US Mission in Nigeria: Ilẹ̀ Amerika nílò olùkọ́ èdè Yorùbá, wo bí o ti lè forúkọ sílẹ̀ níbí

Aarẹ Joe Biden ati Kamala Harris

Oríṣun àwòrán, Twitter/Joe Biden

Ileeṣẹ aṣoju ijọba ilẹ Amerika lorilẹede Naijiria ti kede pe orilẹede Amẹrika nilo awọn olukọ ede Yoruba ati Hausa ni U.S.A.

Ẹka ileeṣẹ aṣoju ijọba Amẹrika to n ri si ọrọ iroyin sọ pe aye ti ṣi silẹ fawọn ọmọ Naijiria to ba kun oju oṣunwọn lati kọ ede ati aṣa Yoruba pẹlu Hausa lawọn ileewe giga fasiti l'Amẹrika lati fi orukọ silẹ fun eto naa.

Ọjọ kinni oṣu keji ọdun 2021 yii ni aye ṣi silẹ fawọn eeyan lati maa forukọ silẹ fun eto naa.

Ọjọ kinni oṣu kẹfa ọdun ni eto iforukọ silẹ fun eto naa yoo wa sopin.

Ẹka ileeṣẹ aṣoju ijọba Amẹrika to n ri si ọrọ ede ilẹ okeere, ''Foreign Language Teaching Assistant Programme (FLTA)'' lo gbe ikede ọhun jade.

Ajọ FLTA ni eto naa wa lati fawọn ọdọ olukọ ilẹ okeere lati wa kọ awọn akẹkọọ l'Amẹrika ni ede ati aṣa Yoruba.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Ajọ naa tun ṣlaaye pe eto yii yoo fawọn to ba nifẹ si eto ọhun lati kẹkọọ sii ipa iṣẹ olukọni.

Ajọ FLTA tun ni eto ọhun yoo tun jẹ ki oye ede oyinbo ye wọn sii, ati pe wọn yoo tun lanfaani lati mọ nipa aṣa ilẹ Amẹrika.

Oju opo agbọrọkaye ilẹ Amerika

Oríṣun àwòrán, Twitter/US Mission in Nigeria

Yatọ si ẹkọ mii ti wọn yoo lanfaani lati kọ, awọn to ba pegede fun eto ọhun yoo maa kopa ninu itakurọsọ lori ede Yoruba ati Hausa.

Wọn yoo tun lanfaani lati kopa ninu ifọrọwerọ lori aṣa ati ede ti wọn ba n kọ.

Oju opo yii(https://apply.iie.org/FLTA2021) ni o ti le forukọ silẹ lati lọ kọ ede Yoruba tabi Hausa l'Amerika.