Gani Adams: Gbogbo gómìnà Yorùbá ni mo kọ̀wé sí láti bá ṣèpàdé

Aworan Iba Gani Adams ati Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

Ni itẹsiwaju ọna ati wa ojutu si awọn ipenija to n koju ilẹ Yoruba, Aarẹ Ọna Kakanfo Gani Adams ati Gomina Seyi Makinde ti dijọ ṣepade pọ nilu Ibadan.

Ipade yi ti wọn ṣe ni bonkẹlẹ la gbọ pe o da lori ọrọ aabo ati ọrọ aje ilẹ kaarọ o jiire.

Atẹjade lati ọdọ agbẹnusọ feto iroyin fun gomina Seyi Makinde, Ọgbẹni Taiwo Adisa sọ pe aarẹ Gani Adams lo kọwe si gbogbo awọn Gomina ipinlẹ Yoruba lati beere fun ipade lori ọrọ aje ati aabo.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gani Adams ninu ọrọ rẹ si ni ''Inu mi si dun pe wọn jẹ mi ni o''

Iba tẹsiwaju pe ''mo ṣepade pẹlu Gomina Ekiti ni ọjọ meji sẹyin, nibayi mo n ṣe ipade pẹlu Gomina Oyo''

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

O ni o ṣe pataki kawọn fikunlukun lori ọrọ iṣẹ agbẹ ati pe, awọn Gomina mejeeji ti sọ ọna tawọn yoo fi mu idagbasoke ba iṣẹ agbẹ, paapa fawọn aladani.

''Mo fẹ fi da wọn loju pe awa naa yoo kopa tiwa lati ri pe a mọ awọn to fẹ dowo pọ pẹlu wọn wa''

Iba Gani Adams tun fikun ọrọ rẹ pe, ati awọn ati ijọba Oyo, ibi kanna lawọn jijọ n foju sun lori mimu alaafia ba ara ilu.

Àkọlé fídíò,

Ogbomoso Quitdruplets: Ọ̀kan nínú àwọn ìbarùn-ún jáde láyé lọ́jọ́ karùn-ún

O ni pẹlu ibi ti ọrọ de yii, awọn ọmọ Yoruba ko gbọdọ sun asunpiye, o si yẹ ki wọn pawọpọ lori ọrọ aabo ilẹ wọn eyi to ni ojuṣe gbogbo ọmọ Yoruba nii ṣe.