Learning Yoruba: Akọmọlédè àti Àṣà Yorùbá gbé oríkì yẹ̀wò

Learning Yoruba: Akọmọlédè àti Àṣà Yorùbá gbé oríkì yẹ̀wò

Laye atijọ to si tun n ṣẹlẹ titi di oni, eeyan le da gbogbo ti apo rẹ silẹ bi o ba gbọ ti oriki rẹ n lọ to si n wọ ọ lakinyẹmi ara.

Aṣa àti iṣe ilẹ kaaro o jiire ni Oriki. Ewi alohun ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ni pẹlu.

Yatọ fun ki a kan maa fọ girama lati ṣalaye itumọ oriki, ko si eeyan ti o gbọ oriki rẹ ti ori rẹ ko ni wu.

Amọ ṣe ẹ mọ wipe kii ṣe eeyan tabi ilu nikan lo ni oriki?

Iran ni oriki, Oriṣa ni, ẹranko gan ni oriki.

Ni ti orukọ eeyan nikan gaan o pin si meji. O lee jẹ oriki abisọ tabi amutọrunwa.

Oriki pọn aṣa Yoruba le pupọ pupọ, agbe aṣa ga si ni. Kkoda ẹ lee ri aṣa ati iṣe ilu kan ninu oriki wọn.

Ohun ti ẹ ko gbọ ri nipa eeyan kan tabi ilu lee ṣuyọ sii yin nigba ti ẹ ba farabalẹ gbọ awọn ọrọ oriki rẹ.