Zlatan: Ọ̀rẹ́ ni mo sìn lọ ‘studio’ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ orin lẹ́yìn tí mo kùnà ìdánwò WAEC

Zlatan: Ọ̀rẹ́ ni mo sìn lọ ‘studio’ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ orin lẹ́yìn tí mo kùnà ìdánwò WAEC

Yoruba ni ori lo mọ ọlọla, ko si si ẹni to le sọ ori olowo lọla.

Omoniyi Temidayo Raphel, ti ọpọ eeyan mọ si Zlatan Ibile lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ti ni oun ko mọ pe oun le di gbajumọ bayii nidi orin kikọ.

Akọrin takansufe naa, to ni wura ni itumọ orukọ inagijẹ Zlatan ti oun n lo, tun ni ọrẹ ni oun sin lọ si gba orin silẹ, ki wọn to ni ki oun naa wa kọrin.

Zlatan ni lootọ ni oun ti n kọrin lati ile ẹkọ girama ti oun si jẹ ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ eyi to jẹ ki oun di ẹni akọkọ ti yoo lo ọkọ ninu idile oun.

Gbajumọ akọrin takansufe naa, to ni ẹmi lo maa n gbe ọpọ orin ti oun n kọ wa, tun fikun pe bọọlu lo wu oun lati gba, ka ni oun ko mọ orin kọ.

Nigba ta ni ko gba awọn ọdọ to n lu jibiti nidi isẹ yawuu nimọran, Zlatan ni ojuse obi wọn ni lati gba wọn nimọran, kii se isẹ toun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọrọ pọ ti Zlatan ba BBC Yoruba sọ, ẹ mọ salai wo fidio yii fun ẹkunrẹrẹ iroyin.