Bolu Akin Olugbade: Ọkọ̀ olówó iyebíye Roll Royce Limousine mẹ́wàá nìkan ni ọlọ́lá yìí gùn nígbà ayé rẹ̀

Bolu Akin-Olugbade

Oríṣun àwòrán, Bolu Akin-Olugbade

Ọpọlọpọ ọlọla ati eniyan jankan lo ti n ṣedaro oniṣowo Bolu Akin- Olugbade to ki aye pe o digba o ṣe, nigba ti arun Coronavirus gba ẹmi rẹ.

Gomina ipnlẹ Ogun, to fi mọ awọn eekan lawujọ lo ṣedaro rẹ gẹgẹ bi gbajumọ to si tun jẹ eniyan pataki ni awujọ.

Bakan naa ni wọn si ba ẹbi ati ara kẹdun lẹyin ti o dakẹ ni ile iwosan to ti n gba itọju arun Covid 19, ki ọlọjọ to de.

Ọmọ olowo ati ọlọla ni Bolu Akin-Olugbade, toun naa si sisẹ lati lowo, bi igbesi aye rẹ si se lọ ree.

Oríṣun àwòrán, Bolu Akin-Olugbade

Ta ni ọlọla Akin Olugbade ti arun Coronavirus gbẹmi rẹ?

Ọjọ Keji, Oṣu Kẹrin, ọdun 1956 ni wọn bi Akin-Olugbade si idile baba ọlọla ati oniṣowo to tun jẹ Balogun Owu nilu Abeokuta, Babatunde Akin-Olugbade.

Bolu lọ si ile iwe Corona ni ilu Eko, lẹyin naa lo tẹsiwaju lọ kọ imọ ofin ni Fasiti kan ni ilu London, ni Ilẹ Gẹẹsi.

Akin-Olugbade tun tẹsiwaju si lati kawe gba oye imọ ofin to de awọn ileeṣẹ ni fasiti California, ni orilẹede Amẹrika.

Agbẹjọro ni Akin-Olugbade, to si n ṣe idokowo ninu rira ile ati ile kikọ, epo rọbi, ile ifowopamọsi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Bolu Akin-Olugbade

Titi di ọjọ iku rẹ ni ẹni ọdun mẹrinlelọgọta, oun ni oloye Aarẹ ọna kankanfo ti ilu Owu.

Akin-Olugbade ati iyawo rẹ, Ladun, ti wọn ti fẹ ara wọn fun ogoji ọdun, ni Eledumare fi ọmọ ati ọmọọmọ kẹ.

E wo awọn ọkọ bọgini ti Akin-Olugbade fi se ara rindin nigba aye rẹ:

Aarẹ Bolu Akin-Olugbade fẹran ọkọ bọgini nigba aye rẹ, paapaa eleyii ti wọn n pe ni Rolls Royce.

Oríṣun àwòrán, Bolu Akin-Olugbade

 • Gbogbo awọn to sunmọ lo mọ wipe o fẹran Rolls Royce Limonsine ko to jade laye,to si jẹ pe mẹwaa iru rẹ lo lo nigba aye rẹ
 • Ọdun 1984, nigba ti Akin-Olugbade wa ni ẹni ọdun mọkanlelogun, lo kọkọ ra ọkọ bọgini Rolls Royce (Luxury) rẹ
 • Rolls Royce Cullinan - RR Cullinan ($500,000) ni ikẹwa to ra ni ọdun 2019
 • Awọn ọkọ Rolls Royce yoku ni o kọ orukọ rẹ si lara bii "BOLU 1, 2, 3, 4, 5…"
 • Ọkọ bọgini Phantom Convertible Drophead
 • Ọkọ bọgini Ghost, 2018 Phantom V111.

E wo awọn ile awosifila ti olola Akin-Olagbade ko to jade laye:

Oríṣun àwòrán, Bolu Akin-Olugbade

 • Ile nla alaja mẹta ni Aarẹ Onakakanfo ti ilu Owu, Bolu Akin Olugbade kọ si aafin rẹ ni Abeokuta, nitosi odo ogun
 • Ile nla awosifila naa ni yara ibusun mọkanla, chandeliers mẹrinla, ile igbafẹ mẹrin lo wa nibẹ
 • Bakan naa ni aafin ọhun dabi ti afin Ilẹ Gẹẹsi, Burkingham Palace, to si ni yara iwo sinima
 • Bẹẹ ni Gbagede 'Amphitheatre' ko gbẹyin nibẹ pẹlu ibi ti ọkọ ofururu rẹ ma n balẹ si
 • Akin Olugbade tun ni ile si ilu Eko, Ilu Ọba ni Ilẹ Gẹẹsi, Ilu Los Angeles ni Ilẹ Amẹrika ati ni Dubai pẹlu.

Ọdaju ni iku, iku ti kii gba owo tabi dukia afi ẹmi ẹda, ka ni iku n gba owo ni, owo nla ni ko ba gba lati fi ẹmi ọlọla Akin-Olugbade silẹ.

Amọ a gbadura pe ki Ọba oke tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere.