Dino Melaye: Mo jẹ́ afọ́jú tẹ́lẹ̀, àmọ́ mo ti ríran pé wọn gba wa ni bí Buhari ṣe di ààrẹ

Dino Melaye/Instagram

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye/Instagram

Asofin agba tẹlẹ nile asofin apapọ ilẹ wa, Sẹnatọ Dino Melaye ti n tọrọ aforrijin lọwọ Ọlọrun lori atilẹyin to se fun aarẹ Muhammadu Buhari lati wọle ibo lọdun 2015.

Melaye, lasiko to n kopa lori eto kan lori mohunmaworan Channels lọjọ Ẹti, eyi to gbe ẹda rẹ soju opo Instagram rẹ, lo ti tọrọ aforijin bẹẹ.

Melaye wa se apejuwe bi Buhari se di aarẹ Naijiria gẹgẹ bii "iwa jibiti ati gbajuẹ to tii buru julọ nilẹ Afirika", to si ni kawọn eeyan gbagbe gbogbo ohun tawọn fi tan wọn jẹ lasiko ipolongo ibo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Asofin tẹlẹ naa ni ijọba Buhari ti ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ ni gbogbo ọna, bẹrẹ lati ori eto aabo to mẹhẹ titi de ori aisi ipese awọn ohun eelo amayedẹrun.

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye/Instagram

"Mo tọrọ aforijin lọwọ Ọlọrun ọga ogo to ga julọ, ẹni to da ọrun ati aye ati lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori bi mo se ti Buhari lẹyin lati de ipo aarẹ.

Bawo ni eeyan se le wa ninu ẹgbẹ oselu kan tabi sugba aarẹ pẹlu gbogbo isẹlẹ to n waye lọwọlọwọ ni Naijiria?

Nitori naa, mo kabamọ gidigidi pe mo ti i lẹyin nitori wọn lu wa ni jibiti ni."

Àkọlé fídíò,

Ogbomoso Quitdruplets: Ọ̀kan nínú àwọn ìbarùn-ún jáde láyé lọ́jọ́ karùn-ún

Bakan naa ni asofin agba tẹlẹ naa wa koro oju si bi ijọba apapọ se buwọ lu pe ki wọn fi biliọnu lọna meji ati ọgọrun miliọnu naira (N2.1m) se oju ọna kilomita kansoso lati Kano si Abuja.

A o ranti pe Dino Melaye lo n soju ẹkun idibo iwọ oorun Kogi nile asofin agba ilẹ wa tẹlẹ ko to di pe o fidi rẹmi ninu atundi ibo to waye.

Ẹ ràgà bo àwọn igbó ọba yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn àti ajínigbé - Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Ekiti state Government

Ijọba apapọ Naijiria ti ke sawọn ipinlẹ gbogbo ni Naijiria lati daabo bo awọn igbo ọba wọn nitori awọn ajinigbe.

Asẹ yii lo wa nitori bi awọn ọdaran darandaran ati ajinigbe se n lo igbo sba lati fori pamọ sisẹ laabi wọn.

Akọwe ijọba apapọ, Boss Mustapha lo pasẹ bẹẹ nibi ipade awọn akọwe ijọba to waye fun saa akọkọ lọdun yii nilu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Mustapha ni ijọba apapọ yoo ro awọn igbo ọba rẹ mẹtadinlogun to wa jakejado Naijiria lagbara lati gbaa lọwọ awọn afurasi ọdaran.

"Gbogbo wa la mọ pe a nilo awọn igbo ọba wa atawọn agbegbe min taa ya sọtọ fun iwulo isẹ ti wọn wa fun, paapaa fun pasi paarọ owo naira wa si tilẹ okeere.

Àkọlé fídíò,

Bed Wetting: Tolulope Joseph ní ò lé ní ogún ọdún tí òun fi tọ̀ sílé kí ìwòsàn tó dé

Bakan naa lawọn igbo ọba yii tun jẹ orisun ipese isẹ oojọ fawọn eeyan, to si tun maa n pese awọn eroja asaraloore fun ilẹ to lọra ati ipese ounjẹ lọpọ yanturu"

"Nitori naa, mo wa n pe awọn ijọba ipinlẹ nija lati bẹrẹ si ni gbe igbesẹ fun idaabo bo awọn igbo yii ti akoso rẹ wa nikawọ wọn."

"Torí ₦20, ọlọ́pàá yìnbọn fún mi lọ́rùn, n kò sì le b'óbìnrin lòpọ̀ mọ́ tàbí bímọ''

Oríṣun àwòrán, Reuters

A ṣe agba adura ni awọn Yoruba maa n gba pe a o ni rin lọjọ ebi n pọna.

Ọkunrin kan ẹni ọdun marunlelogoji, Olasunkanmi Fagbemi ti ṣalaye fun igbimọ to n gbẹjọ iwa ọdaran ọlọpaa nipa bi ibọn ọlọpaa ṣe tun un da, ti ko si le fun obinrin loyun lati igba naa.

Fagbemi ni oun n rinrin ajo lọ si ilu Ibadan lọjọ kejidinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2010, lawọn ọlọpaa kan da ọkọ ero ti oun wọ duro.

''Awakọ ero ti mo wa ninu rẹ fun awọn ọlọpaa naa ni ọgọrun un naira, lẹyin naa lawọn ọlọpaa ni ki o paaki sẹgbẹ daadaa, ko le gba ṣenji rẹ.

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Awakọ naa bọ silẹ ninu ọkọ lati gba ọgọrin naira ṣenji rẹ, nibi ti a ti n duro ninu ọkọ ni ọlọpaa kan ti yinbọn sinu ọkọ ti mo wa nibẹ.

"Ibọn naa ba mi lọrun, ọta ibọn ọhun tun lọ sinu egungun ẹyin mi.

Awọn ọlọpaa naa fẹsẹ fẹẹ lẹyin ti wọn ri ohun to ṣẹlẹ,'' Fagbemi ṣalaye.

Fagbemi ni awakọ ero naa lo gbe oun lọ si ile iwosan UCH niluu Ibadan nibi ti wọn ti ṣiṣẹ abẹ foun lati yọ ọta ibọn ninu eegun ẹyin oun lẹyin ọjọ kẹrin.

Àkọlé fídíò,

Adebunmi Adeyeye: Mo jẹ gbèsè gbọ́múléláńtà, ìdí iṣẹ́ kabúkabú ni mo ti ri san

''Mo ti kọ iwe ipẹjọ laimoye igba si awọn alaṣẹ atawọn oriṣiiriṣii ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, amọ wọn o ṣe nkankan lori ọrọ naa lati bi ọdun mẹwaa sẹyin bayii,'' Fagbemi lo sọ bẹẹ.

Fagbemi ni nkan ko rọrun fun oun mọ lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye nitori oun ti naa ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu lati tọju ara oun.

Koda, o ni oun ti rinrin ajo lọ si orilẹede India fun itọju ara oun.

Bakan naa ni Fagbemi sọ pe oun ti ta dukia ati ohun ini oun lori ati tọju ara oun.

Àkọlé fídíò,

Akomolede àti Asa: Mọ̀ si nípa àṣà ìsọmọlórúkọ́ nílẹ̀ Yorùbá àti ìtumọ̀ orúkọ̀ fún ìkókó

''Mo n gbero lati gbeyawo nigba ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si mi, wọn si ti sọ fun mi nile iwosan pe n ko le ba obinrin sun loyun tori ailera mi ayafi nipasẹ IVF loku,'' Fagbemi lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, alaga igbimọ oluwadii naa, Adajọ Solomon Olugbemi sọ pe igbimọ ọhun yoo kọ lẹta si ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, lati mu ẹri to daju wa pe otitọ ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.