Insecurity in Yorubaland: Ọba Tejuosho ní àwọn tó ṣe àpérò àpapọ̀ ọmọ Oodua yẹ kò pe gbogbo oríadé sí ìpàdé

Oríṣun àwòrán, OPC
Ipade apapọ awọn ọmọ Kootu Oojire waye nilu Ibadan ni Ọjọru nilu Ibadan ti se olu ilu ipinlẹ Oyo, lati jiroro lori eto aabo to mẹhẹ ati awọn ipenija mioi to n koju iran Yoruba.
Ọpọ awọn eekanlu nilẹ Yoruba lo bawọn peju sibi ipade naa ninu eyi ta ti ri Alagba Banji Akitoye, Oloye Sunday Igboho ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Sugbọn ọpọ eeyan lo n beere pe ki lo de tawọn ọba alaye kankan nilẹ Yoruba ko fi bawọn peju sibi ipade naa niwọn igba to jẹ pe eto aabo to mẹhẹ yii, awọn gan lo gberu julọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Òpùrọ́ ló pọ̀ nínú àwọn oníṣẹ̀ṣe, olóòtọ́ọ́ wọn ṣọ̀wọ́n - Olugbon
- N kò ní baba ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú, Ọ́lọ́run nìkan ni mo bẹ̀rù - Seyi Makinde
- A ń lọ ṣí ẹnu bodè Yorùbá tíjọba tìpa sílẹ̀, kí oúnjẹ wọlé nírọ̀rùn - Sunday Igboho
- Ẹyọ kan lára agbára tí mo ní, ni mo lò láti mú Wakili - Gani Adams
- A kọ òrìṣà babańlá wa sílẹ̀ ló jẹ́ kí ọ̀daràn darandaran máa pa wá bí ẹ̀fọn - Àwọn Oníṣẹ̀ṣe
- Ìtàn ayé John Magufuli, Ààrẹ Tanzania tọ́pọ̀ èèyàn ń pè ní 'bulldozer'
- Wo ohun tí o kò mọ̀ nípa Ààrẹ Tanzania, John Magufuli tó jáde láyé
- Wo ewu tó rọ̀ ma kí wọn sin ọba tó ṣètùtù nílànà ẹ̀sìn Krìsítẹ́nì àti Islam
Idi ree ti BBC Yoruba fi tọ awọn ọba alaye kan lọ lati sewadi ohun to faa, tawọn ori ade ko se bawọn peju sibi ipade apapọ ọmọ Yoruba naa.
Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi makinde
Nigba to ba BBC sọrọ, Ọba Adetokunbọ Gbadegẹsin Okikiọla Tejuosho, Adabọnyin Ẹkùn Akọkọ, to jẹ ọba ìlú Orile-Kenta, nijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ Ogun, sọ pe ninu iwe iroyin ni oun ti gbọ́ nipa ipade naa.
Ọba Tejuosho ni o dabi pe kii ṣe gbogbo ọba ilẹ Yoruba ni wọn pe si ibi ipade apero to waye nilu Ibadan naa, eyi to da lori eto aabo to mẹhẹ.
O ni "awọn ọba kan ti wọn gbagbọ pe awọn lo di ilẹ Yoruba ni wọn maa n pe si ipade, kii si ṣe emi ni ma a tako nkan ti wọn ba sọ nibẹ ni orúkọ gbogbo ọmọ Yoruba."
Farmers Herders Crisis: Rẹ́rẹ́ rún, ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò lágbègbè Ariwa Yewa
Lori ọrọ idasilẹ orilẹ-ede Yoruba, Ọba Tejuosho sọ pe oun faramọ àbájade ipade naa, to ba ti jẹ pe yoo mu idagbasoke ati ọna abayọ si ipenija eto aabo ba ilẹ Yoruba.
Sugbọn, o ni o gbọdọ gba ọna to yẹ, ti ko ni i fa itajẹsilẹ tabi ogun.
Ijọba, ẹ lo OPC, Amotekun, Fijilante ati ọdẹ ibilẹ fun ipese aabo labẹle
Ẹwẹ, Ọba tejuosho tun ti kesi ijọba apapọ lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ, fijilante, OPC ati Amotekun fun ipese eto aabo to peye.
Ọba alaye naa parọwa yii lasiko to n dunnu si bi awọn akẹkọọ fasiti Olabisi Onabanjo meji se ri idande gba lọwọ awọn ajinigbe.
Oriade naa ni awọn alaabo ibilẹ n sisẹ kara lati gba awọn ọmọ Yoruba to wa ni igbekun silẹ, to si tun tọkasi iyanju wọn lati ri pe tu Alhaji Lookman Onabanjo, tii se onisowo kan ti wọn ji gbe laipẹ yii silẹ.
Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde
O wa se apejuwe awọn ajinigbe naa gẹgẹ bii ẹni ibi ti ko lẹkọọ, eyi ti awujọ kankan ko le fara da nilẹ Yoruba.
Ọba Tejuosho wa gbarata lori pe ko sibi to ni aabo mọ ni tibu tooro ilẹ Yoruba, to si sapejuwe iwa ijinigbe gẹgẹ bii iwa ọdaran to wuwo pupọ.
Bakan naa lo rọ awọn araalu lati maa fi oju sọri nitori ipese aabo to peye jẹ ojuse gbogbo wa.
Gómìnà Yorùbá, ẹ lo ààbò lábẹ́lé láti ṣọ́ ìpínlẹ̀ yín, ẹ má gbára lé ọlọ́pàá - Afenifere
Oríṣun àwòrán, Amotekun Oyo state
Agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, eyi lo mu ki ẹgbẹ Afenifere Renewal Group ARG tun se n ronu jinlẹ lori eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.
