Tony Momoh: Mínísítà ètò ìròyìn nígbà kan rí jáde láyé lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin

Tony Momoh

Oríṣun àwòrán, Twitter/Atiku Abubakar

Minisita eto iroyin ati aṣa tẹlẹ ri lorilẹede Naijiria Tony Momoh ti jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọrin.

Awọn to sun mọ oloogbe naa lo sọ nipa iku rẹ fawọn akọroyin.

Wọn ni nile rẹ to wa niluu Abuja ni minisita eto iroyin tẹlẹ ti jẹ Ọlọrun nipe.

Ọpọ awọn eekan ilu atawọn olosẹlu lo ti ṣedaro Ọgbẹni Momoh.

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Atiku Abubakar ṣapejuwe Momoh gẹgẹ bi eniyan to dara.

Atiku fọrọ ikẹdun ranṣẹ si idile Momoh nigba to gbadura pe ki Eleduwa tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

Momoh di ipo minisita eto iroyin ati aṣa mu laarin ọdun 1986 si 1990 lasiko ijọba ologun Ibrahim Babangida.