Niger Attack: Ìjọ̀ba kéde ọjọ́ mẹ́ta láti dárò àwọn èèyàn tó jáláìsí nínú ìkọlù náà

Agbegbe ti ikọlu ti waye ni Niger

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan, eeyan mejidinlọgọta ti jade laye lorilẹede Niger lasiko ti ikọ agbebọna kan kọlu awọn agbegbe to paala pẹlu orilẹede Mali.

Awọn agbebọn naa lo sina ibọn bolẹ sara ọkọ mẹrin to n ko awọn ero pada lati ọja lagbegbe Tillaberi.

Lọwọlọwọ bayii, ko si ikọ adunkoomọni kankan to tii jade sita pe oun lo wa nidi ikọlu naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ sa, ikọ ajijagbara meji lo n ba orilẹede Niger soro bayii, ọkan ninu wọn lo wa niwọ oorun orilẹede naa lẹba ilẹ Mali ati Burkina Faso.

Ikọ ajijagbara keji lo wa ni ila oorun guusu ilẹ Niger nibi to ti paala pẹlu orilẹede wa Naijiria.

Atẹjade kan ti ijọba ilẹ Niger ka sita lori mohunmaworan ilẹ naa salaye pe "ọpọ agbebọn to dimọra, ti ẹnikẹni ko si damọ lo kọlu ọkọ mẹrin to n ko ero bọ lati ọja Banibangou pada wa si abule Chinedogar ati Darey-Daye.

Lẹyin ikọlu wọn, eeyan mejidinlọgọta lo jade laye, ọkan fara pa, ti ọpọ ounjẹ onihoro si sofo danu, bakan naa ni wọn jo ọpọ ọkọ nina, ti wọn si tun gba ọkọ meji sọdọ."

Ijọba Niger wa kede ọjọ mẹta fun idaro awọn eeyan to jalaisi lorilẹede naa lati ipasẹ ikọlu ọhun, bẹrẹ lati oni Ọjọru.

Àkọlé fídíò,

Akomolede àti Asa: Mọ̀ si nípa àṣà ìsọmọlórúkọ́ nílẹ̀ Yorùbá àti ìtumọ̀ orúkọ̀ fún ìkókó

Atẹjade naa wa rọ awọn araalu lati maa fi oju sọri pupọ, ki wọn si maa sọrọ sita pẹlu ipinnu ọkan lati tako iwa ọdaran ni gbogbo ọna.

Ẹ dáábò bo ara yín, a kò le ṣọ́ gbogbo ilé ẹ̀kọ́ Nàíjíríà - Ìjọba àpapọ̀ lahùn

Oríṣun àwòrán, @NigeriainfoFM

Ijọba apapọ ti ke si awọn ọmọ Naijiria lati fi ọwọ gidi mu eto abo ara wọn gẹgẹ bii ọna kan gboogi lati fopin si awọn ikọlu to n waye si awọn akẹkọọ.

Minisita abẹle fun eto ẹkọ, Chukwuemeka Nwajiuba lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin lọjọ Aje, nibi to ti sọ pe ko ṣeeṣe ki ijọba dabo bo gbogbo ile ẹkọ to wa ni Naijiria.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ijọba apapọ ti sọ fun awọn ile ẹkọ lati maa fi gbogbo ohun to jọ mọ ọrọ abo to awọn agbofinro leti.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ifọrọwerọ ọhun, ni wọn ti beere lọwọ minisita naa pe, ki ni ohun gan pato ti ijọba n ṣe lati dabo bo awọn ile ẹkọ lọwọ awọn janduku to n kọlu wọn lemọlemọ.

Àkọlé fídíò,

Akomolede àti Asa: Mọ̀ si nípa àṣà ìsọmọlórúkọ́ nílẹ̀ Yorùbá àti ìtumọ̀ orúkọ̀ fún ìkókó

O ni "eto aabo ṣe pataki lootọ, o si jẹ ohun to jẹ awọn araalu logun, ṣugbọn ijọba ko le daabo bo gbogbo ile."

"Oju ni alakan fi n ṣori, nitori naa ni a ṣe sọ fun awọn ile ẹkọ nibikibi ti wọn ba wa pe, ti wọn ba kofiri ohun to le ṣakoba fun ẹmi ati dukia wọn, ki wọn tete fi to awọn agbofinro leti."

Nwajiuba sọ pe gbogbo ile ẹkọ to wa n Naijiria, yala ti ijọba ni tabi ti aladani, lo ni odi, ṣugbọn eyii ko da nnkan ti awọn awọn eeyan naa ko ba le maa ṣọ ara wọn.

O ni "o yẹ ki awọn eeyan maa ṣọ ara wọn, ki wọn si mu eto aabo wọn lọkunkundun, bẹẹ si ni ki wọn tete maa ke sawọn agbofinro ti wọn ba kofiri ohun to le fi wọn sinu ewu."

Àkọlé fídíò,

Adebunmi Adeyeye: Mo jẹ gbèsè gbọ́múléláńtà, ìdí iṣẹ́ kabúkabú ni mo ti ri san

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Kaduna ti sọ pe awọn olukọ mẹta pere ni awọn janduku kan ji gbe nile ẹkọ alakọbẹrẹ UBE to wa ni Magajin, iyẹn ni ijọba ibilẹ Brinin Gwari, nipinlẹ naa.

Kọmiṣọna to n ri si eto abo abẹlẹ, Samuel Aruwan sọ nibi ipade awọn akọroyin kan pe awọn janduku ọhun ko ri akẹkọọ kankan gbe lọ.

O ti to ọjọ mẹta kan ti awọn ajinigbe ti kọju si awọn akẹkọọ, paapaa labegbe oke ọya, eyii to ti fa ibẹru si ọkan ọpọ obi ati akẹkọọ lati lọ sile ẹkọ.

Iléeṣẹ́ ọlapàá ní iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ láti dóòlà akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì Fásítì Olabisi Onabanjo tí wọ́n jígbé

Oríṣun àwòrán, Olabisi Onabanjo University

Awọn janduku agbebọn ti ji awọn akẹkọọbinrin meji fasiti Olabisi Onabajo to wa ni niluu Ayetoro, ni ijọba ibilẹ Ariwa Yewa nipinlẹ Ogun.

Agbẹnusọ fu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ fun BBC Yoruba pe, ni bii ago mẹsan abọ alẹ ọjọ Aiku ọjọ kẹrinla oṣu kẹta ọdun 2021 yii ni wọn ji awọn akẹkọọ naa gbe nigba ti wọn n pada si ile wọn.

Ọgbẹni Oyeyemi ṣalaye pe aaya bẹ silẹ, o bẹ sare ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi ṣe nitori iṣẹ iwadii ti bẹrẹ ni pẹru lati awọn akẹkọọ naa ri.

''Ọga ọlọpaa ilu Ayetoro gan an lo dari akitiyan ileeṣẹ ọlọpaa lati wa awọn akẹkọnbinrin naa rii.

Awọn ọlọpaa kogberegbe naa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun, a si gbagbọ pe a o ri awọn akẹkọọ naa laipẹ,'' agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye.

Nigba ti BBC Yoruba beere bo ya otitọ ni pe awọn agbebọn ọhun n beere fun aadọta miliọnu owo naira lati fi awọn akẹkọọ naa silẹ, Ọgbẹni Oyeyemi ni oun ko ni fẹ sọrọ lori rẹ.

O ni ọrọ lori owofun awọn ajinigbe le ṣakoba fun iwadii ileeṣẹ ọlọpaa to n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.