Idi si ree ti wọn tun se n kesi awọn gomina to wa lẹkun iwọ oorun Naijiria lati san sokoto wọn ko le ńidi ipese eto aabo to peye fun ipinlẹ wọn.
Ẹgbẹ Afenifere ni ohun taa ba ni, laa naani, o si yẹ kawọn gomina kogiri mọ igbesẹ riro ikọ alaabo Amotekun lagbara, ki wahala to de.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ dáábò bo ara yín, a kò le ṣọ́ gbogbo ilé ẹ̀kọ́ Nàíjíríà - Ìjọba àpapọ̀ lahùn
- Ohun tó ṣe mi rèé nígbà tí mo gba abẹ́rẹ́ àjẹ́sára AstraZeneca - Kọ̀misáná fétò ìlera l‘Eko
- Níbo ní £46,933 owó ìrànwọ́ tí wọn dá fún Sunday Igboho wa?
- Ẹ mú ẹ̀rí tó dájú wá lórí ọ̀rọ̀ Fulani darandaran Wakili, ọlọ́pàá rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo
- Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ti fà kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Grammy tẹ́lẹ̀ rí
- Iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ láti dóòlà akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì Fásítì Olabisi Onabanjo táwọn agbébọn jígbé- Ọlọ́pàá
- Asari Dokubo tó kéde orílẹ̀èdè Biafra lu òfin ìdìtẹ̀ sí orílẹ̀-èdè - Àgbà Amòfin
- Ọwọ́ mi dẹ púpọ̀ ní Ayete, n kò kéde lórí ayélujára ní – Sunday Igboho
"Ẹ pese awọn ohun ija fun wọn, to fi mọ awọn ohun eelo ti wọn nilo ati owo pelu orukọ rere, ki wsn le kaato lati koju ipenija eto aabo to ba suyọ nibikibi lẹkun yii."
Adebunmi Adeyeye: Mo jẹ gbèsè gbọ́múléláńtà, ìdí iṣẹ́ kabúkabú ni mo ti ri san
Bakan naa ni wọn gba awọn gomina nimọran lati sawari ohun eelo labẹle, ti wsn yoo fi ro awọn eeyan wọn lagbara nidi didaabo bo ẹkun yii, kipo gbigbe ara le ileesẹ ọlọpa apapọ.
Nigba to n gbarata lori asa ijinigbe to n di lemọlemọ ni Naijiria, asaaju ẹgbẹ ARG, Olawale Osun ni ko yẹ kawọn gomina sun asunpiye, oju si lo yẹ ki alakan wọn maa fi sọri bayii.
Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta
"O yẹ ko ti ye awọn gomina lẹkun iwọ oorun Naijiria bayii pe ẹyin ni aabo awọn eeyan ipinlẹ yin gberu, ẹ lọ gbaju mọ."
Ẹ mú ẹ̀rí tó dájú wá lórí ọ̀rọ̀ Fulani darandaran Wakili, ọlọ́pàá rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo
Oríṣun àwòrán, Facebook/OPC diary
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe ohun ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori ọga Fulani, Iskilu Wakili atawọn eeyan rẹ meji ti wọn fọwọ ofin mu.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, CSP Fadeyi Olugbenga, Anipr fi sita lọjọ Aje, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Iyakangu ti bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ awọn Fulani ọhun.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn to ba ni ẹri to daju lori ẹsun ijinigbe atawọn ẹsun mii ti wọn fi kan Wakili atawọn eeyan rẹ pe ki wọn mu awọn ẹri naa wa.
- Mo ti gbé Wakili lọ sílé ẹjọ́ rí, adájọ́ ní ká lọ yanjú ọ̀rọ̀ láàrin wa - Baálẹ̀ Itamofin Ayete
- Mò ń lọ ibùdó tí Fulani ti ń wa kùsà ní Idere, màá lé wọn dànù pátápátá - Sunday Igboho
- Àwọn agbébọn láti Òkè Ọya ń wa góòlù ní Ilesa, Owo àti Igangan láì sí ìdíwọ́ - Gani Adams
- Iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ láti dóòlà akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì Fásítì Olabisi Onabanjo táwọn agbébọn jígbé- Ọlọ́pàá
- Asari Dokubo tó kéde orílẹ̀èdè Biafra lu òfin ìdìtẹ̀ sí orílẹ̀-èdè - Àgbà Amòfin
- Ọwọ́ mi dẹ púpọ̀ ní Ayete, n kò kéde lórí ayélujára ní – Sunday Igboho
- Níbo ní £46,933 owó ìrànwọ́ tí wọn dá fún Sunday Igboho wa?
- Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ti fà kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Grammy tẹ́lẹ̀ rí
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ ninu atẹjade naa wi pe awọn ẹri yii yoo ṣe iranwọ lori ati mọ otitọ lori ọrọ naa.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Oyo tun sọ ninu atẹjade naa pe irọ lawọn kan n gbe kiri pe ileeṣẹ ọlọpaa ju awọn to mu ẹjọ awọn Fulani darandaran lagbegbe Ibarapa si atimọle.
Bakan naa lo sọ pe irọ ni pe ileeṣẹ ọlọpaa gbowo ki wọn to fun wọn ni beeli.
Ọga ọlọpaaa Oyo ni iru awọn eeyan to n gbe irufẹ iroyin bayii n tabuku iṣẹ riniribi tawọn ọlọpaa n ṣe nipinlẹ naa.
Ọga ọlọpaa ni ileeṣẹ ọlọpaa Oyo ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn araalu ti wọn ba ni ohun kan tabi omiran to le ṣe iranwọn lori ọrọ abo nipinlẹ Oyo.