2021 Nigerian Budget: Àbádòfin ìṣúná 2021 ré kọjá ìpele ìkejì nílé aṣòfin àgbà

Aarẹ Muhammadu Buhari gbe aba iṣuna ka iwaju awọn asofin apapọ

Oríṣun àwòrán, SENATE NIGERIA

Aba isuna oni triliọnu mẹtala ti aarẹ Muhammadu Buhari fi ṣọwọ s'awọn aṣofin ti rẹ kọja ipele kika Ikeji ni ile aṣofin agba.

Lọjọbọ ni awọn aṣofin agba tẹti si kika rẹ ti wọn sì ni ko tẹsiwaju abala to kan.

Igbesẹ yi waye lẹyin ijiroro ọlọjọ mẹta lori awọn koko to wa ninu abadofin yi ti aarẹ pe orukọ rẹ ni aba isuna idapada ati iduro sinsin ọrọ aje Naijiria.

Lọjọbo to kọja ni aarẹ Buhari tẹ abadofin naa siwaju ile aṣofin.

Ọkọọkan ejeeji lawọn aṣofin n sagbeyẹwo aba isuna naa t'awọn kan si n naka abuku si ibi to ku diẹ si b'awọn mii ṣe n gbosuba fún ùn.

Ohun kan to kan awọn aṣofin lominu ni iye ti wọn kọ sinu rẹ pe Naijiria yoo fi seto gbese to le ni triliọnu mẹta naira ati erongba lati ya owo to le ni triliọnu marun un lati fi seto isuna.

A máa ná N10.2 bílíọnù fi tún wáyà iná àti inú ilé Aso Rock ṣe- Buhari

Oríṣun àwòrán, @Abujang

Aarẹ Buhari ti gbe eto iṣuna ọdun 2021 lọ siwaju ile igbimọ asofin mejeeji ni Abuja.

Ọkan ninu atupalẹ eto iṣuna naa ti awọn eeyan n pariwo bayii lori ayelujara ni ti owo to le ni biliọnu mẹwaa naira ti Aarẹ Buhari ni wọn fẹ fi tun àwọn wáyà ina ati inu ile Aso Rock se ni Abuja.

Wọn ni wọn ti fi afojusun lati na o din diẹ ni biliọnu marun un naira lori atunṣe ati ipese awọn wáyà ina.

Wọn yoo si na biliọnu marun un naira le ni ọọdunrun lori atunṣe awọn ọọfiisi ati ile inu Aso Rock to jẹ ileejọba ni Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.

Awọn alakalẹ bi wọn ṣe fẹ na owo naa ni wọn gbe si abẹ "ERGP 7102245" to jẹ atunṣe awọn waya ina ni eyi ti wọn maa na N4,854,381,299.

Ati atunse awọn ile gbigbe ati ọọfiisi ti wọn yoo ti na: N153,693,262 ati N5,244,027,241."

Àkọlé fídíò,

coronavirus prevention badge update: Wo òótọ́ àti irọ́ tó wà nínú báàjì àyà náà

Wọn ni miliọnu marun un ati igba naira ni wọn yoo fi yanju ọrọ atunse jẹnẹratọ amunawa ti wọn yoo si fi miliọnu marundinlaadọta N45m ra epo jẹnẹratọ.

Wọn ni wọn yoo fi N274m fi san owo ina ọba PHCN ti wọn yoo si fi N67.1m sanwo lilo ayelujara (Internet)

Àkọlé fídíò,

Abayọmi Aranmọlatẹ, Dr Laser: Vagino Plasty àti iṣẹ́ abẹ ẹwà Obìnrin ló jẹ mí lógún

Wo owó tí Buhari bù fún ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan nínú ìṣúná ọdún 2021

Aarẹ Muhammadu Buhari gbe aba kalẹ lọjọbọ siwaju ile asofin apapọ ilẹ wa eyi ti apapọ rẹ totriliọnu mẹtala naira (₦13.08trn).

Ninu aba isuna naa, oniruuru ileesẹ ijọba ati lajọlajọ ni ijọba se alakalẹ iye ti wọn yoo naa fun ọdn to n bọ, to si bu owo naa fun wọn.

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Èyí ní àtúpalẹ̀ ètò ìṣúná fọ́dún 2021

Aarẹ Buhari, lasiko to n gbe aba isuna naa kalẹ salaye pe gbogbo awọn akanse isẹ to n lọ lọwọ nijọba yoo sa ipa rẹ lati pari lọdun 2021, to fi mọ awọn oju popo ati oju irin.

Bakan naa ni ijọba ko gbagbe ẹka to n pese ina ọba, eto irinna oju irin ati eto ẹkọ alakọbẹrẹ ati ipese ilera alabọde ninu eto isuna naa.

