Báyìí lórí ṣé ko mi yọ lọ́wọ́ àwọn agbébọn - Gómìnà Samuel Ortom

Samuel Ortom

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gomina ipinlẹ Benue Samuel Ortom ti fidi ọrọ mulẹ pe lootọ lawọn agbebọn ṣe ikọlu si oun logunjọ oṣu Kẹta.

Gomina naa sọ pe awọn agbebọn ti wọn doju ija kọ awọn ẹsọ rẹ wọ aṣọ dudu ti wọn si to mẹẹdogun

O ni awọn agbebọn yi fẹ ran oun lọ si ọrun aremabọ ni nitori o to kilomita meji ti awọn fi sa fun wọn

Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni Ortom tu kẹkẹ ọrọ silẹ ṣapejuwe awọn agbebọn yi gẹgẹ bi darandaran to si ni bi awọn mẹẹdogun wọn ni wọn tọ ipasẹ oun de eti odo toun ti n fẹsẹ rin.

Gomina Ortom jẹ eeyan kan to n bẹnu atẹ lu ihuwasi awọn darandaran to jẹ ipenija aabo ni Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii.

Ṣaaju lo ti sọ fun BBC ninu ifọrọwerọ kan laipẹ yi pe awọn ẹgbẹ darandaran yi tako ofin ti oun ko si faramọ iṣesi wọn.

Bakan naa lo kesi ijọba lati fi iru ọwọ to fi mu awọn ẹgbẹ mii bi ti IPOB ati ESN ti ijọba ni awọn wọgile mu ẹgbẹ Miyetti Allah awọn darandaran.

Àkọlé fídíò,

Taooma: Ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú àwọn òbí mi yàtọ̀ sí bí mó ṣé n polongo nínú fídíò mi