Nigeria Independence Day: Ìyàpa ẹ̀yà, èdè àti ẹ̀sìn ló mú akùdé bá ìṣọ̀kan Nàíjíríà

Olusegun Obasanjo ati Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu awọn lẹta ti ọpọ awọn akọroyin lati ilẹ afirika ati awọn onkowe kọ, BBC salaye lori isoro to buru julọ to n koju orilẹede adulawọ ti awọn eeyan rẹ pọ julọ ni Afirika, bo se n se ayẹyẹ ọgọta ọdun to gba ominira kuro lọwọ ijọba ilẹ gẹẹsi.

Ọna wo ni eniyan le gba lati ko oniruuru ẹya jọ ni isọkan, ki o si mu inu gbogbo wọn dun?

Eyi jẹ isoro akọkọ ti Naijiria koju fun ọdun mẹwaa akọkọ to gba ominira, nkan to si tun n koju titi di asiko yii ree, nibayii to ti pe ọgọta ọdun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn oniruuru ariyanjiyan to maa n waye lo da lori ọrọ ẹlẹyamẹya, ti wọn o si ma sọ pe, ki lo tọ si ẹya yii, ki lo tọ si tọhun, nigbawo, ni asiko wo, nibo ati pe bawo?

Tabi bawo ni wọn se huwa si ẹya kan, to yatọ si ẹya miran?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilede Naijiria ni oniruuru ẹya to le ni ọọdunrun, sugbọn ẹya mẹta lo bori gbogbo rẹ, eyiun ẹya Yoruba, Hausa ati Igbo.

Ẹya ọtọọtọ ni awọn eniyan wọnyii, ki awọn gẹẹsi to da gbogbo wọn pọ soju kan, ti wọn si n ṣe ijọba apapọ lonii pẹlu ipinlẹ mẹrindinlogoji ati olu ilu ni Abuja.

Oniruuru iwọde ati ifẹhonu han lo ti waye nitori ọrọ ati se ijọba, eyi si ti mu ki awọn ẹya Igbo fariga pe, awọn fẹ fi Naijiria silẹ, eyi si ni ọrọ Biafra to n waye titi di asiko yii.

Ọpọ nkan lo pin awọn ọmọ Naijiria si ọtọọtọ, bii asa, ẹsin, awọn ilana ijọba lati ẹyin wa ati eyi to o n ja lọwọ, bii ọrọ awọn agbesumọmi to n fojojumọ pa awọn eniyan lẹkun.

O le ni miliọnu mẹtala ọmọde ti ko lọ si ile iwe, eyi lo si pọju ni gbogbo agbaye, gẹgẹ bi ajọ Unicef se sọ, ida mọkandinlaadọrin awọn ọmọde ti ko lọ sile ẹkọ lo wa lati iha ariwa Naijiria.

Sibẹ awọn iha ariwa yii lo maa n gba gbogbo ipo to se gboogi ninu ijọba, wọn pọ to miliọnu lọna aadọrun, ninu eniyan miliọnu lna igba to wa ni Naijiria.

Iha ariwa Naijiria ni ipinlẹ Ogun ninu ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni orilede naa.

"O ṣeni laanu pe, ile iṣẹ to ri si bi a ṣe n pin awọn ẹya fun igbanisẹ (Federal Character) gan ni isoro, nítorí awọn ti ko koju osuwọn ni wọn ko sẹnu iṣẹ ijọba." eyi ni ọrọ Ike Ikweremadu.

"Awọn oṣiṣẹ yii a maa mu adinku ba iṣẹ ijọba, ti wọn si sọ ọ di nnkan yẹpẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Koda, awọn oṣiṣẹ ti ko koju osuwọn yii wọn a tun se ọga lẹnu iṣẹ ju awọn ti wọn ni iwe ẹri to koju osuwọn ju ti wọn lọ.

Awọn to wa ni ile iṣẹ "Federal Character" yii naa lo n ri si bi wọn se n yan ọga lawọn ile iṣẹ nlanla ijọba."

Ninu ọgọta ọdun ti Naijiria pe lonii, ẹya Ariwa ti dari orilẹede yii fun ọdun mejidinlogoji, nipasẹ iditẹ gbajọba lati ọwọ awọn ologun.

Aimọye itan nipa bi awọn eeyan se maa ṣiṣẹ takuntakun lai ri igbega, ti awọn miran yoo si lo magomago lati goke, paapaa julọ, nitori pe awọn eniyan wọn lo wa nibẹ.

Àkọlé fídíò,

Goitre Patients: Àwọn èèyàn tó ní àrùn gẹ̀gẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìkórira àti ìdẹ́yẹsí ní àwọn ń kojú

Lọdọdun ni awọn iwe iroyin maa n gbe jade pe, iye maaki bayi ni a le fi gba akẹkọọ wọle si fasiti, tabi lati gba awọn akẹkọọ wọle si ile ẹkọ sẹkọndiri ijọba apapọ.

Awọn akẹkọọ lati iha Arewa ni wọn maa n beere maaki to kere julọ lọdọ wọn yatọ si awọn ọmọ to wa lati iha Guusu.

