Onila/Agindigbi Communities: Ọdún mẹ́ta ní àwa 18 fi dá #400,000 tí a fi kọ́ ilé ìwé

Ìjọba ìpińlẹ̀ Kwara dá owó tí àwọn obí márundínlọ́gbọ̀n fi kọ́ ilé Ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ wan pada

Oríṣun àwòrán, Kwara Govt

Ìjọba ìpińlẹ̀ Kwara, Abdulrahaman Abdulrazaq ti sàbẹ̀wò ilé iwé alákọbẹ̀rẹ̀ Nomadic ti Agindigbi àti St Luke LGEA oníla lẹ́gbẹ̀ẹ́ Agbamu níjọba ìbílẹ̀ Irepodun, ìpínlẹ̀ Kwara.

Gómínà lọ síbl láti lọ sẹ àdápada owó ti àwọn òbínrin márùndílọ́gbọ̀n kan ti náà lati fi kọ ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ wọ́n ni abúlé náà.

Sáájú ni Ẹ̀ka BBC ti ṣe àbẹ̀wò sí ìlú náà níbi tí láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu wò lórí bi wọ́n ṣe kọ yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ ojúlé mẹ́ta, nígbà ti ilé ìwé kejì ń kọ tíwọn lọ́wọ́, wọ́n tí n dá owó náà pamọ́ láti ọdún 2017

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara nígbà tó de ìlú náà ló sọ fún wan pé, kí wọ́n sọ iye ti wọ́n ti na lórí kíkọ́ ilé Ẹ̀kọ́ náà tọ sí fún ìlú kọ̀ọ̀kan ní ẹgbẹ̀rún lọ́na ẹdẹ́gbẹ̀ta Náírà.

Gómínà fí ìdúnu rẹ̀ hàn fún ìgbésẹ̀ akin ti àwọn obìnrín náà gbé láti ṣe iṣk ribirni tí wọ́n ṣe lórí ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọ́n.

Báwo ni ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀?

Àwọn obìnrin tó ṣe àkọ́jọpọ̀ owó yìí sàlàyé pé, ilé ìwé tí àwọn ọmọ náà ń lọ tẹ́lẹ̀, bí òòrùn bá ràn orí wan ni, bí ojò bá rọ̀ orí àwọn yìí náà ni gẹ́gẹ́ bi Deborah Aweda ọkan lára àwọn obí tó n dá owó náà ṣe sọ.

Arabinrin Aweda ni àwọn obìnrín márùndínlọ́gbọ̀n bẹ̀rẹ̀ si ni yọ ẹgbẹ̀run méjì nínú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá Nàìrà ti ìjọba àpapọ̀ ń fún wọ́n n lósoo'sù, àti pé ọdún mẹ́ta ni àwọn fi dá #480,000 tí àwọn sì bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ rẹ̀.

Ní ti ìlú Keji, àwọn obìnrín méjìdílógún ló darapọ̀ tí wan sì ń dá ẹgbẹ̀run méjì àbọ̀ lóṣooṣù, àwọn pẹ̀lú lo ọdún méji kí wọ́n tó kọ tan, wọ́n ni #400, 000 ni àwọn ri kójọ, lẹ́yìn ti wọ́n kọ ilé náà tán ni wọ́n tún gba àwọn olùkọ́ méjì tó n kọ́ àwọn ọmọ náà tí wan sì ń san ẹgbẹ̀rún méje náírà fún wọ́n lóṣooṣù.

Lásíkò tó sàbẹ̀wò síbẹ̀, ó ni " mò ń dá owó ti àwọn obìnrin tó kọ́ àwọn ilé ìwé yìí

Oríṣun àwòrán, Kwara state Gov

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ọ̀kan olórí ọ̀dọ́ ní ìliú náà Abolaji Sunday fẹ̀dun ọkàn rẹ̀ hàn pé ijọba tí gbàgbé àwọn ilú náà sińú ìyà àti ìṣẹ́