Benin Republic: Ìjọba sọ̀rọ̀ lórí ìròyin tó ní Benin fẹ́ di ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ Nàìjíríà

Aarẹ Benin, Patric Talon ati Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Government of Nigeria

Ọpọ ọmọ Naijiria lo sọ ero wọn boya wọn fẹ ki orilẹede Benin Republic di ọkan lara awọn ipinlẹ to wa lorilẹede yii.

Niṣe lori ayelujara gbona giri giri lẹyin ti ọgọọrọ eeyan n gba ọrọ naa bi ẹni n gba igba ọti lori Twitter ati Facebook lọjọ Satide.

Iroyin kan lo kọkọ sọ pe minisita ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama ṣalaye pe Aarẹ orilẹede Benin, Patrice Talon sọ erongba rẹ pe awọn ṣetan lati di ipinlẹ kẹtadinlogoji ni Naijiria.

Amọ, awọn Naijiria sọ ti inu wọn lori Twitter ati Facebook lori ọrọ naa.

Ọpọ eeyan lo sọ pe kaka ki kiniun ṣe akapo ẹkun, ki onikaluku maa ṣe ọdẹ tiẹ lọọtọọ.

Wọn ni ọrọ Naijiria gan an ti too gbọ, wọn sọ pe ki orilẹede Benin wa laye rẹ.

Sẹnẹtọ Shehu Sani atawọn ọmọ Najiria mii faramọ pe ki Benin Republic darapọ mọ Naijiria.

Ṣugbọn Sani ṣe ikilọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ tumọ ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ ni Naijiria lede Faranse fun awọn eeyan Benin.

Ẹka ileeṣẹ ijọba orilẹede Naijiria to n ri si ọrọ ilẹ okeere ti fesi pe ko si ohun to jọ bẹẹ pe Benin Republic fẹ di ipinlẹ kẹtadinlogoji ni Naijiria.

Ninu atẹjade to fi sita loju opo Twitter rẹ, ilẹẹṣẹ ijọba naa ni orilẹede Naijiria ko ni erongba lati sọ Benin di ọkan lara ipinlẹ ni Naijiria.

Ijọba sọ ninu atẹjade ọhun pe awọn kan lo ṣi ọrọ ti minisita ọrọ ilẹ okeere sọ gbọ.

Atẹjade ọhun ṣalaye pe ohun ti Ọgbẹni Onyeama sọ ni pe Aarẹ Muhammadu Buhari ati aarẹ Benin fẹ ki ajọṣepọ to wa laarin Naijiria ati Benin tun dan mọran sii.