Kalashnikov AK-47: Ohun mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìbọn AK-47 rèé

AK-47

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ti to nnkan bii ọjọ mẹta sẹyin ti ọpọ ọmọ Naijiria ti n ke gbajare si ijọba apapọ lati gba wọn lọwọ awọn Fulani darandaran to n gbe ibọn Ak-47 rin kaakiri.

Lara awọn ẹsun ti awọn eeyan fi kan awọn Fulani ọhun ni pe wọn n jinigbe, ti wọn si n gba owo itusilẹ lọwọ awọn eeyan.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n bu ẹnu ẹtẹ lu Aarẹ Muhammamdu Buhari pe ko gbe igbesẹ kankan nipa ọrọ naa.

Koda, awọn kan tilẹ sọ pe Aarẹ ko sọrọ nitori pe oun ni baba isalẹ ẹgbẹ awọn darandaran, iyẹn Miyetti Allah.

Eredi ree ti ọkan lara awọn agbẹnusọ Buhari, Garba Shehu, fi sọ fun BBC pe Aarẹ ti paṣe pe ki awọn ọmọ ogun yinbo fun ẹnikẹni ti wọn ba ka ibọn Ak-47 naa mọ lọwọ.

Shehu sọ pe aṣẹ ọhun jẹ ọkan lara awọn ọna ti ijọba apapọ fẹ gba lati kapa iwa ọdaran ati ijinigbe ni Naijiria.

Ṣugbọn irufẹ ibọn wo gan an ni wọn n pe ni Ak-47 yii?

Eyi ni ibeere ti ọpọ n beere lori ayelujara ni eyi to jẹ ki BBC ṣe iwadii lori ibọn naa.

Àkọlé fídíò,

Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

Awọn ohun marun un to yẹ ki o mọ nipa ibọn AK-47 ree\:

Orukọ ibọn naa:

Orukọ ẹni to ṣe ibọn Ak-47 ni Mikhail Kalashnikov, ọmọ orilẹ-ede Rusia si ni ọkunrin naa.

Wọn ti n lo ibọn Ak-47 lati ọdun 1948 titi di akoko yii.

Orukọ ibọn naa gangan ni Avtomat Kalashnikova, ti awọn kan si n pe ni Kalashnikov.

Àkọlé fídíò,

Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala

Awọn to n lo AK-47

Lara awọn orilẹ-ede ti awọn ọmọ ogun wọn n lo ibọn AK-47 ni: Hungary, India, Indonesia, Iran, Iraq, Israel, Lebanon lai yọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria silẹ pẹlu.

Ṣe AK-47 ba ofin mu?

Ọrọ yii da lori orilẹ-ede ti eeyan ti n lo ibọn naa.

Labẹ ofin Naijiria, o lodi si ofin ki eeyan ti kii ṣe agbofinro tabi ọmọ ogun maa gbe ibọn AK-47 kiri.

Ki eeyan to le maa gbe ibọn AK-47 lọwọ, o ni lati gba aṣẹ lọwọ ijọba, ṣugbọn ọpọ lo n ra ibọna naa ni ọna aitọ kaakiri agbaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọta melo ni Ak-47 le gbe lẹẹkan ṣoṣo?

Gẹgẹ bii iwadii ti ileeṣẹ iroyin military.com ṣe, ibọn AK-47 le yin ọta ẹgbẹta laarin iṣẹju aaya.

Àkọlé fídíò,

Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Bawo ni ibọn yii ṣe buru to?

Awọn onimọ nipa ohun ija oloro sọ pe AK-47 ni ibọn to buru ju, to si le tete gbẹmi eeyan ju ti awọn ologun tii ṣe.

Gẹgẹ bii nnkan ti awọn onimọ nipa eto ilera sọ, ọta ibọn naa kan ṣoṣo le ba ẹya ara eeyan jẹ, o si tun lagbara lati mu ẹmi lọ ni iṣẹju aaya.

Sugbọn nigba miran, eyii da lori ibi ti ibọn naa ba ti ba eeyan ati bi ẹni to yi ibọn ọhun ba ṣe jina tabi sun mọ eeyan si.

Kilode ti ibọn yii ṣe gbajumọ lọwọ awọn agbesumọmi?

Ibọn naa rọrun lati gbe ka.

Eeyan ko si nilo lati kọ ẹkọ rẹpẹtẹ ko to le mọ bi wọn ṣe n yinbọn AK-47, idi ree to ṣe wọnpọ lọwọ awọn aṣẹrubalu tabi agbesumọmi.

Àkọlé fídíò,

Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

AK-47 nilẹ Amẹrika

Gẹgẹ bii itan ṣe sọ, o to ọdun 1950 ki ileeṣẹ ọmọ ogun Amẹrika to mọ nipa ibọn AK-47.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ ogun ilẹ Anmẹrika kii ṣa baa lo ibọn Ak-47 yii, pupọ ninu awọn ọmọ ogun naa lo ni imọ nipa lilo rẹ.