Akomolede BBC Yoruba: Ṣé ẹ mọ̀ pé àṣà nílẹ̀ Yorùbá ni ìwà ọmọlúàbí?

Akomolede BBC Yoruba: Ṣé ẹ mọ̀ pé àṣà nílẹ̀ Yorùbá ni ìwà ọmọlúàbí?

"B'eegun ẹni ba joo 're, ori a maa ya atọkun"

"B'ọmọ ẹni ba dara ka wi"

"Ọmọ to dara ti baba ni, eyi ti ko dara, ti iya ni"

Awọn owe atawọn aṣayan ọrọ bi eleyi ko ṣajoji si iwa rere nilẹ Yoruba.

Iyaafin Adenke Okun jẹ agba nilẹ Yoruba, torinaa ni wọn ṣe jẹ olukọ to lee kọ nipa aṣa yii daadaa.

Aṣa ọmluabi jẹ ohun ti wọn fi n da eeyan mọ yatọ lawujọ kaakiri agbalaye torinaa ni ẹya Yoruba ṣe mu u lọkunkundun.

Aṣa Yoruba si fẹran keeyan maa hu iwa rere pupọ ni wọn fi maa n n pa aweọn owe to rọ mọ eyi.

Ikini

Too ba mọ eeyan ki, awọn Yoruba ko naani ẹti ko ba mọ eeyan ki o. Koda bi ọmọkunrin o dọbalẹ ki igba aya rẹ kan ilẹ tabi ki ọmọbinrin fi orokun mejeeji kunlẹ ki agba, o lee gba igbati lọwọ obi nilẹ yoruba eyi to ṣajoji sawọn ẹya mii. Yoruba a ni ọmọ bẹẹ n gbin agbado ki agbalagba ni.

Otitọ sisọ

Ibọwọ fun agba

Iwa irẹlẹ to maa n mu ni ko ogo aye ja

Fifi ohun rere sọrọ ati ọpọlọpọ ohun iwuri to yẹ ni iwa ni akẹkọ etoo Akọmọlede lorii BBC Yoruba ṣi lawẹlawẹ ninu fidio to wa loke yii.