Champions league draw: Kà bí Juventus àti Barcelona, PSG àti Man United, pẹ̀lú Bayern ati Athletico Madrid yoo ṣe dáná sun ara wọn ní Champions League tọdun yii

Ronaldo ati Messi

Oríṣun àwòrán, Giveme sport

Iyikoto idije champions league fun ti saa idije bọọlu ọdun yii ati ọdun 2020/21 waye lọjọbọ.

Ohun to gbẹyẹ lasiko iyikoto naa ni bi wọn ṣe mu ẹgbẹ agbabọọlu Juventus ati Barcelona pọ si ipin kan naa.

Eyi tumọ si pe Ronaldo ati Messi yoo tun fojurinju lati ta okoto ayo lori papa. Ẹ si mọ pe ṣonṣo meji ni wọn ti ko gbọdọ fojurinju nitori ọkan ni lati tẹ fun ekeji ni.

Bi awọn ipin ipele komẹsẹ o yọ idije champions league fun saa 2020/21 yoo ṣe lọ niyi:

Igba akọkọ niyi ti Messi ati Ronaldo yoo maa forikori lati igba ti Ronaldo ti fi Real Madrid silẹ lọ si Juventus.