iranwọ àwọn ilé iṣẹ́ elétò ààbò to pọ.

Ó ní àwọn ọmọ ológun, àwọn ọlọpàá àti àjọ elétò ààbò gbogbo yóò wà láwọn ibi kọ́lọ́fín, ti gbogbo àwọn ẹni ibi maa n fara pamọ́ sí.

Bakan naa ni INEC ni àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò náà yóò ri i dájú pé, ìdìbò ti kò mú wàhálà dání, pàápàá jùlọ láwọn iha kọ̀ọ̀kan ni ìpínlẹ̀ náà lo waye lọjọ Kẹwaa osu Kẹwaa ọdun yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

INEC ní o tó àwọn ilé orí omi bíi méjìlélọ́gọ́ta àti ibudó ìdìbò ọ̀rinlérúgbà ó din mẹ́wàá to wa ni agbègbè ẹsẹ̀ odò, tawọn oju omi tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti mẹ́sàn sì wà ni ìpinlẹ̀ náà.

Bẹ́ẹ ni àwọn òṣìṣẹ́ tí yóò lọ ṣiṣẹ́ nibẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rin.

Kọmísọ́nà àjọ INEC, tó tún jẹ́ alága ìròyìn àti ìtanijí Festus Okoye ni àwọn ti kàn si ilé iṣẹ́ ọmọogun ojú omi àti àwọn ọlọpàá inú omi, láti sin àwọn èròjà tí wọ́n yóò lò fún ìdìbò lágbègbè náà.

Saájú àsìkò yìí, o ni àwọn àgbègbè eti odò náà fi han pé, màgòmágó le ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, nítorí bi ibẹ̀ ṣe rí.

Oríṣun àwòrán, Others

Okoye ní láti le ri dájú pé, ètò ìdìbò lọ ni irọwọ́rọsẹ̀, àjọ INEC ti kan sí ọlọpàá ojú omi, àwọn ọmọogun ojú omi àti àwọn ilé iṣẹ́ ààbò tó farapẹ láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

Àwọn ibudó ìdìbò ọ̀rinlérúgbà ó din mẹ́wàá to wa ni agbegbe omi yii, ló wà ni ìjọba ìbílẹ̀ Ese-Odo àti ilaje, ti wọ́n si ni àwọn ilé orí omi bíi méjìlélọ́gọ́ta.

Àkọlé fídíò,

Yomi Fabiyi: Fíìmù ‘Owó orí ẹlẹ́wọ̀n’ jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà ìpọ́njú làá mọ ọ̀rẹ́

Ẹ̀wẹ̀, sáájú ni àdàri ètò àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba YIAGA, Cynthia Mbamalu ti kéde pé, pẹlú àwọn ìrírí nínú ìdìbò 2016, ìjọba ìbílẹ̀ Ilaje ní àwọn ìròyìn to buru ju ti n wá.

Ó ní láti ri dájú pé ìdìbò yìí kò dàbí àwọn èyí tó ti ṣẹ̀lẹ̀ láti ẹyìn wá, àjọ elétò ìdìbò gbọdọ pèsè ètò ààbò tó péye ni àwọn ibùdó ìdìbò tó wà ní eti omí, lásìkò tí wọn bá n pín nǹkan ìdìbò àti lásíkò ìdìbò gan.

Ẹ fura, làásìgbò le wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà yìí lásìkò ìbò gómìnà Ondo - YIAGA

Oríṣun àwòrán, Nguher Gabrielle Zaki

Awọn ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ti ke gbajare si awọn alaṣẹ lati dena jagidijagan ati awọn iwa kotọ mii, to le waye lasiko idibo Gomina to n bọ nipinlẹ Ondo.

Ninu iwadii ti ajọ YIAGA gbe jade ṣaaju idibo, eyi ti wọn fi ṣọwọ ṣawọn akọroyin, wọn darukọ awọn ijọba ibilẹ mẹfa ti iwa ipa ti le waye lasiko ibo ni Ondo.

Lara awọn agbegbe naa la ti ri ijọba ibile bii Akoko South-West, Akure South, Idanre, Owo, Akoko South-East ati Ese-Odo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

YIAGA ni eyi ri bẹẹ nitori awọn nnkan tawọn ti foju ri lasiko ipolongo ibo, bii iwa ipa, ikọlu si alatako, biba ọkọ jẹ ati lilọ kaakiri pẹlu ohun ija oloro, se gbilẹ lawọn agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Nguher Gabrielle Zaki

'' O jẹ ohun to fọwọ kan wa lẹmi wi pe, idibo Gomina yii le mu ki awọn iwa ti ko tọ waye, paapa bi awọn ti ọrọ kan ṣe n huwa ipa bayii''

Ajọ ọhun wa mẹnuba awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC, PDP, ZLP ati LP gẹgẹ bi awọn to n hu iwa ipa yii, ti wọn si tun jẹ ẹni to n fara ko iwa jagidijagan pẹlu.

Wọn ni bi wọn ko ba dẹkun iru iwa bayii, awọn oludibo le maa jade sita lasiko ibo nitori ibẹru bojo.

Oríṣun àwòrán, Nguher Gabrielle Zaki

Lakotan YIAGA wa gba ajọ eleto idibo ni imọran pe, ki wọn ba awọn alẹnulọrọ sọrọ lọna ati jẹ ki ibo lọ ni irọwọrọsẹ.

Bẹẹ ni wọn ni ki wọn tẹsiwaju pẹlu ṣiṣe afihan esi idbo loju opo ayelujara eyi ti yoo jẹ ki onikaluku ri okodoro bi idibo ti ṣe lọ

lagbegbe wọn.

Àkọlé fídíò,

October 1 Celebrant: Atinuke Oladeru ni kẹ yé ṣépè fún Nàíjíríà mọ́, ẹ pa ohùn dà