Professor Peller: Aya olóògbé Peller bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ọjọ́ tí ojú ogun le lásìkò tóun àti ọkọ rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ idán

Professor Peller: Aya olóògbé Peller bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ọjọ́ tí ojú ogun le lásìkò tóun àti ọkọ rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ idán

Iyawo gbajugbaja ọlọwọ idan ti gbogbo agbaye mọ, Professor Peller ni Lady Peller bẹẹ naa si ni oun ni alabaṣiṣẹpọ rẹ.

Oun funrarẹ sọ fun BBC Yoruba pe "mo ba Professor Peller ṣiṣẹ́ dáadáa, opidan ni Professor Peller, opidan lemi naa, iṣẹ taa dẹ n ṣe niyẹn".

Lọjọ ti gbajugbaja olorin Afro ọmọ Naijiria, Fela Anikulapo Kuti ku naa ni iroyin tun kan nigboro pe Professor Peller ti di oloogbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọ buruku, esu gbomi mu ni ọjọ ti Professor Peller ge mi si meji:

Alhaja Silifat Abiola Peller ti gbogbo eniyan mọ si Lady Peller ṣalaye ọ̀rọ̀ lori ọjọ buruku ti Eṣu gbomi mu, eyi ti Professor Peller n lo iyawo rẹ lọwọ lati pidan toti baba ge e si meji amọ ti ko tete ri i da pada wa saye.

Iṣẹlẹ ọjọ naa mu ki awọn eeyan to wa wo iran lẹyin igba naa ti Professor Peller bọ sori itage lati pidan pe Lady Peller lawọn fẹ ri toripe wọn ko ri aaye rẹ lati igba ti opidan ọkọ rẹ ti ge e si meji lori itage.

Ọrọ̀ kunlẹ ti Lady Peller sọ fun akọroyin BBC Yoruba lori ọpọlọpọ ohun to n ru awọn eeyan ati oluworan ọjọ naa loju titi di oni.

Lady Peller sọ fun araye gbọ́ pe "Musulumi gidi lemi, Musulumi gidi ni ọkọ mi" pẹlu bi wọn ṣe n pidan to.

O ni Ọlọrun mọ pe oun fẹ pe e si Aljana naa lo fi jẹ ko wa lori irun Sujud to fi jade laye ti awọn to ṣọ ọ fi ri i pa tori o jẹwọ igba ti kii si ogun kankan lara oun pe "igba tu mo ba n kirun fun ọlọrun mi ni".