Fulani Herdsmen Killing: Ẹran dídà káàkiri di ẹ̀ṣẹ̀ ní Oyo àti Ogun

Maalu lori ire oko

Oríṣun àwòrán, @Muhammed Gumi

Ijọba ipinlẹ Oyo kede pe o ti di ofin bayii pe awọn darandaran ko gbọdọ da ẹran mọ kaakiri ipinlẹ naa.

Eyi ko sẹyin bi eto aabo ti dẹnukọlẹ ni ilẹ Yoruba pẹlu awọn darandaran ti wọn fẹsun ijinigbe ati ipaniyan kan kaakiri awọn ipinlẹ marun un ni ilẹ Kaarọ Oojire

Akowe iroyin fun Gomina Seyi Makinde, Taiwo Adisa lo sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe awọn darandaran ni anfaani lati ra ilẹ ti wọn yoo ti ma a da ẹran wọn kaakiri ipinlẹ Oyo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn darandaran gbọdọ mọ wi pe, ọrọ aje tara wọn ni ọsin ati katakara ẹran jẹ, nitori naa, ko yẹ ki wọn fi da awọn ẹlomiran laamu.

"Ofin tuntun nipinlẹ Oyo fi idi rẹ mulẹ pe, idokowo ara ẹni ni isẹ darandaran, nitori naa, ijọba gba wọn laaye lati ra ilẹ lọwọ ijọba lati lo fun iṣẹ wọn''

Àkọlé fídíò,

Jude Chukwuka: Wò ó bí oríkì àwọn ìlú Yorùbá ṣe yọ̀ lẹ́nu ọmọ Igbo jú ọmọ onílùú lọ

''Amọ ofin naa ko fi aye gba dida ẹran kaakiri ni igboro kọja aala ti wọn fun wọn ni ori ilẹ tijọba yoo ya wọn lo fun ọdun mẹta, wọn yoo si pada wa ṣe iforukosilẹ miran fun ọdun mẹta mii''

''Ijọba ti kọ fun awọn ọmọde lati ma a da ẹran kaakiri ayafi ki agbalagba kan duro ti wọn.''

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ogun ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati sọ ọ di ofin pe ki awọn darandaran wa ma a fi orukọsilẹ, ki wọn to le ṣiṣẹ nipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Abẹnugan ile igbimọ Aṣofin nipinlẹ Ogun, Olakunle Oluomo naa ti ni o da oun loju pe awọn yoo buwọlu abadofin naa ni Oṣu Keji, ọdun 2021.

Olakunle Oluomo fikun wi pe gbogbo awọn ti ọrọ naa kan, gbọdọ fi ọwọ sowọpọ pẹlu ijọba, ki abadofin naa le kẹsẹ jari.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Ewu ń bẹ pẹ̀lú kíkó Amotekun lọ Oke Ogun-Ibarapa lórí ọ̀rọ̀ Fulani - Baajigan Ilaji Ile

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Baajigan Ilu Ilaji Ile, nijọba ibilẹ Iwajowa nipinle Oyo, Oba Lawal Oyeleye Oyedepo ti woye pe ewu n bẹ loko Longẹ pẹlu bi ijọba ipinlẹ Oyo ti pàṣẹ pe ki igba ẹṣọ eleto abo Amọtẹkun lọ si agbegbe Ibarapa.

Ikọ Amotekun naa nijọba ni yoo lọ dẹkun aawọ to n ṣẹlẹ laarin awọn eeyan agbegbe naa atawon Fulani darandaran.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Baajigan ni ko sí apa ẹni to ka awọn ẹṣọ Amọtẹkun nitori wọn o sí labẹ ijọba ibilẹ.

Kabiyesi Oyedepo sọ pe, awọn ẹṣọ Amọtẹkun ko niru nidi lo jẹ ki ọpọ ninu wọn maa ṣiwa hu s'awọn to ju wọn lọ.

Baajigan ilu Ilaji Ile ṣalaye pe, ati ọga ati awọn ọmọṣẹ Amọtẹkun, iwa kan naa ni gbogbo wọn jọ n hu.

Oríṣun àwòrán, @Muhammed Gumi

"Alaga ijoba ibilẹ kankan ko lagbara lori ẹṣọ Amọtẹkun, awọn mii n ṣiṣẹ daadaa lara wọn ṣugbọn awọn to n huwa aitọ lo pọju ninu wọn," Baajigan ṣalaye.

Ọba Oyedepo ni "laipẹ yii ni a ṣe ìpàdé pọ pẹlu DPO ọga ọlọpaa at'awọn ọtẹlẹmuyẹ ni ijọba ibilẹ Iwajowa, awọn Amọtẹkun ko wa nitori wọn ko si labẹ ijọba ibilẹ."

