PDP Reconciliation: Bukola Saraki ṣe ìpàdé pẹ̀lú gómínà Seyi Makinde, Ayo Fayose lórí ọ̀rọ̀ adarí ẹgbẹ́ PDP

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, Twitter/Saraki

Aarẹ ile igbimọ asofin tẹlẹri, Bukọla Saraki ti ṣe ipade pọ pẹlu gomina ipinlẹ Ekiti ati gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lori ọna ati mu ilọsiwaju ba ẹgbẹ oṣelu PDP.

Saraki lo fi iroyin naa lede loju opo ikansiraẹni Twitter rẹ.

O ni lọna ati mu idagbasoke ba ẹgbẹ oṣelu PDP, oun ṣe ipade pẹlu Fayoṣe ni ọsẹ to kọja.

Bakan naa ni Saraki fikun wi pe ni Ọjọ Ẹti, oṣẹ yii ni oun ṣe ipade pọ pẹlu Makinde ti ipinlẹ Oyo.

O ni oun gbe igbesẹ naa lati ma a gbọ lati ẹnu awọn adari lọna ati dẹku aigbọra ẹniye ni ẹgbẹ oṣelu naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Saraki

''Inu mi dun lati gbọ ọrọ lẹnu awọn alẹnulọrọ ni ẹgbẹ oṣelu PDP''

''Awọn mejeeji ni wọn ṣetan lati ri wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni agbara si ni orilẹede Naijiria''

Ẹgbẹ oṣelu PDP n koju idojukọ lori ẹni ti yoo jẹ asaaju ẹgbẹ oṣelu naa saaju idibo gbogboogbo ọdun 2023.

Ni ọpọ igba ni Fayose ti kọ lati ri Seyi Makinde gẹgẹ bi asaaju ni ẹgbẹ oṣelu PDP.

Fayose ni baba isalẹ ni oun jẹ fun Makinde ninu iṣẹ oṣelu, eleyii ti Makinde kọ lati gbe ori fun un.