Jemila Bio Ibrahim: Àìmọye ìgbà ni mo ti bó lẹ́sẹ̀ ṣùgbọ́n bí ẹṣin bá dá ni mọ́'lẹ̀...

Jemila Bio Ibrahim: Àìmọye ìgbà ni mo ti bó lẹ́sẹ̀ ṣùgbọ́n bí ẹṣin bá dá ni mọ́'lẹ̀...

"Ibẹru yẹn nikan lẹ maa gbe kuro lọkan yin tẹẹ ba fẹ gun ẹṣin".

Jemila Bio Ibrahim jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ "Emirates Equestrians Club" eyi to tumọ si awọn to n gun ẹṣin gba afẹ ni ilu Ilorin.

Ninu fọnran yii, o di mimọ pe iye owo ẹṣin kuro ni keremi koda lawọn orilẹede to ti ni iyi, ẹṣin mii to miliọnu lọna aadọrin naira (70m). Abdulzeez Olayinka Oniyangi ni:

"Ẹṣin mii wa to jẹ 70m, taa ba n sọrọ Argentine Horses, amọ nibi, ẹ lee ri bii 400,0000, 600,000, itọju rẹ ni pataki.

Ẹgbẹ yii gba pe ọna idaraya kan ni gigun ẹṣin nitorinaa wọn n fẹ obinrin sii.