Nigba ti maaki to kere julọ lati wọ ile iwe ba jẹ igba fun ẹni to wa lati Guusu, wọn le fi maaki mọkandinlogoje gba ọmọ lati ariwa, si ile ẹkọ kan naa.

Ni ọpọ igba, ko si iwuri fun ẹni to ba se nnkan ọtọ, "Federal Character" naa tun fi ofin de e pe, ki ibaraẹnise to dan mọran le wa, gbogbo ẹya ni o gbọdọ peju fun ipo ijọba.

Àkọlé fídíò,

SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike

Iru nnkan bayii ko fi aaye gba ẹni to koju osuwọn fun isẹ naa, yala, wọn samojuto ẹya to ti wa.

Ọpọ ọmọ Naijiria to mọ iwe, tabi mọ iṣẹ doju amin, ko ni ri iṣẹ se lati fi tẹ orilede wọn siwaju nitori awọn ti wọn mọwe bẹẹ pọ, aaye kekere si lo wa fun ipinlẹ to ti wa.

Awọn miran gba pe, nnkan to dara ni Federal Character, sugbọn wọn nilo atunto diẹ si iṣẹ ti wọn se.

Mo ni igbagbọ pe, gbogbo ọmọ Naijiria ni ipo aṣẹ ijọba tọ si. Sugbọn awọn ọmọ Naijiria naa gbodọ mọ iṣẹ wọn de oju ami

Awọn akọṣẹmọṣẹ wa ni gbogbo ẹkun Naijiria, ti wọn si gbọdọ wa wọn jade.

Àkọlé fídíò,

October 1 Celebrant: Atinuke Oladeru ni kẹ yé ṣépè fún Nàíjíríà mọ́, ẹ pa ohùn dà

Se bi gbogbo eniyan lagbaye lo mọ pe awọn ọmọ Naijiria ni ọpọlọ pupọ, ni gbogbo ẹka imọ, paapaa julọ lati awọn ẹkun ariwa ti wọn ro pe wọn ko kawe to.

Ọpọ igba ni awọn alatako ijọba ti maa n naka alebu si aarẹ Muhammadu Buhari, lori ọrọ "Federal Character" pe o yẹ ki wọn kaṣẹ rẹ nilẹ.

"Mi o ni isoro pẹlu ẹya Naijiria kankan, sugbọn mo ni isoro nipa bi awọn ijọba se n dari iyanisipo." Ekweremadu lo sọ eyi lọdun 2018 niwaju ile asofin.

Lọwọ lọwọ bayii, mẹtadinlogun ninu Ogun awọn olori ẹka eto aabo ni Naijiria, ti aarẹ Buhari yan, ẹkun ariwa ni wọn ti wa,

Mẹrindinlogun ninu wọn si jẹ musulumi bi tirẹ.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Aṣa lori BBC: Kí ní ìtúmọ̀ Sílébù àti àmi ohun tó ń fún ni?

Mẹẹdogun ninu mọkanlelogun awọn igbakeji ọga ologun lo wa lati ariwa, ti mẹrindinlogun ninu wọn si jẹ musulumi.

Lasiko to n gbeja ọga rẹ, agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Garba Shehu sọ fun mi pe, "se iwọ le fi ẹni ti o ko mọ si ipo aṣẹ ọmọogun, ti o ba jẹ adari?

Ipo yii kan naa ni onkọwe Wole Soyinka wa, nigba to n tọka si pe, awọn kan yoo maa tẹle ara wọn, ti wọn ti jẹ ẹya to pọ."

Ẹwẹ, agbẹnusọ Aarẹ tọkasi pe, wọn ti naka alebu si awọn ijọba to ti koja tẹlẹ naa pe, wọn maa n gba awọn eniyan to jẹ ẹya wọn sisẹ, ju ẹya miran lọ.

Àkọlé fídíò,

Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

"Ti awọn eniyan ko ba si ni ijọba, ẹni naa yoo ma ri aṣiṣe awọn miran ni - ọgbẹni Shehu.

" Nigba ti Obasanjo wa ni ijọba, ọpọ awọn eniyan lo n fẹsun kan pe o n yan awọn eniyan iha iwoorun - guusu sipo"

Awọn ẹgbẹ kan ni iha guusu ti ni ọna abayọ kan ṣoṣo ni pe, ki Naijiria tuka, ki olukuluku ẹya si wa ni aaye ara rẹ gẹgẹ bi orilẹede.

Awọn oloselu kan ati awọn onwoye miran ni "atunto" ni nkan to yẹ, ti ẹkun kọọkan yoo le ma maa dari ara wọn, eyi yoo si mu isọkan ati irẹpọ ba Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Toyin Atoyebi mechanic: Ẹ wo Toyin, ọmọbinrin ọdún 16 tó ń tún skadà àti gẹnẹrátọ̀ ṣe ní

Bakan naa ni wọn ni yoo mu ki adinku ba bi agbara se wa loju kan nilu Abuja.

Gbogbo ilana ti Naijiria ba pada gunle, bi yoo se maa gun akasọ lati lọ aadọrin ọdun ominira yii, nkan ẹyọ kan to ṣe pataki ni pe:

Ọjọ iwaju Naijiria wa lọwọ bi ijọba to ba n bọ, yoo se mu isọkan wa laarin gbogbo ẹya.