Seyi Makinde: Tí aráàlú bá kọ̀ mí bíi gómìnà, ẹ̀rù kò bà mí láti fipò sílẹ̀

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti kede pe ko le tu iru kan lara oun, ti oun ba kuna lati bori ibo fun saa keji.

Makinde lo ti kuna fun igba mẹta ọtọọtọ to tiraka lati di ibo gomina ipinlẹ Oyo eyi to waye lọdun 2007, 2011 ati 2015.

Gomina Makinde lo sisọ loju ọrọ yii nibi ipade awọn alẹnulọrọ lori eto aabo ilẹ Yoruba to waye ni gbọngan Mapo nilu Ibadan lọjọru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O tun fikun pe oun setan lati kuro lori aleefa tawọn araalu ba ni ki oun maa lọ, ru ko si ba oun lati fi ipo gomina silẹ.

"Ti awọn eeyan ipinlẹ Oyo ba ni ki n kuro ni ọọfisi gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo, n ko ni ro ni ẹẹmeji, ki n to kuro nitori ojoojumọ ni mo n gbe baagi mi lọ si ọọfisi lati ile."

Gani Adams ati Seyi Makinde n ki ara wọn pẹlu ẹyin ọwọ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Bakan naa ni gomina Makinde ni oun ko ni baba isalẹ ninu oselu, Ọlọrun si lo sọ oun di gomina, kii se ẹda alaaye kankan.

"Ọlọrun nikan ni mo bẹru, n ko bẹru ẹda alaaye kankan, ko si si bi ẹda kan se ni agbara to, emi ko le e bẹru rẹ.

Mo dije fun ipo gomina lọdun 2007,2011 ati 2015, ti mo si ja kulẹ amọ nigba ti Ọlọrun ni akoko to lati sọ mi di gomina, o gbe mi de ipo naa."

Makinde ni oun ko ni abẹrẹ ni ọọfisi ti oun le boju wo lẹyin, ti ilọ ba ti ya, oun ti setan."

O fikun pe ijọba oun ti n pese aabo to peye lati daabo bo ẹmi ati dukia, ti ijọba oun yoo si tun se amulo awọn ara ita lẹka eto aabo rẹ.

Àkọlé fídíò,

Farmers Herders Crisis: Rẹ́rẹ́ rún, ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò lágbègbè Ariwa Yewa

"Nitori ipo ti mo wa, awọn ohun ti mo n ri, ẹyin ko le ri i, mo si n seleri pe ma maa se ipinnu nibamu pẹlu ifẹ araalu ni."

O wa sisọ loju rẹ pe nibi ipade eto aabo to kọja, oun da aawọ silẹ nitori pe eto aabo to mẹhẹ ti kọja ka maa fi ẹnu pa a lasan.

O ni awọn eeyan ti ko ba si lara awọn osisẹ ikọ alaabo Amotekun le lọ di ara ikọ ọdẹ ibilẹ Soludero tabi Fijilante gẹgẹ bi ara ọna lati fi ara wọn silẹ fun isẹ aabo ilu.

Àwọn agbébọn jí èèyàn méjì gbé ní ibùdó tí wọ́n tí ń fọ́ òkúta ní Ibadan

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Saaju la ti sọ fun yin pe awọn eeyan meji ọtọọtọ ni awọn agbebọn ji gbe l'ọjọ Aje ni ibudo ti wọn ti n fọ okuta kan to n bẹ nilu Ibadan.

Ọkan ninu awọn eeyan meji naa jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ abanikọle, RCC ti ẹnikeji si jẹ oṣiṣẹ ile ifowopamọ Polaris.

Ijinigbe naa ṣẹlẹ lasiko ti awọn agbebọn yawọ ibudo ti wọn ti n fọ okuta(Binu Quarry) to n bẹ ni ilu Dalli lopopona Ibadan si Ijẹbu-Ode lati gbe awọn eeyan meji naa.

Iroyin fi idi ẹ mulẹ wi pe wọn ti fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa agbegbe Idi Ayunrẹ leti nilu Ibadan.

Ijinigbe yii waye lẹyin oṣu diẹ ti awọn agbebọn yawọ ibudo ti wọn ti n fọ okuta kan ni agbegbe ijọba ibilẹ Akinyẹle, ti wọn si ji awọn oṣiṣẹ kan gbe lọ.

Alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Arakunrin Olugbenga Fadeyi fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

L'ọjọ Iṣẹgun ni Fadeyi ṣe alaye wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n sa gbogbo ipa lati ri i daju wi pe awọn eeyan naa gba ominira.