Iskilu Wakili: Wakili àtàwọn méjì míì dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn, ìjínigbé àti olè kàn wọ́n

Iskilu Wakili

Oríṣun àwòrán, Facebook/OPC Diary

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fẹsun ipaniyan, ijinigbe ati ẹsun ole kan Fulani darandaran, Iskilu Abdullahi Wakili ti ọpọ sọ pe o da agbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo ru.

Ileẹjọ majisireeti to wa ni agbegbe Iyaganku niluu Ibadan lọjọ Iṣẹgun paṣẹ pe ki wọn ju Wakili ati ọmọkunrin rẹ meji, Samaila, 27 ati Aliyu Manu si atimọle.

Ẹsun onikoko mẹfa ni ileeṣẹ ọlọpaa fi kan Wakili atawọn ọmọ rẹ mejeeji.

Adajọ Majisireeti, Emmanuel Idowu ko gbọ ẹbẹ ti awọn afurasi naa n bẹ pe ileẹjọ Majisireeti ko lagbara lati ṣe igbẹjọ ọhun.

Adajọ paṣẹ rara lai beṣu bẹgba pe ki wọn gbe wọn ju si atimọle.

Adajọ sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹtadinlogun oṣu karun un ọdun 2021 yii.

Laipẹ yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mu Wakili lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo ti wọn si le awọn ọlọpaa lọwọ.