Alleged threat to life: Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) káwọ́ sẹ́yìn rojọ́ lórí ẹ̀sùn ìdúnkookò láti gbẹ̀mí ìyá rẹ̀''

couple

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán,

Ija kò dọlà, orúkọ lo n sọ ni

Ọmọkunrin kan, Quadri Taiwo ti dero ileẹjọ niluu Eko lori ẹsun pe o n dunkoko lati gbẹmi iya rẹ.

Taiwo ẹni ọdun mẹtadinlogun kawọ sẹyin rojọ nileẹjọ majisireeti ni Ikeja lọjọ Aje ọjọ kinni, oṣu keji, ọdun 2021 yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fẹsun kan Taiwo pe o n dunkoko lati gbẹmi iya rẹ ati pe o n fa wahala eyi to lodi si ofin ipinlẹ naa.

Amọ, Taiwo sọ fun ileẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Olupẹjọ ASP Kehinde Ajayi ṣalaye fun ileẹjọ pe Taiwo oṣu kọkanla ọdun 2020 ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ni opopona Balogun lagbegbe Orile-Agege.

Ajayi ni Taiwo dunkoko mọ iya rẹ, arabinrin Mojisola Taiwo lẹyin ede-ai-ede laarin awọn mejeeji.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Bakan naa ni ASP Ajayi sọ pe Taiwo ko gba alaafia laaye lẹyin to fi oriṣii atẹjiṣẹ eebu si iya rẹ.

''Lẹyin iwadii ti a ṣe ni a to fi ọwọ ofin mu Taiwo,'' ASP Ajayi ṣalaye.

Àkọlé fídíò,

Tolulope Adeleke Aire: Mo wòye pé àwọn ọkùnrin Nàìjíríà kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìtọ́jú ọmọ tu

Adajọ majisireeti, Arabinrin A.O. Ajibade gba beeli N50,000 fun Taiwo pẹlu oniduro kan.

O sun ẹjọ naa siwaju titi di ọjọ kọkanla, oṣu keji.

Àkọlé fídíò,

Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