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Bi alakalẹ eto isuna fun ọdun 2021 yoo ṣe lọ niyii:

 • Ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ abẹle - N227.02 bn
 • Ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ ọlọpaa - N441.39 bn
 • Ileeṣẹ ijọba to n risi eto ẹkọ (owo iranwọ fun awọn akẹkọọ labẹlẹ ati loke okun) - N545.10 bn
 • Ileeṣẹ ijọba to n risi eto aabo - N840.56 bn
 • Ileeṣẹ ijọba to n risi eto ilẹra - N380.21 bn
 • Ẹka ina ọba - (to fi mọ N150bn fun agbende ẹka ina ọba) N198 bn
 • Ẹka iṣẹ ati ile gbigbe - N404 bn
 • Ẹka irinna ọkọ oju irin (Lagos-Ibadan-Kano, Abuja-Kaduna, Port-Harcourt-Maiduguri ati Itakpe-Ajaokuta-Warri)- N256 bn
 • Eto aabo: N121 bn
 • Eto ọgbin ati idagbasoke awọn igberiko - N110 bn
 • Eka ipese omi - N153 bn
 • Ẹka idokowo ati karakata - N51 bn
 • Eto ẹkọ - N127 bn
 • Ajọ ẹkọ ọfẹ kariaye: N70 bn
 • Eto ilera - N132 bn

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

 • Owo ẹya fun awọn olokoowo ke ke ke- N100 bn
 • Owo ẹya fun eto iwosan ati ipoogun - N100 bn
 • Owoya fun awọn ileeṣẹ eto ọgbin ati ipese iṣẹ nla nla - N1 trn
 • Ajọ to n ri si idagbasoke agbegbe Niger Delta - N63.51 bn
 • Ajọ to n ri si idagbasoke agbegbe North East - N29.70 bn
 • Ajọ eleto idajọ NJC - N110 bn
 • Ajọ iranwọ fun eto ẹkọ alakọbẹrẹ - N70.05 bn
 • Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria (INEC) - N40.00 bn
 • Ile igbimọ Aṣofin apapọ - N128.00 bn
 • Ajọ eleti gbaroye lawujọ - N5.20 bn
 • Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan - N3.00 bn
 • Ajọ to n risi ẹto ilera alabode - N35.03 bn
 • Owo iranwo fun iṣẹ akanṣe - N355 bn
 • Owo iranwọ fun ilegbe ẹbi - N20 bn
 • Owo iranwọ fun awọn ọdọ - N25 bn
 • Awọn olu ileeṣẹ ijọba bii ọgọta - N336 bn

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Buhari gbé àbá ìṣúná ₦13.08trn kalẹ̀, ó ń wá owó tí yóò fi gbọ́ bùkátà rẹ̀

Aarẹ orilẹede Naijira, Muhammadu Buhari ti gbe aba isuna oni triliọnu mẹtala naira (₦13.08trn) kalẹ sile asofin apapọ ilẹ fun ọdun 2021,

Aba isuna naa lo fi triliọnu meji o le diẹ (₦2.2trn) pọ ju ti ọdun to kọja lọ, eyi to din diẹ ni triliọnu mskanla naira (₦10.805).

Nigba to n gbe aba isuna naa ka iwaju ile, aarẹ Buhari ni ipenija nla to n koju ijọba oun bayii ni ọna lati ri owo gbọ bukata eto isuna naa.

O fikun pe awọn minisita oun yoo bẹrẹ si ni tọpinpin bi wsn se n gba owo ori wọle lati ri daju pe ohun gbogbo n sisẹ bo se yẹ.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Owo isuna ọdun to n bọ naa ni wọn gbe le pasipaarọ owo naira ilẹ wa si Dọla tilẹ Amẹrika, eyi tii se naira ọrinlelọọdunrun o din kan (₦379) si dọla kan.

Owo agba epo to wa ni ogoji dọla si ni wọn gbe isuna naa le, ti ireti si wa pe wọn yoo ri owo to din diẹ ni miliọnu meji dọla ($1.86m) lojumọ.

Awọn ohun to sẹlẹ niwaju ile lasiko to aarẹ n gbe aba isuna kalẹ:

Deede aago mọkanla aarọ ọjọbọ ni aarẹ bẹrẹ kika eto isuna naa niwaju awọn asofin apapọ ilẹ wa.

Àkọlé fídíò,

Ondo Elections 2020: Ọgọ́rùn-ún ọdún tí a máa lò lórí oyè l'Ondo, ẹ ó rí àrà - Ojon YPP

Ọpọ awọn osisẹ agbofinro si la gbọ pe wọn peju wamu wamu sile asofin apapọ naa, ti aarẹ Buhari ti n gbe aba isuna naa kalẹ.

Saaju ni alaga igbimọ ile to wa feto isuna nile asofin agba ilẹ wa, Sẹnetọ Barau Jibril ti kede pe ilana gbigbe aba isuna tọdun yioi kalẹ yoo yatọ si ti tẹlẹ nitori arun coronavirus to gbode kan.

Gẹgẹ bo se wi, awọn yoo tẹle ilana to dena arun Coronavirus naa, ti adinku yoo si ba iye eeyan ti yoo tẹle aarẹ wa sile asofin apapọ, ki ile maa baa kun akunju.

Àkọlé fídíò,

SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike