Buhari on Zamfara: Buhari ni káwọn agbófinró ó yìnbọn fáwọn tó ń gbé ìbọn AK-47, àwọn ọmọ Nàìjíríà ń pariwo "lórí irọ́"

Buhari atawọn olori ileeṣẹ ọ̀mọ̀dr

Oríṣun àwòrán, Tweeter/@MBuhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ pe ki awọn agbofinro o maa yinbọn si ẹnikẹni ti wsn ba ba ibọn atamatase AK-47 lọwọ rẹ.

Eyi wa lara awọn igbesẹ tuntun ti aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari n gbe lati dẹkun gbọnmọgbọnmọ iwa ijinigbe, ati ikogunjalu to n waye loirlẹede Naijiria.

Agbẹnusọ fun aarẹ, Garba Shehu ni ijọba apapọ ti wa gba bayii lati fi irin koju irin lori wahala to n fojojums gogo bayii lawọn ipinlẹ bii Zamfara atawọn ipinlẹ miran lẹkun ariwa orilẹede Naijiria.

"Aarẹ ti pasẹ fawọn agbofinro lati wọ gbogbo awọn igbo to jẹ ibuba awọn oniṣẹ ibi naa lọ ki wọn si le wọn jade, ki wọn si doju ibọn kọ ẹnikẹni ti wọn ba ri nibẹ pẹlu awọn ohun ija oloro bii AK-47".

Àkọlé fídíò,

Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

Shehu Garba tun jẹ ko di mimọ pe idi ti aarẹ Buhari fi paṣẹ pe ko gbọdọ si baluu kan ti yoo tun fo mọ nipinlẹ Zamfara.

O ni eyi ko ṣẹyin lẹyin iwadii awọn ọtẹlẹmuyẹ to fihan pe awọn baluu aladani kan n fo wọ ipinlẹ naa lati ko nnkan ijagun oloro fawọn apanilẹkunjaye naa.

Sugbọn awọn ọmọ Naijiria ti n fi ero wọn han lori eyi ti ero wọn si ṣe ọtọọtọ lori rẹ.

Oríṣun àwòrán, facebook/screenshot

Àkọlé fídíò,

Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala

Bi awọn kan ṣe n bi aarẹ leere boya o ti ṣeto awọn ohun ija to lee koju eyi tawọn sbayejẹ yii n ko dani, fawọn agbofinro lawsn miran n pariwo pe ileri bẹẹ kii n fi ẹsẹ mulẹ.

Ninu ọrọ tirẹ loju opo BBC News Yoruba ni facebook,

Oríṣun àwòrán, Screenshot/facebook

Àkọlé fídíò,

Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun