Okonjo-Iweala WTO DG nomination: Kíni ìdí tí orílẹ̀-èdè America ṣe tako ìyànsípò Okonjo-Iweala gẹ́gẹ́ bi olórí ajọ WTO

Okonjo Iweala

Oríṣun àwòrán, TEAMNGOZI

Lootọ ni wọn ti fi orukọ ọmọ orilẹ-ede Naijiria, Ngozi Okonjo-Iweala silẹ lati di oludari agba fun ajọ okoowo l'agbaye, World Tradr Organisation (WTO).

Ṣugbọn, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla, ni ireti wa pe ajọ naa yoo kede erongba rẹ.

Ọpọ ninu awọn aṣoju orilẹ-ede ninu ajọ naa, to parapọ mọ awọn ọmọ igbimọ lati yan Ọga Agba tuntun, lo fọwọ si iyansipo Okonjo-Iweala.

Orilẹ-ede America nikan ni aṣoju ti ko faramọ iyansipo rẹ nibi ipade to waye l'Ọjọru.

Àkọlé fídíò,

Kété tí wọ́n bá ti báa yín sùn tàn torí pé ẹ tóbi, ẹ gbà pé ìfẹ́ yẹn ti parí - Auntie Remi Ọlọ́yàn ńlá

Kini idi ti ilẹ America ko fi ṣe atilẹyin fun?

Oríṣun àwòrán, WTO/WEBSITE

Gẹgẹ bi Akọroyin BBC lori eto ọrọ aje, Andrew Walker, ṣe ṣalaye, oludije fun ipo naa lati orilẹ-ede South Korea, ni America faramọ, nitori "iriri to ni nipa okoowo, ati ipá lati ṣe amojuto daadaa".

Wọn ko sọ idi ti wọn fi tako Okonjo-Iweala.

Ṣugbọn, o di igba ti igbesẹ to kẹhin ba waye, ki ijiroro to o tan.

Nibo ni nkan yoo yọri si?

Bi ọrọ naa ṣe n lọ, lootọ ni Okonjo-Iweala, ni ibo to pọju, amọ iyansipo rẹ ko ti i fi ẹsẹ mulẹ.

Ijiroro ṣi n lọ lọwọ lori boya ajọ WTO faramọ ẹni to ni ibo to pọju lọ.

Àkọlé fídíò,

Wo imọran Fọlọrunṣọ Alakija fun awọn ọdọ adulawọ

Ọkan lara awọn akọroyin lati Naijiria to ni anfaani lati mojuto eto idibo naa, Oluwamayowa Tijani, sọ fun BBC Pidgin pe "iṣoro to wa nibẹ ni pe orilẹ-ede America ko faramọ Okonjo-Iweala".

"Nkan ti orilẹ-ede America si le ṣe lati gbe erongba wọn lẹyin, ni lati wa awọn orilẹ-ede mii ti yoo darapọ mọ wọn lati tako o."

Ajọ̀ WTO lo ma n mojuto ijiroro ati adehun okoowo laarin awọn orilẹ-ede.

Nibẹ si ni awọn orilẹ-ede ti le yanju aawọ to ba waye laarin wọn nitori okoowo.

Okonjo, to ti fi igba kan jẹ minisita fun eto inawo ni Naijiria, ni obinrin akọkọ to de ipo naa lati ọdun mẹẹdọgbọn ti wọn ti da ajọ WTO silẹ.

Àkọlé fídíò,

Adetoun Ogunṣẹyẹ: ìrìnàjò ẹ̀kọ́ mi títí dé òkè kò rọrùn rárá

Oun naa si tun ni ọmọ ilẹ Africa akọkọ to de ipo naa.

Apapọ ibo mẹrinlelọgọrun ni oun nikan ni, ninu ibo mẹrinlelọgọjọ ti awọn aṣoju di.

Eyi yoo mu ko fi ẹyin minisita fun okoowo l'orilẹ-ede South Korea, Yoo Myung- he, ti wọn jọ de ipele to kẹhin.

Bi ipinnu Ngozi Okonjo-Iweala lati di Oludari ajọ WTO ṣe n jọ ọ bọ̀ diẹdiẹ

Ipinnu Minisita feto ọrọ aje Naijiria tẹlẹ Ngozi Okonjo Iweala lati di ipo adari ajọ idokowo lagbaye WTO mu n sunmọ mimu ṣẹ bọ diẹ diẹ.

Eyi ko sẹyin bi o ti ṣeeṣe ki wọn kede orukọ rẹ lojobọ lara awọn meji to tẹsiwaju de abala ìkẹyìn eto iyansipo tó n lọ lọwọ.

Ni bi nkan ti ṣe ri yi, oun ati ọmọ orileede South Korea Yoo Myung- he ni wọn yoo fi orukọ wọn ṣọwọ ninu awọn marun un to ṣẹku tẹlẹ.

Obinrin ni awọn mejeeji.

Bi o ba fi le jawe olubori yoo jẹ obinrin akọkọ lati Afrika ti yoo di ipo yi mu.

Àwọn onwoye si n sọ pe yiyan ọmọ Afrika si ipo yi yoo mu idagbasoke ba karakata nilẹ naa eyi ti o daduro si ida meji si mẹta idokowo lagbaye.

Bakan naa ni adari ajọ naa tuntun ti wọn ba yan yoo ni lati pẹtu saawọ idokowo laarin Amerika ati China.

Ṣaaju ni aarẹ Trump ti kọdi iyansipo awọn adajọ si igbimọ ipẹtusaawọ ajọ naa.

Eyi si n ṣakoba fun ajọ naa nipa ṣiṣe iṣẹ rẹ lẹkunrẹrẹ.

Loṣu to n bọ ni wọn yoo kede ẹni ba pegede fi ipo olori WTO.

Àkọlé fídíò,

Ondo Elections 2020: Ọgọ́rùn-ún ọdún tí a máa lò lórí oyè l'Ondo, ẹ ó rí àrà - Ojon YPP

Ta ni Ngozi Okonjo-Iweala to dupo olori ajọ okowo agbaye WTO?

Ọjọgbọn Ngozi Okonjo-Iweala jẹ minisita ijọba meji lorilẹede Naijiria-2003 si 2006 labẹ aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ, 2011 si 2015 labẹ iṣejọba aarẹ Goddluck Jonathan.

Banki agbaye ni Ọjọgbọn Ngozi Okonjo-Iweala ti n ṣiṣẹ ki aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ to pe e wa sile wa ṣe minisita fun eto iṣuna lorilẹede Naijiriaoun ni obinrin akskọ ti yoo ṣe minisita fun eto iṣuna ati minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @NOIweala

Àkọlé àwòrán,

Pupọ ọmọ orilede Naijiria ni ko ni gbagbe minisita 'alaṣọ ankara' yii pẹlu gele 'ipakọ o gbọ ṣuti' rẹ

Ọkan lara awọn eekan to lagbara labẹ iṣejọba aarẹ Ọbasanjọ laarin ọdun 2003 si 2006 ni Okonjo-Iweala, o si ko ipa ribiribi ninu bi awọn igbimọ orilẹede agba kan lagbaye ṣe wọgile gbese biliọnu mejidinlogun dọla, $18bn ti orilẹede Naijiria jẹ ṣaaju igba naa.

Pupọ ọmọ orilede Naijiria ni ko ni gbagbe minisita 'alaṣọ ankara' yii pẹlu gele 'ipakọ o gbọ ṣuti' rẹ.