Kaduna killings: Gómìnà El-Rufai kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí àwọn tó kú

Awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Awọn janduku agbebọn tun ti ṣekupa eeyan mẹtala ninu ikọlu mii to waye ni ijọba ibilẹ Zangon Kataf, Kauru ati Chikun nipinlẹ Kaduna.

Kọmiṣọna fun ọrọ abẹle ati ọrọ aabo nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan ṣalaye pe, ileeṣẹ ologun ti fidi ọrọ naa mulẹ.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ, awọn janduku naa kọlu Irmiya Godwin ati aburo rẹ, lẹyin ti wọn de lati oko wọn to wa ni ijọba ibilẹ Zango Kataf.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn ṣekupa Godwin, amọ aburo rẹ mori bọ, o si sa asala fun ẹmi rẹ.

Bakan naa lawọn janduku ọhun tun kọlu abule Kizachi ni ijọba ibilẹ Kauru nibi ti wọn ti pa eeyan mẹwaa, ti eeyan mẹrin si farapa.

Oríṣun àwòrán, Andrwe Akyalla

Ile mẹrindinlọgọta ati alupupu mẹrindinlogun ni wọn dana sun, koda wọn tun sọ ina si aba ti awọn eeyan abule naa ko ere oko si.

Orukọ awọn tawọn janduku ọhun pa gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ ni Esther Bulus ati ọmọ rẹ ti ko ju ọdun kan lọ, Maria Bulus, Lami Bulus, Aliyu Bulus.

Awọn yoku ni Monday Joseph, Geje Abuba, Wakili Filibus, Yakubu Ali, Dije Waziri ati Joseph Ibrahim.

Cecilia Aku, Yakubu Idi, Godiya Saleh, Moses Adamu ni awọn eeyan to ṣeeṣe ninu ikọlu naa, wọn n gba itọju lọwọ nile iwosan bayii.

Àkọlé fídíò,

Ogbomoso Quitdruplets: Ọ̀kan nínú àwọn ìbarùn-ún jáde láyé lọ́jọ́ karùn-ún

Bakan naa, awọn agbebọn ṣekupa Duza Bamaiyi ni abule Masaka ni ijọba ibilẹ Chikun, nibi ti eeyan meji ti farapa.

Wọn tun pa Zakka Pada ni abule Kurmin ni ijọba ibilẹ Chikun kan naa.

Ẹwẹ, gomina Nasir El-Rufai ti kẹdun pẹlu awọn ẹbi oloogbe, o si gbadura pe ki Eleduwa tẹ wọn si afẹfẹ rere.