Fake Lemonade in Kano: Ọwọ́ ìjọba tẹ èèyàn mẹ́rin lórí títa ayédèrú ohun mímu tó ń pààyàn

Ibudo ti wọn ti n tọju ajakalẹ arun ni Kano

Ajọ to n daabo bo ẹtọ araalu nipinlẹ Kano ṣọ pe, ọwọ ti tẹ eeyan mẹrin to ta ayederu ohun mímu fun awọn eeyan nipinlẹ naa.

Iroyin sọ pe ṣe ni awọn to mu ohun mimu naa bẹrẹ si ni bì, ti wọn si n tọ ẹ̀jẹ̀ lẹyin ti wọn mu u tan.

Ọga agba fun ajọ naa, Baffa Dan Agundi sọ fun BBC pe, ninu ile kan ti wọn ko ti i kọ tan nijọba ibilẹ Munjibir, ni ọwọ ti tẹ àwọn eeyan mẹrin naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni apo to to ẹẹdẹgbẹta ni wọn fi di awọn nkan mimu naa, ti ọjọ ti lọ lori wọn, àti awọn nkan mii to lewu fun eeyan lati jẹ.

Ọgbẹni Baffa sọ pe "ojúṣe ẹni to jẹ olori ninu awọn ti ọwọ wa tẹ ni lati ko awọn nkan mimu to jẹ ayederu, ati eyi ti ọjọ ti lọ lori wọn, wa fun awọn to ku.

" Koda, diẹ lara awọn nkan ti a ba nibẹ ko jọ nkan mimu. "

O ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa nipasẹ iwadii, lẹyin ti awọn eeyan kan sọ pe ọjà Singha ati Bakin Asibiti, nilu Kano, ni awọn ti ra nkan mimu naa.

Bakan naa ni ileesẹ ijọba to wa fun eto ilera nipinlẹ Kano sọ pe lootọ ni eeyan mẹrin kú, lẹyin ti wọn mu àwọn nkan mimu naa.

Àkọlé fídíò,

Akomolede àti Asa: Mọ̀ si nípa àṣà ìsọmọlórúkọ́ nílẹ̀ Yorùbá àti ìtumọ̀ orúkọ̀ fún ìkókó

Dokita Bashir Lawal, ti ileewosan Abdullahi Wase sọ pe aisan Lassa Fever ni awọn kọkọ ro pe o n ṣe awọn eeyan naa, nigba ti wọn gbe wọn de ileewosan rẹ.

O ni sugbọn, awọn pada mọ pe kii ṣe Lassa.

"Eeyan meji lo ku si ileewosan, meji ku si ile wọn, eeyan bi i 189 si n gba itọju lọwọ ni ileewosan ọtọọtọ nilu Kano."

Agbébọn tún jí ọ̀pọ̀ àkẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti olùkọ́ ní Kaduna gbé lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe awọn agbebọn tun ti ji awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ Rema, nijọba ibilẹ Birnin Gwari nipinlẹ Kaduna gbe lọ.

Bakna naa la gbọ pe awọn olukọ awọn akẹkọọ yii gan wa lara awọn eeyan tawọn agbebọn naa ji gbe lọ.

Ọsan ọjọ Aje ni isẹlẹ naa waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kọmisana feto aabo ati ọrọ abẹle nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan lo fidi isẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fisita fawọn akọroyin.

Awọn alasẹ ko si ti le sọ pato iye akẹkọọ ati olukọ tawọn agbebọn naa ji ko lọ.

Àkọlé fídíò,

Adebunmi Adeyeye: Mo jẹ gbèsè gbọ́múléláńtà, ìdí iṣẹ́ kabúkabú ni mo ti ri san

Ọba alaye kan to kọ lati darukọ rẹ naa fidi isẹlẹ yii mulẹ fun BBC.

Bẹẹ ba si gbagbe, alẹ ọjọ Satide ni awọn agbebọn yii tun gbinyanju lati kọlu ile ẹkọ girama Ikara , ti wọn si gbinyanju lati ji awọn akẹkọọ ibẹ gbe.

Ọba alaye naa ni awọn akẹkọọ ọọdunrun ati meje ni wọn doola wọn lọwọ awọn ajinigbe naa.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.