Iwa ika tawọn Fulani darandaran n hu fun wa l‘Oke Ogun buru jai:

Ọba Oyedepo tilu Ilaji Ile tun ṣalaye fun BBC Yoruba bi awọn Fulani darandaran ti da maalu ba ire oko awọn agbẹ jẹ lagbegbe Oke Ogun.

"Oko agbado eeka mẹwaa ti emi gan an ti mo jẹ ọba da, gbogbo rẹ lawọn Fulani fi maalu jẹ tan.

Àkọlé fídíò,

Ifọrọwerọ pẹlu Gani Adams lori ọrọ Sunday Igboho

Awọn Fulani yii tun maa n da maalu wọ aarin ilu, n ṣe lawọn maalu yii yoo fọn kaakiri ninu ilu, ohun ti wọn n ṣe fun wa buru jai," Ọba Oyedepo lo sọ bẹẹ.

Baajigan ilu Ilaji Ile wa rawọ ẹbẹ sí ijọba apapọ lati wa nnkan ṣe sí ọrọ eto abo to mẹhẹ lagbegbe Oke Ogun nipinlẹ Oyo.

Ẹwẹ, ọgagun ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Oyo kọ lati sọrọ nigba ti BBC Yoruba pè e lori ago.

O ni oun ni lati gba aṣẹ lọwọ ijọba, ki oun to le sọ ohunkohun nipa ọrọ naa.

Ìkórira ní kò jẹ́ kí alátakò rí aáyan mi lórí ààbò Oke Ogun àti Ibarapa - Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/@OfficialSeyiMakinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti fesi lori aayan rẹ lati mu ki eto aabo fẹsẹ rinlẹ lagbegbe Oke Ogun.

Makinde, ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin, Taiwo Adisa fisita salaye pe, lodi si ero awọn ẹgbẹ oselu alatako nipinlẹ naa, oun ti se isẹ takuntakun lẹka eto aabo.

Gomina Makinde ni oun ti ko dara ni bi ẹgbẹ oselu alatako se n tọwọ oselu bọ aifararọ eto aabo lagbegbe Oke Ogun ati Ibarapa, to fi mọ awọn agbegbe miran nipinlẹ Oyo.

"Kedere ni aayan mi han fun araye nidi ipese eto aabo to peye si agbegbe Oke Ogun ati Ibarapa, koda, mo fi ikọ Operation Burst sọwọ sibẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi makinde

Ogunlọgọ awọn ologun, ọlọpaa ati osisẹ aabo ara ẹni laabo ilu, Civil defence lo wa ninu ikọ alabo Operation Burst naa, ti wọn si kun awọn agbegbe mejeeji biba.

Bakan naa ni mo ti fi ikọ awọn ọlọpaa kogberegbe, Mopol sọwọ sibẹ, to si dabi ẹni pe ilu Agọ Are, ni Oke Ogun, gan ni ibujoko wọn wa bayii."

Makinde tun tẹ siwaju pe, ikọ Amotekun gan ti pọ bii esu lawọn agbegbe yii, ti isẹ akin ti wọn n se nibẹ si ti bẹrẹ si so eso rere.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho: N kò fẹ́ oyè ọ̀gá àgbà páta fún ikọ̀ Amotekun nílẹ̀ Yorùbá

O ni iwa tẹnbẹlẹkun, ikorira ati inunibini ni ko jẹ ki awọn alatako ri ọpọ aseyọri ijọba oun lẹka eto aabo naa, ti wọn si mọọmọ diju lati ri.

O wa mẹnuba awọn ọrọ to n tẹnu awọn eekan ninu ẹgbẹ oselu APC jade, to fi mọ Minisita feto ere idaraya, Sunday Dare, gẹgẹ bii eyi to ba ni ninujẹ.

" O se ni laanu pe iru eeyan to wa ninu igbimọ alakoso ijọba apapọ ti ko se aseyọri kankan lẹka eto aabo ilẹ Naijiria naa n sọrọ.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

Amọ o se pataki ka jẹ ko mọ awọn aseyọri wa lẹka eto aabo, bo tilẹ jẹ pe a ko fẹ maa ba gba ọrọ bi ẹni gba igba ọti."

Makinde wa sọ fun awọn alatako rẹ pe, dipo ki wọn tọwọ oselu bọ ọrọ aabo yii, ko ba dara ki wọn kẹdun pẹlu awọn eeyan ipinlẹ Oyo nipa gbigbe ero gidi kalẹ lati mu agbega ba ipese eto aabo to pegede.

