Airforce Plane crash in Abuja: Iléeṣé ológùn ti ń sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Isinku awọn ologun to ku ninu baalu

Oríṣun àwòrán, Channels

Ẹkun ko ṣee pa mora ni ibi itẹ oku National Military Cemetery ni Abuja nibi ti ile iṣẹ ologun Naijiria ti n si oku awọn meje to papoda ninu baalu to ja lọjọ Aiku.

Awọn Sagẹnti naa wa lara awọn to wa ninu ọkọ baalu Beechcraft King Air 350 ti ile iṣẹ ogun ofurufu eyi to ja ni ilu Bassa ti ko jina si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe ti Abuja lasiko ti wọn lọ fun iṣẹ ogun kan Lara awọn to wa nibi eto isinku naa ni Minisita eto abo, Bashir Magashi, awọn ọga awọn ologun mii ti ọga awọn ọmọ ogun alaabo, Major General Lucky Irabor dari.

Àkọlé fídíò,

Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi

Awọn mọlẹbi awọn oloogbe naa wa nibi itẹ oku nibi ti ko ti si oju ẹni kankan to gbẹ tabi da furu ayafi pẹlu omije tori awọn ẹni ire to lọ.

Awọn ọmọ ologun meje to ku ninu ijamba ọkọ ofurufu ni Ọjọ Isinmi yoo wọ ka ilẹ sun ni Ọjọbọ, Ọjọ Karundinlọgbọn, Oṣu Keji , ọdun 2021.

Ileeṣẹ ọmọogun ofurufu ni Naijiria lo fi iroyin yii lede ni Ọjọọru lasiko ti wọn n ba awọn oniroyin sọrọ.

Ni itẹ awọn akọni ti orilẹede Naijiria ni wọn n sin awọn meje ọhun si ni agbegbe Lugbe, lọna Airport Road, ni ilu Abuja.

Àkọlé fídíò,

'Tí mi ò bá rí ògùn rà fún ọmọ mi, á máa gé ara rẹ̀ jẹ tí ẹ̀jẹ̀ yóò máa ṣàn'

Ọkọ ofurufu, Beechcraft King Air B350i ti wọn wa naa lo taku looju ofurufu, to si da ijamba ọkọ to pa gbogbo awọn to wa ninu ọkọ ofurufu ọhun.

Awọn akọni to ku ọhun ni ọmọogun Haruna Gadzama, ọmọogun Henry Piyo, ọmọogun Micheal Okpara, ọmọogun Bassey Etim, ọmọogun Olasunkanmi Olawunmi, ọmọogun Ugochukwu Oluka ati ọmọogun Adewale Johnson.

Oríṣun àwòrán, icirnigeria

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria jake jado lo kẹrora awọn akọni ti wọn ku iku gbigbona naa.

Bakan naa ni Adari Ikọ Ọmọogun Ofurufu ni Naijiria, Air Vice Marshal Isiaka Amao ti pe fun iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Ọgagun naa fikun wi pe awọn ọmọogun ti wọn ku naa ṣẹṣẹ kuro ni ilu Minna, ni ipinlẹ Niger nibi ti wọn ti lọ ṣewadii lori ọna ati doola ẹmi awọn

akẹkọọ mejilelogoji ati awọn olukọ ti awọn aginigbe ko lọ kuro ni ileewe wọn ni Government Science College, Kagara, ipinlẹ Niger lasiko ti wọn ṣe ikọlu sibẹ.

Mo ri bí bàálú náà ṣe ń tiraka kó má ja lulẹ̀ ṣùgbọn ó pàpà ja náà ni- Èèyan tó ṣojú rẹ̀ kòró

Oríṣun àwòrán, @wyrelessng

O ṣoju mi koro kan ti sọ pe atukọ baalu ileeṣẹ ologun ofurufu to ja lulẹ niluu Abuja gbiyanju ki iṣẹlẹ naa ma waye ṣugbọn omi pọ ju ọka lọ fun un.

Nigba to n ba BBC sọrọ, o ni oju oun gan ni baalu naa ṣe ja lulẹ ti ina si ṣẹyọ lara rẹ.

O ṣalaye pe "mo ri bi baalu naa ṣe n tiraka ko ma ja lulẹ nitori atukọ rẹ gbiyanju lati pada si papakọ ofurufu ṣugbọn o papa ja naa ni."

"Lẹyin ti baalu naa ja tan ni ina ati eefin ṣọ lara rẹ."

Obinrin ọhun sọ siwaju si pe, ṣe ni omi bẹrẹ si n bọ loju oun ti oun si n kigbe ikunlẹ abiyamọ lẹyin iṣẹlẹ naa.

Gẹgẹ bii ohun ileeṣẹ ologun sọ ṣaaju, ẹmi meje lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣẹyin?

Ẹ̀mí méje lói sọnù nínú ọkọ̀ òfúrufú ọmọ ogun tó já lulẹ̀ l'Abuja - NAF

Oríṣun àwòrán, @bellokambra1

Ọọfisi alukoro ileeṣẹ ologun ofurufu Naijiria ti kede pe eeyan meje lo dero ọrun lẹyin ti baalu ileeṣẹ naa kan ja niluu Abuja lọjọ Aiku.

Alukoro ileeṣẹ ọhun, Air Vice Marshal Ibikunle Daramola lo fidi iroyin naa mulẹ loju opo Twitter rẹ.

O ni "A fẹ fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni baalu ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu Beechcraft KingAir B350i ja lasiko to n pada si Abuja lẹyin ti ẹnjini rẹ kọṣẹ."

"Awọn oṣiṣẹ pajawiri ti wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ, ṣugbọn o ṣeni laanu pe eeyan meje lo ba iṣẹlẹ naa lọ."

Ibikunle fi kun pe, ọga agba ileeṣẹ ọhun, Air Vice Marshal IO Amao ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa ni kankan.

Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ilu lati ṣe suru nitori awọn yoo tu iṣu de isalẹ ikoko iṣẹlẹ naa laipẹ.

Ẹwẹ, ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ti ba BBC sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ ki baalu naa to ja.

Nkechi Ugochukwu to n gbe lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ sọ pe inu yara ni oun ti gbọ ariwo nla kan.

O ni "ko jẹ tuntun pe mo maa n gbọ iro awọn ọkọ ofurufu ninu yara mi ti wọn ba n kọja, ṣugbọn ariwo eyii yatọ."

O ṣlaye pe awọn eeyan korajọ lẹyin ti baalu naa ja tan ṣugbọn wọn ko foju ri ẹnikankan to ru la, o fi kun pe ọkọ ofurufu ologun ni.

Ki lo tin ṣẹlẹ sẹyin?

Ìròyìn Yàjóyàjó -Ọkọ̀ òfúrufú ọmọ ogun kan ti já lulẹ̀ l'Abuja

Oríṣun àwòrán, @mobilisingniger

Ọkọ ofurufu ileeṣẹ ọmọ ogun kan, King Air 350, ti ja lulẹ niluu Abuja.

Iroyin ni atukọ baalu na ti kọkọ ke gbajare pe ọkan lara irinṣẹ rẹ ti kọṣẹ nigba to n fo bọ lati Minna.

Minisita to n ri si eto irinna ọkọ ofurufu ni Naijiria, Hadi Sirika ti fidii iroyin naa mulẹ loju opo Twitter rẹ.

Sirika ni iṣẹlẹ naa jẹ eyii to buru jọjọ.