Ogbomoso Quintuplets: Ọ̀kan nínú àwọn ìbarùn-ún jáde láyé lọ́jọ́ karùn-ún

Ogbomoso Quintuplets: Ọ̀kan nínú àwọn ìbarùn-ún jáde láyé lọ́jọ́ karùn-ún

Isẹ Oluwa, awamaridi ni nitori ọna rẹ, ko si ẹni to ye tabi ẹni to mọ, bo si se wu Oluwa lo n se ọla.

Nibi ti awọn eeyan kan ti n fi ojoojumọ sunkun si Ọlọrun lọrun fun ẹbun ọmọ, ni Ọba Oke ti fi ibarun ta idile Idowu ati Funmilayo Oluwadara lọrẹ.

Awọn tọkọ-taya yii lo ti kọkọ bi ọmọ marun tẹlẹ, ki oore ibarun tun to wọle de, ti iya wọn si bi wọn wọọrọwọ lai se isẹ abẹ.

Nigba ti tọkọtaya Oluwadara n ba BBC Yoruba sọrọ nilu Ogbomoso, wọn ni ibẹta ni dokita kọkọ ni oun yoo bi, ki ibarun to wa, ọkunrin kan ati obinrin mẹrin.

Ni ọjọ karun tawọn ọms naa dele aye la gbọ pe ọkunrin kan soso laarin awọn ibarun naa jade laye.

Tọkọ-taya naa ti wọn jẹ alagbaro, ni ko ti wa ri owo ile iwosan san lati maa lọ sile, bi o tilk jẹ pe dokita ti yọnda wọn.

Wọn wa n bẹbẹ fun iranwọ owo lọdọ awọn ẹlẹyinju aanu, lati sanwo ile iwosan ati fun itọju awọn ọmọ mẹrin to ku pẹlu awọn ẹgbọn wọn nitori ọna abayọ.