N kò le ṣàtìlẹyìn fún arúfin láti tán ìṣòro ètò ààbò - Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Gomina ipinlẹ Oyo, Enginia Seyi Makinde ti salaye pe ijọba oun ko le gbinyanju lati fopin si isoro aifararọ eto aabo nipa sise atilẹyin fawọn eeyan to n tẹ ofin loju.

Gomina Makinde, sisọ loju ọrọ naa lasiko to n sọrọ nibi ipade to waye nilu Akure laarin awọn gomina ilẹ Yoruba ati ẹgbẹ darandaran Miyetti Allah.

Makinde fikun pe isoro eto aabo ko le tan nilẹ tijọba ba se atilẹyin fun ẹni to ba n ru ofin lọwọ ara rẹ, to si n koro oro lai bọwọ fun ofin sawọn eeyan to gba pe wọn huwa aidaa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Makinde ni oun ko le se atilẹyin fun iru ẹni bẹẹ, to n huwa to le sọ orilẹede yii sinu ogun ẹlẹyamẹya , nitori o yẹ ka le mọ ohun ti yoo gbẹyin iru isẹlẹ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

O ni oun yoo yan lati se atilẹyin fun awọn agbofinro nipinlẹ oun ni, lati pese awọn eto iranwọ fun wọn, ti yoo jẹ ki wsn se isẹ wọn doju ami.

Gomina ipinlẹ Oyo tun sọ siwaju pe oun yoo se iranwọ fun ibagbepọ alaafia laarin awọn alamuleti oun nipa sise iwuri fun awsn eeyan ipinlẹ Oyo lati maa gbe pọ ni alaafia.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

O ni awsn yoo dijọ koju ọta awọn papọ ni, ti wsn jẹ ọdaran to wa ninu ẹya gbogbo, toun yoo si tun maa pese anfaani fawọn araalu, lọna ati mu ikayasoke ku laarin wọn.

Ẹ̀yin èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo, mìmì kan kò lè mì yín lónìí- Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde sọ pe oun ti gbọ nipa awọn kan to n pin iwe fawọn Fulani lati kuro lori ilẹ wọn ni ipinlẹ Oyo.Ìjọba Oyo korò ojú sí ìròyìn tó ń jáde pé káwọn èèyàn Ibadan ó gbélé nítorí Igboho

Ti ẹ o ba gbagbe, ajafẹtọ Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti kọkọ fawọn Fulani to wa ni agbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo lati kuro lori ilẹ ti wọn wa lori ẹsun pe awọn lo wa nidi iṣẹlẹ ijinigbe ati iṣekupani to n ti waye kaakiri ipinlẹ naa.

Makinde ní ẹnikẹ́ni tó bá dúnkokò mọ́ Fulani láti kúró lórí ilẹ̀ Oyo yóò fojú winá òfin

Amọ, Makinde ni iwe ofin orilẹede Naijiria laa kalẹ pe awọn ọmọ Naijiria ni ẹtọ lati maa gbe lalaafia nibi kibi to ba wu wọn kaakiri orilẹede yii.

Gomina ipinlẹ Oyo ni iwe ofin Naijiria yii ni oun bura pe oun ko ni tapa si gẹgẹ bi gomina.

''Ẹnikẹni to ba fi ipa mu ẹnikẹni lati kuro lori ilẹ ti wọn n gbe nipinlẹ Oyo yoo foju wina ofin,'' Makinde ṣalaye.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Gomina rọ ẹnikẹni to ba n gbero lati dunkoko mọ ẹnikẹni lati kuro nibi ti wọn n gbe wi pe ki wọn lọ ki ọwọ mọ bọ aṣọ.

Makinde ni ''Hausa tabi Fulani to n wa ibi ti yoo ti ko ẹran wọn jẹ oko kọ ni ọta wa nipinlẹ Oyo.'

Awọn ọta wa nipinlẹ Oyo kii ṣe awọn agbẹ to n dako lati jẹ ati lati ta fun araalu.

''Ijọba wa n gbiyanju lati wa egbo egbo dẹkun fawọn janduku agbebọn atawọn ọdaran to n ṣọṣẹ ni ipinlẹ Oyo.

Bakan naa ni Makinde ke pe awọn lọbalọba lati maa gba ẹnikan kan laaye lati lo wọn da alaafia to wa ni ipinlẹ Oyo ru.

Makinde tun kepe awọn alaga ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Oyo lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn lọbalọba atawọn agbofinro lati rii pe alaafia jọba.