Ìjọba Eko ti ń lu ọkọ̀ 88 tà ní gbàǹjo ni Alausa ni Ikeja

Moto

Wo ọnà tí olè gbà jàǹfàní ọkọ́ lọ́wọ́ ìjọba Eko kí ilẹ̀ ò í tó ṣú

Awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko fẹ lu ọkọ mejidinlaadọrin ta ni gbanjo lẹyin ti awọn to ni wọn ti yaafi wọn fun ijọbanitori oniruuru ofin irina ọkọ ti won tapa si.

Lọjọru ni too waye gege bi ohun ti alukoro ikọ amuṣẹya lori ọrọ ayika at'awọn ẹsun miran nipinlẹ Eko, Adebayọ Taofeeq sọ.

Ninu atẹjade to fi sita, o ni wọn ti gba iwe aṣẹ ile ẹjọ lori rẹ.

Lara awọn ẹsẹ ti awọn to ni ọkọ naa ṣẹ nigbigba ọna ti ko tọ ati bẹẹbẹ lọ.

Eto irinna ọkọ nipinlẹ Eko laa kalẹ pe ẹnikẹni ti wọn ba mu to n gba ọna ti ko lẹtọ si lati gba yoo jowo ọkọ rẹ fun ijọba nitabi ko tilẹ fi ẹwọn jura sii.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Igba keji niyi ti ijọba ipinlẹ Eko yoo maa lu awon ọkọ ti wọn ba gba lọwọ awọn to rufin irinna ta ni gbanjo. Losu kọkanla ọdun 2020 ni wọn kọkọ ta ọkọ mẹrinlelogoji.

Àkọlé fídíò,

Joe Biden Innauguration: Tani ìyàwó Joe Biden tí yóò jẹ obìnrin akọ̀kọ nílẹ̀ Amẹrika?

Nibayii, iyeoko ti wọn ti lu ta ni gbanjo jẹ mejilelaadọjọ ṣugbọn alukoro ikọ naa ko sọ boya ẹnikẹni ti lọ si ẹwọn.

Àkọlé fídíò,

BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020

Bi ijọba ṣe fẹ lu awọn ọkọ naa ta ni gbanjo loni, ijọba ipinlẹ Eko ti salaye fawọn to ni ọkọ naa pe awọn pẹlu lee darapọ lati ra awọn ọkọ ọhun bi elomiran ko ba naa lowo to ju tiwọn lọ.

Kini awọn ara ilu n sọ nipa bi awọn mọtọ naa:

Awọn ọmọ Naijiria sọrọ ilẹ kun lori igbesẹ ijọba ipinlẹ Eko yii

Nigba ti BBC de ibi ti wọn ti n ta awọn ọkọ naa, ẹnu ya wa bi ero ṣe pọ to nibẹ ni Alausa, ni Ikeja nipinlẹ Eko.

Bi awọn kan ṣe n yin ijọba pe ohun ti wọn ṣe dara.

Ni awọn miran n ni ko dara to lasiko yii

Awọn miran si n kilọ fawọn olugbe ipinlẹ Eko lori titẹle ofin irinna bi o ti yẹ ki wọn ma baa bọ sọwọ.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí