Big breast: Damilola Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Big breast: Damilola Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Ariwo ọyàn ńlá ló máa ń tẹ̀lẹ́ mi ní gbogbo 'bus stop'- Damilola Tosin Adegboro

Leyin iforowanilenuwo BBC pẹlu Remi Fatolu, ọpọ obinrin miran to lọyan naa tún ti jáde sita sọrọ soke nipa idẹyẹsi ti oju wọn n ri.

Damilola Adegboro
oyan nla

Damilola Oluwatosin Adegboro ati Oluwaseun Amoo jade sita wa sọ idẹyẹsi ti awọn n koju nitori ọyan aya wọn bo ṣe tobi to.

Oluwatosin ni orin Ọlọmurọrọ maa wolẹ ni awọn kan gana an ma n kọ fun oun ni eyi to jẹ orin aalọ apagbe to ṣafihan obinrin to lọyan.

Remi Fatolu ni inu oun dun pe oun ṣe ifọrọwanilẹnuwo naa pelu BBC nitori pe nkan yi pada pẹlu oju ti awọn eeyan fi n wo oun ni awujọ.Remilekun Fatolu bú sẹ́kún fún ohun tó ti pàdánù láyé torí ọyàn ńla rẹ̀.

Tosin Adegboro ni oju onidọti ni ọpọ ọkunrin fi n wo awọn to lọyan, ṣugbọn irọ ni eyi.

oyan nla

Ọpọ ọkunrin lo wu lati maa fẹ awa ti a ni ọyan nla ṣugbọn wọn ko fẹ gbe wa silẹ bii iyawo- Oluwatosin Adegboro.

Awọn obinrin miran maa n bẹbé pe ki n fun awọn ni diẹ lara ọyan mi ni, ọyan naa ti su mi.

Wọn mẹnuba awọn ipenija ti wọn n ri lawujọ ati eebu lọdọ awọn obinrin miran lori ọyan nla wọn.

Tosin ni ọpọ igba ni oju maa n ti oun nitori ọyan nla naa.

oyan nla

Mi ò kí ń fẹ́ ya fọ́tò tabi ki n jade kuro nile nitori eèbú nipa ọyan nla ti mo ni- Tosin Adegboro

Ọpọ maa n jẹ ko dabi pe iwọ lo da ara ẹ pẹlu ọyan nla tabi ohun to wu eeyan ni.

Remi Fatolu gab awọn obinrin to ni ipenija yii nimọran lati jade sita sórọ ki wọn si gab kadara ki ara wọn le fuyẹ.

oyan nla

Oluwaseun Amoo ni ki awọn eeyna dẹkun idẹyẹsi obinrin to ba ni ọyan nla nitori pe ko rọrun rara.

Oluwatosin Adegboro ni ko wu ẹni to ni ọyan nla naa bẹẹ nitori pe oun kọ lo da ara rẹ ati pe ọrọ awọn eeyan maa n fa ironu ati ibanujẹ ti eeyan ko ba ṣọra.