Sunday Igboho: Afurasí mẹ́rin tí wọn ló ń dọdẹ Majasọla nílé rẹ̀ ní Soka, bọ́ sí àhàmọ ọlọ́pàá

Awọn afurasi Sọja ti Igboho mu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Koiki Media

Ilumọọka ajafẹtọ ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho ni ọwọ rẹ ti tẹ awọn eeyan meji ti wọn wọ asọ ologun ati eeyan meji mii ti wọn jẹ araalu.

Sunday Igboho ni ọwọ oun tẹ awọn eeyan mẹrẹẹrin naa lori ẹsun pe wọn n sọ oun lọwọ lẹsẹ kiri ni deede aago kan ọsan ọjọ Ẹti.

Fidio kan ti agbẹnusọ fun Sunday Igboho, Olayomi Koiki fisita lasiko ti isẹlẹ naa n waye loju opo Facebook rẹ, ni isẹlẹ ti foju han.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu fidio naa, ni awọn eeyan mẹrẹẹrin naa ti kunlẹ, tawọn alatilẹyin Igboho si n da 'sẹria' fun wọn.

Amọ awọn afurasi ologun naa ni awọn n gun ọkada lọ si ibi kan ti awọn n lọ ni, awọn ko si mọ ibẹ, nigba ti awọn ri awọn araalu meji naa ti wọn n ja, ti awọn si duro lati la wọn.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Koiki Media

Awọn eeyan ti irisi wọn naa jọ ti ologun naa ni Igboho wa fẹsun kan pe ijọba lo ran wọn lati maa dọdẹ ile oun to wa ni adugbo Soka nilu Ibadan.

Bakan naa lo ni igbesẹ ijọba naa lo seese ko wa lati gbe oun sahamọ nitori ikede ti oun se ni Ọjọru pe ilẹ Yoruba kii se ara Naijiria mọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Koiki Media

Igboho wa se apejuwe awọn eeyan meji to jẹ araalu laarin awọn afurasi mẹrẹẹrin bii ọmọ ale Yoruba.

O ni ti kii ba se bẹẹ, wọn ko ba ti ran wọn lati wa maa ṣọ oun kiri, ti oun si n seleri lati pari wọn.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Koiki Media

"Ẹ́ lọ sọfun ẹni to ran yin si mi pe o kere gan, tẹ ba tiẹ wa fẹ se were, kii se ọdọ mi lo yẹ kẹ se si. Gbogbo ẹyin ọmọ ale Yoruba yii, ni maa pari yin.

Ti kii ba se ohun ti mo gbe lọwọ ni, ati ki ilẹ Yoruba ma bajẹ, iru yin kere si mi."

Amọ iroyin kan ni Sunday Igboho ni ki awọn eeyan oun mase fiya jẹ awọn afurasi naa, to si ti fa wọn le ọlọpaa lọwọ.

Ninu fidio naa ni Olayomi Koiki ti salaye pe, idunkooko si Sunday Igboho ti n lagbara bayii.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Koiki Media

O wa n beere pe ki ni awọn ologun n wa lori ọkada ni agbegbe Soka, nigba to jẹ pe Alakia ni ibudo ologun wọn wa.

O wa ke si ijọba apapọ lati sọra se nipa irufẹ awọn eeyan to n ran lati maa sọ ile Sunday Igboho.

Wayi o, BBC Yoruba gbiyanju lati ba agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi sọrọ lati fidi isẹlẹ yii mulẹ, amọ ko gbe ipe rẹ lori aago