Sasa market ibadan: Èèyàn méje dèrò àtìmọ́lé nítorí rògbòdìyàn wáyé nílùú Ibadan

aworan ara awọn ohun ti wọn bajẹ nibi wahala naa

Oríṣun àwòrán, Arakunrin akeredolu/twitter

Ile ẹjọ Majistreeti Iyaganku tọ n bẹ nilu Ibadan ti paṣẹ l'Ọjọbọ pe ki wọn sọ awọn ọkunrin meje kan si atimọle Abolongo to n bẹ l'Ọyọ lorii ẹsun ṣiṣẹ dukiya lofo ati iṣekupani lasiko rogbodiyan to waye ninu ọja Ṣaṣa.

Ileeṣẹ ọlọpaa gbe Tajudeen Oladunni, ẹni aadọta ọdun; Saburi Lawal, ẹni ọdun mẹtadinlogoji; Ojo Joshua, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn; Adekunle Olanrewaju, ẹni ọdun mejidinlogoji.

Pẹlu Olagunju James, ẹni ọdun mẹrinlelogoji; Rasaq Yahya, ẹni ọdun mejilelọgbọn ati Olaide Olawuyi, to jẹ ẹni ogun ọdun lọ si ile ẹjọ lori ẹsun mẹfa ọtọọtọ to da lori i iditẹ, ṣiṣe dukiya lofo ati iṣekupani.

Àkọlé fídíò,

Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala

Adajọ I.O Osho ko gba ẹbẹ awọn afurasi naa lati gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ mii.

O paṣẹ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa da iwe ipẹjọ wọn pada si ọọfisi awọn agbefọba nipinlẹ Ọyọ fun amọran to peye lori ẹjọ naa.

Oríṣun àwòrán, Arakunrin akeredolu/twitter

Arabinrin Osho wa sun igbẹjọ ọhun siwaju di ọjọ kọkanla, oṣu Karun un, ọdun ti a wa yii.

Saaju ni agbẹjọro fun ijọba, Foluke Oladosu ti kọkọ sọ fun ile ẹjọ naa pe awọn afurasi naa lẹ idi apo pọ lati ṣiṣẹ laabi.

Ọladoṣu ni l'ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun yii, ni nnkan bi i aago mẹwa owurọ ni awọn afurasi ọhun ṣekupa Arakunrin Adeola Shakirudeen lẹyin ti wọn luu bi i ejo aijẹ.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fi ẹsun kan awọn eeyan naa pe awọn afurasi ọhun tun ṣekupa awọn eeyan mọkanlelọgbọn miran.

Àkọlé fídíò,

Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro

Wọn fi kun ọrọ wọn pe awọn afurasi naa dana sun ile meji kan to jẹ ti Arakunrin Adelabu Ibrahim, ti wọn si fi dukiya ti o to bi i aadọta milliọnu naira ṣofo.

Ileeṣẹ ọlọpaa tẹsiwaju wi pe, awọn afurasi naa tun dana sun ile kan to jẹ ti Osuolale Akindele, ti wọn si ba dukiya ti o to ogun milliọnu naira jẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣe alaye pe awọn ẹsun naa tako agbekale ofin ọdun 2000, eyii to n risi iwa ọdaran nipinlẹ Ọyọ.

Àkọlé fídíò,

#EndSars Ogbomoso: Èmí kò ní kí wọ́n pa ọlọ́pàá tó pa Isisaka, ṣùgbọ́n...- Ramota, Iya Isi