Nyesom Wike: Lẹ́yìn Ọlọ́run, èmi ló tún kàn fún Rotimi Amaechi torí èmi ló sọ ọ́ di gómìnà

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rivers State Government
Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti sọ pe, oun ko le fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ laelae lọ darapọ mọ APC.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC, Wike sọ pe kikuro ninu ẹgbẹ PDP dabi ẹni pe oun ni fi ẹgbẹ to ni arun iba silẹ, lati lọ si APC to ni arun jẹjẹrẹ.
Wike ni ohunkohun ti kii ba ṣẹlẹ, mimi kan ko le mi oun ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìyàtọ tàbí àfiwé wo ló wà láàrin Sunday Igboho, Nnamdi Kanu àti Asari Dokubo?
- Ọwọ́ Sunday Igboho tẹ ‘Sọ́jà’ àti aráàlú mẹ́rin tó ní wọn ń dọdẹ òun
- Agbébọn pa èèyàn 13, ṣun ile 56, ọkadà 16 ní Kaduna
- Gani Adams àti Seyi Makinde ṣèpàdé, àbọ̀ wọn rèé
- Ẹyọ kan lára agbára tí mo ní, ni mo lò láti mú Wakili - Gani Adams
- Sunday Igboho ṣẹ̀ sí òfin ète ìdìtẹ̀ gbàjọba, ó sì le fojú winá òfin - Amofin
- Bí ọlọ́pàá bá tó bẹ́ẹ̀, kó dá wa lọ́nà, Yoruba kìí ṣe ara Naijiria mọ́ - Sunday Igboho
Gomina Wike tun fesi lori ọrọ ti gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, Rotimi Amaechi sọ pe oṣiṣẹ oun nii ṣe tẹlẹ.
Wike ni ''emi lo ku lẹyin Ọlọrun fun Amaechi, nitori emi ni Ọlọrun lo fun un lati wọle gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Rivers.
Ogbomoso Quitdruplets: Ọ̀kan nínú àwọn ìbarùn-ún jáde láyé lọ́jọ́ karùn-ún
Emi naa ni Amaechi wa n sọ pe oṣiṣẹ rẹ ni mo jẹ tẹlẹ, mo ni fọnran aworan ti Amaechi ti sọ ni ṣọọṣi pe, lẹyin Ọlọrun, emi lo tun kan fun un.''
Gomina Wike ni oun gan an ni oun sọ Amaechi di gomina Rivers lai si ani ani kankan nibẹ.
''O ni oṣiṣẹ oun ni mo jẹ, ṣugbọn emi naa ni mo n fi ẹyin rẹ gbalẹ lagbo oṣelu.
Ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu rẹ APC fidi rẹmi ninu ibo aarẹ ati ibo ile igbimọ aṣofin l'Abuja.
Bed Wetting: Tolulope Joseph ní ò lé ní ogún ọdún tí òun fi tọ̀ sílé kí ìwòsàn tó dé
O tun sọ pe, n ko le se gomina laelae, amọ oju rẹ naa lo ṣe ti mo fi wọle ibo gomina lẹẹmeji ọtọtọ.
Emi funra mi ni mo sọ pe ipo adari awọn oṣiṣẹ ni mo fẹ nigba ti Amaechi jẹ gomina ipinlẹ Rivers,'' Wike lo sọ bẹẹ.
- Ẹ gbọ́ ná, kí ló lè mú kí àfín 114 di àwátì?
- Afurasí olóṣèlú tí ọlọ́pàá mú lórí ikú ọmọ mi, ló jẹ́ alátakò rẹ̀ nínú PDP - Baba Aborode
- Jimoh Odutola, akọni oníṣòwò tí kò kàwé, àmọ́ táwọn Ààrẹ orílẹ̀-èdè ń ké sí láti wá dá iléesẹ́
- Akẹ́kọ̀ọ́ kò yọjú sílé ẹ̀kọ́ lẹ́yìn tí àwọn olùkọ́ padà sẹnu iṣẹ́ nílèèwẹ tí rògbòdìyàn Hijab ti wáyé n'Ilorin
Gomina ni ile ẹjọ ati igbimọ to n gbẹjọ ẹsun ṣiṣe owo ilu kumọ kumọ lo fidi rẹ mulẹ pe Amaechi jẹbi ẹsun iwa ajẹbanu.
Amaechi lo ta ileeṣẹ afẹfẹ gaasi ipinlẹ Rivers fun ọdunrun miliiọnu le mẹjọ owo dọla.