Stem Cell treatment: Àrùn tó lé ní 80 ni àwọn onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó leè fi ìwọ́ àti olubi

Stem Cell treatment: Àrùn tó lé ní 80 ni àwọn onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó leè fi ìwọ́ àti olubi

Titi di oni, sisọ iwọ ati olubi smọ nu ti di aṣa eyi ti o maa n waye ni kete ti ibi smọ tuntun ba ti waye.

Amọṣa awọn ims tuntun ti fihan bayii pe ko si idi fun wa lati maa sọ iwọ ati olubi awọn ọmọ tuntun ti a ba ṣẹṣẹ bi mọ nitori agbara iwosan ọpọlọpọ arun gbẹmigbẹmi lo wa ninu wọn.

Gẹgẹ bi awọn onimọ ti ṣe sọ, ko din ni ọgọrin aisan gbẹmigbẹmi ati baraku ti wọn lee fi awọn eroja aṣaralore to wa ninu iwọ ati olubi ọmọ tuntun wo.

Koda awọn aisan bii foniku-fọla dide (Sickle cell), warapa (Epilepsy) ati Rọlapa-rọ lẹsẹ (Stroke) wa lara awọn aisan ti wọn n fi iwọ ati olubi ọms wo bayii.

Gẹgẹbi awọn onimọ iṣegun ṣe sọ, ko din ni alaisan mẹẹdogun ti wọn ti ri iwosan kuro lọwọ aisan foniku-fọla dide ni Naijiria nipasẹ imọ lilo iwọ ati olubi ọmọ fi ṣe iwosan yii, eleyii ti a mọ si Stem cell.