Deborah Adebola Fasoyin: Ní gbogbo ìgbà ọdún láyé àtijọ́, báyìí ni CAC ṣe máà ń kọ orin “Odun n lo sopin
Èmi kọ́ ló gbé orin ọdún ń lọ sópin kalẹ̀, CAC ló ni í ni mó n ṣe àkójọ orin- Fasoyin
Orin ọdun n lọ sopin jẹ eyi to gbajumọ laarin ọpọ eeyan lai fi ti ẹsin se nitori ọpọ adura to pọ ninu orin naa.
Ti ọdun ba si ti n lọ sopin ni orin naa maa n gbalẹ kan , eyi tawọn eeyan n lo lati se adura funra wọn.
Ọna lati mọ nipa bi agbekalẹ orin naa se waye, lo mu ki BBC Yoruba kan si asaaju ẹgbẹ akọrin obinrin ninu ijọ CAC to kọ orin naa, Mama Deborah Adebola Fasoyin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Ọba Seriki Abass ti Badagry, tó ní aya 128, ọmọ 144
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Kí ló fà ogun Ìjàyè àti ìṣubú Kurunmi, ìfẹ́ ìlú ni àbí orí kunkun?
- Duro Ladipọ, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà àti ọmọ àlúfà tí kò gbàgbé àṣà ìbílẹ̀
- Ìtàn ìgbésí ayé Oshodi, ọmọ Tápà léǹpe tó di akọni ní ìlú Eko
- Láti 110kg ni mo ti já sí 87kg báyìí, ṣùgbọ́n mí ò ṣáàro ọyàn mi ńla tó dínkù - Ronke Oshodi Oke
"Oreofe ni Ọlọ́run fún láti wà lára àwọn tó kọ orin "Odun n lo sopin."
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ, ìya Fasoyin sàlàyé pé àgbáríjọ àwọn akọrin CAC ló jọ máa wọ inú àwẹ̀ àti àdúra láti ṣe àkójọ orin gbogbo orin wọn.
Ìyá Fasoyin sàlàyé pé lẹ́yin àdúra àti àwẹ́ ní wọn yóò wá mú àwọn ti ẹmi mímọ bá fí sí wọ́n lakan láti gbé síta.
O wa fidi rẹ mulẹ pe ọjọ Kọkandinlogun osu Kẹsan ọdun 2020 yii ni wọn ṣe orin náà si ẹ̀yà Igbo àti Hausa fún ànfàni àwọn ti kò gbọ́ Yorùbá.