Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èya ara èèyàn

Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èya ara èèyàn

A kò lé sọ pé kí wọ́n má to eegun pẹ̀lú ewé àti egbò mọ́ nítorií pé ó ń ṣiṣẹ́- Ojọgbọn Adebukola Ositelu

Oloye Adimula Kehinde Akinfẹnwa jẹ ọkan lara awọn oniṣegun ibilẹ to n to eegun to ba kan tabi to ba yẹ.

BBC ṣabẹwo lati mọ sii nipa ọna ti wọn n gba lọna ibile lati to eegun.

Oludari ileeṣẹ Adimula Olofin Orthopaedic Home Clinic yii sọ nipa ewe aato ati egungun ẹranko ati ohùn ti wọn n pe pẹlu awọn nkan mii ti wọn fi n jẹ ki egungun pada si aaye rẹ.

Kini iyatọ ti wọn fi n to eegun lọna ibilẹ ati tile iwosan igbalode isinyi?

BBC ba awọn alaisan ti wọn n to eegun wọn lọna ibilẹ sọrọ lori iriri wọn.

Lara wọn ni Abimbola ti eegun ọwọ rẹ kan nigba to n gba bọọlu ati Ogbeni Ogunjide Femi ti eegun rẹ kan nibi ijamba ọkọ.

Ogunjide Femi sọ ohun toju rẹ ti ri nipa iṣẹ abẹ ati itọju miran to ti gba.

Oloye Kehinde Akinfenwa Topatosẹ sọ nipa irufẹ ẹranko ti wọn n lo eegun rẹ fi to ti eeyan ati awọn ẹya ara to yẹ ni lilo fi ṣe ọṣẹ, ipara tabi oogun.

Dokita Adedamola Dada to jẹ Oniṣegun oyinbo naa ba BBC sọrọ lori iṣẹ egungun tito lọna igbalode tile iwosan.

O sọ pataki yiya fọto eegun to kan ṣaaju gbigba itọju kankan.

Onisegun Oyinbo Dada gba awọn eeyan nimọran lati ṣọra fun ewu lilọ kiri lai de ile iwosan ti eegun ẹni ba kan nitori pe o maa n jẹ ki iṣoro titun eegun naa ṣe pọ sii ni.

Bakan naa ni BBC tun kan si Ọjọgbọn Adebukọla Ositelu to jẹ alaga ajọ to n risi ọrọ awọn oniṣegun ibilẹ ni ipinlẹ Eko.

Ojọgbọn Adebukola Ositelu sọ ipa ti eto iṣegun ibilẹ n ko ninu ilera awọn eeyan Naijiria pe a ko le yọ wọn sẹyin.

O menuba ohun to ku ni ṣiṣe fun idagbasoke ona ilana itọju mejeeji ni Naijiria.

Pẹlu irufẹ ajọṣepọ to yẹ ko wa laarin awọn mejeeji.

Produced by Oyeyemi Mustapha