Seyi Makinde-Olaniyan: Igbákejì Gómìnà Oyo ní kò síjà láàrin òun àti Gómìnà

Engr Remi Olaniyan ati Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Engr Remi Olaniyan

Igbakeji Gomina ipinlẹ Oyo, Amoju-ẹrọ Raufu Olaniyan ti ṣalaye pe iroyin ayederu lawọn kan n gbe kiri pe, ija wa laarin rẹ ati Gomina Seyi Makinde.

Igbakeji Gomina Oyo, to ba BBC Yoruba sọrọ l'Ọjọbọ ṣalaye pe, oun ko figba kan sọ sita pe ija wa laarin awọn mejeeji, bẹẹ ni Makinde fun ra rẹ naa ko sọ fun ẹnikan pe oun ati igbakeji oun n ja.

Amoju-ẹrọ Olaniyan ni awọn oloṣelu kan, ti wọn n wa oju rere Gómìnà ipinlẹ Oyo lo wa nidi ọrọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Asiko oṣelu ni a wa yii, awọn to n gbe iru iroyin yii n wa bi okele wọn yoo ṣe pọn lọdọ gomina ni," igbakeji gomina lo sọ fun BBC bẹẹ.

Iroyin kan ti kọkọ jade pe igbakeji gomina ipinlẹ Oyo sọ pe ija to wa laarin oun ati Makinde ko le pari laelae.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Engr Remi Olaniyan

Amọ, Amoju-ẹrọ Olaniyan sọ fun BBC pe, "ohun to ba wu onikaluku lo le fi ẹnu rẹ sọ nitori ijọba awaarawa lo wa lode."

Igbakeji gomina ipinlẹ Oyo ni awọn to n gbe irufẹ iroyin bayii mọ ohun ti wọn ni lọkàn fun ra wọn .

Bakan naa lo tun fikun ọrọ rẹ pe, ero ọkan awọn akọroyin lasan, ni awọn ileeṣẹ iroyin to gbe iru iroyin bayii sita, oun ko ba ẹnikẹni ja tabi ni ẹnikẹni sinu.

"Wọn ni mo n binu tori gomina ko fa awọn isẹ kan le mi lọwọ, amọ bi gomina fa isẹ le mi lọwọ, agunla, bi ko si fa a le mi lọwọ, ko si wahala, jẹjẹ mi ni mo n lọ."

Àkọlé fídíò,

Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Ọgbẹni Olaniyan ti sọ tẹlẹ ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ rẹ lori eto iroyin, Omolere Omoetan fi sita pe, ojuṣe oun gẹgẹ bi igbakeji gomina ipinlẹ Oyo ni lati ṣiṣẹ pọ pẹlu Gomina Makinde.

O ni oun ṣetan lati tẹsiwaju nipa ṣiṣe bẹẹ, bakanna lo ni oun ko ni kaarẹ nitori ohun tawọn eeyan kan n sọ kiri.