Omoniyi and Elizabeth Oke Blind Couple in Ado-Ekiti: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú

Omoniyi and Elizabeth Oke Blind Couple in Ado-Ekiti: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú

Ọba alara ni Ọba Oke, ara to ba si wu lo ma n fi ẹda ọwọ rẹ da. Ko si yẹ ki ẹnikẹni ro pe o ti tan fun oun, ti Eledua ba fi dara to wu u.

Eyi ni ọrọ iwuri to ti ẹnu tọkọtaya Omoniyi ati Elizabeth Oke, ti wọn ni ipenija oju jade lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ nilu Ado Ekiti.

Awọn tọkọtaya mejeeji yii ko si jẹ ki ipo ti wọn wa se idiwọ fun wọn lati yan isẹ oojọ kan laayo nitori wọn ni isẹ ọwọ ti wọn n se.

Iyawo lo maa n fi ilẹkẹ da ara to ba wu lati fi se baagi, bata, apamọwọ, apẹ fulawa ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti ọkọ rẹ yo si kiri awọn ọja naa lọ sawọn ọọfisi ati sọọbu.

Awọn tọkọtaya to ni ipenija oju naa ni kii se pe wọn bi awọn mọ ipo yii amọ ipenija lo de lasiko ti awọn wa nile ẹkọ, ti awọn ko si le riran mọ.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn wa n rọ awọn eeyan awujọ lati ye maa ro pe ko yẹ ki iru awọn eeyan to ba ni ipenija bayii jade laye tabi pe o ti tan fun wọn.

Wọn ni Ọba Oke lo fi awọn da ara to wu u, ẹni to ba si le se iranlọwọ fun iru awọn, ko se e, sugbọn awọn si n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun isẹda awọn.