Kayode Olabode killed in Ondo : Opó àti àbúrò olóògbé ní ikú Kayode Olabode kìí ṣe àtọ̀runwá

Kayode Olabode killed in Ondo : Opó àti àbúrò olóògbé ní ikú Kayode Olabode kìí ṣe àtọ̀runwá

Ọkunrin kan nilu Akure, Kayode Olabode, ni wọn ni ọlọpa mẹta kọlu, to si sagbako iku ojiji lati ipasẹ sọbiri ti wọn fi gba lori.

Gẹgẹ bi opo oloogbe. Olayinka Olabode ati aburo oloogbe, Olugbenga Agbebi ti salaye fun BBC Yoruba, wọn ni awọn ọlọpaa naa fẹ gba ilẹ ọhun fun ara wọn ni, ti wọn si salaye awọn ohun to mu ifura lọwọ nipa iku oloogbe naa ati bi ejo se lọwọ ninu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti wa fesi pe aisan ẹjẹ ruru lo mu ẹmi oloogbe naa lọ, iku rẹ ko si wa lati ọwọ ẹnikẹni.

Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa Ondo, Tee-Leo Ikoro ni awọn ti tu awọn afurasi to wa ni ahamọ silẹ lẹyin abajade iku Olabode, ti wọn si ri pe iku atọrunwa ni, ko ni ọwọ aye ninu.