Apam Beach Drowning: Wọ́n ti sin òkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ẹ̀dógún náà lápapọ̀

Posi awọn akẹkọ to ku

Bi eeyan ba jẹ ori ahun, yoo sọkun to ba gbọ iroyin nipa iku awọn akẹkọ bii ogun, ti wọn ls luwẹ ni eti okun Apam lọjọ Aiku, ọjọ Keje osu Kẹta ọdun 2021.

Ileesẹ ọlọpaa nilẹ Ghana ti wa fidi rẹ mulẹ pe awọn ti ri oku mẹtala lara awọn akẹkọ naa to ku sinu okun ti wọn ti n luwẹ letikun Apam lọjọ Aje, ọjọ Kẹjọ osu Kẹta.

Atẹjade kan ti ileesẹ ọlọpaa ni Ghana fisita salaye pe meji ninu awọn akẹkọ naa ni wọn ri laaye leti okun ọhun, nigba ti wọn ri oku akẹkọọ mejila.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọga ọlọpaa Irene Oppong to wa ni ẹka to n gbọ ọrọ araalu nilu Cape Coast ni ọkunrin kan, Kwame Akono lo mu ẹsun nipa isẹlẹ naa tọ oun wa.

"Deede aago mẹsan ku ogun isẹju ni ọkunrin naamu ẹsun tọ wa wa pe ọmọ ẹgbọn oun, Joshua Annor, tii se ọmọ ọdun mẹẹdogun lo lọ gba bọọlu leti okun, to si ri sinu rẹ pẹlu awọn ọmọ miran.

Idi niyi ta fi tete morile eti okun naa pẹlu ikọ ti yoo wa awọn ọmọ naa jade, Ọlọrun si ba wa se, a ri Simon Dadzie, ọmọ ọdun mẹẹdogun ati Gogffrey Apperetsie, ọmọ ọdun mẹrinla yọ laaye."

Oppong fikun pe awọn akẹkọ mejeeji yii lawọn tete gbe lọ sile iwosan ijọ Aguda ti Luke fun itọju to yẹ.

Àkọlé fídíò,

Akomolede àti Asa: Mọ̀ si nípa àṣà ìsọmọlórúkọ́ nílẹ̀ Yorùbá àti ìtumọ̀ orúkọ̀ fún ìkókó

O ni awọn oku awọn akẹkọọ tawọn ri ni aarọ ọjọ Aje ni ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹrinla si mẹtadinlogun, ti oku ọmọbinrin meji si wa laarin wọn.

O ni awọn oku awọn ọmọbinrin mejeeji naa lawọn gbe lọ sile igbokusi to wa nile iwosan fun ayẹwo to yẹ, ti iwadi si ti n lọ lọwọ lati mọ iru iku to pa awọn akẹkọ naa.

Àkọlé fídíò,

Adebunmi Adeyeye: Mo jẹ gbèsè gbọ́múléláńtà, ìdí iṣẹ́ kabúkabú ni mo ti ri san

Amọ sa, wọn ti sin oku awọn akẹkọ mẹtala ọhun lapapọ loni ọjọ Isẹgun, kutu hai si lawọn mọlẹbi wọn ti de sile iwosan katoliki Luke nibi ti wọn gbe oku awọn ọmọ naa si.