Fuji Music: Kollington Ayinla sọ ẹni tó dá orin Fuji sílẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà

Fuji Music: Kollington Ayinla sọ ẹni tó dá orin Fuji sílẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà

Agbaọjẹ olorin Fuji ni Naijiria, Alhaji Kollington Ayinla tun ti yanna na bi orin Fuji ṣe bẹrẹ lorilẹede Naijiria.

Ọpọ awuyewuye lo ti wa lori ẹni ti o bẹrẹ orin Fuji ni Naijira laarin oloogbe Sikiru Ayinde barrister ati Alhaji Kollington, Kebe n Kwara.

Amọ, Kollington fun ra rẹ naa ti fi kọ orin pe ''Edumare fiṣẹ yin wa gbogbo wa, lagbaja lo da Fuji silẹ, ọrọ awawi, tamẹdo lo da Fuji silẹ, Edumare fiṣẹ yin wa gbogbo wa.''

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ileeṣẹ FUJI: A Opera, Kollington gba pe oloogbe Ayinde Barrister lo da ere Fuji silẹ nigba ti oun tẹ le e ninu iṣẹ orin Fuji.

Nibi akanṣe eto naa to waye ni Alliance Francaise de Lagos/The Mike Adenuga Center, Ikoyi, Kollington sọ pe orin Fuji ti kọja bẹẹ lasiko yii.

Kollington ṣalaye pe oun ko lero pe orin Fuji le di gbajugbaja orin bi o ti da lonii.

''Orin gidi ni orin Fuji, o ti kan kaakiri gbogbo agbaaye bayii, gbogbo eeyan ni Naijiria lo fẹ kọ orin Fuji bayii,'' Kollington lo sọ bẹẹ.

Alhaji Kollington fikun ọrọ rẹ pe ijinlẹ ede Yoruba lawọn maa n fi kọ orin Fuji ṣugbọn laye ode oni ''awọn ọmọ wa ti fi ede oyinbo si orin Fuji lati le jẹ ko jẹ itẹwọgba sii kaakiri agbaaye.