Ekiti by-election: INEC ní èèyàn mẹ́ta kú, ọlọ́pàá ní kò rí bẹ́ẹ̀, PDP fapajánú

Aworan Gomina Kayode Fayemi ati Ayodele Fayose

Oríṣun àwòrán, Facebook/KayodeFayemi/Ayodele Fayose

Iwọ lo lẹbi emi kọ lorin tawọn alẹnulọrọ paapa ninu ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP n fi bẹnu lori laasigbo to waye nibi idibo atundi ijọba ibilẹ to waye ni Ekiti.

Lọjọ Abamẹta niṣe ni ajọ eleto idibo INEC wọgile eto idibo naa to si sọ pe eeyan mẹta ku ti agunbanirọ kan ati ọlọpaa kan naa si farapa.

Ayodele Fayose to jẹ eekan ninu ẹgbẹ PDP sọ pe iṣẹlẹ yi yoo maa ja awọn aṣebi ninu nitori pe wọn ṣeku pa awọn eeyan wọn nitori idibo sile aṣofin ipinlẹ lasan.

Ninu ọrọ to fi soju opo rẹ ni Twitter, Fayose ṣalaye pe ohun to ṣẹlẹ ni Omuo Ekiti ko ju pe ijọba fun ara rẹ n ṣagbatẹru iwa agbesunmọmi lati fi doju ija kọ ara ilu.

O ni nigba ti wọn ri pe ewe ti fẹ sunko ti ara ilu o si fẹran wọn mọ ni wọn fi n dunkoko mọ ara ilu.

''Pipa awọn alaiṣẹ nitori wọọdu marun un ninu idibo atundi ijọba ibilẹ jẹ iwa to buru jai to si doju ti ni.

''Mo ro pe a ti kọja iru iwa ẹranko yi ni Ekiti paapa lọwọ yi ti ijọba n koju ipenija aabo eleyi ti wọn ko rojutu si''

Bi Fayose ṣe n tutọ soke foju gba lawọn ajọ eleto idibo Naijiria INEC naa n sọ pe awọn ti so eto idibo yi rọ.

Wọn ni ti awọn ba tẹsiwaju lati ṣeto idibo yi yoo da bi gba pe awọn n gbe lẹyin iwa ibajẹ ni.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Inec

Festus Okoye to jẹ Kọmisana ajọ naa to n mojuto ọrọ idanilẹ oludibo to buwọlu atẹjade yi ni awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ yi.

Ọlọpaa ni ko si ẹnikankan to ku

Nigba ti iroyin yi kọkọ lu sita ti BBC Yoruba kan si alukoro ọlọpaa Ekiti ASP Abutu Sunday sọ pe ko si ẹni to kú.

O sọ ninu atẹjade to fi ranṣẹ si BBC pe eeyan mẹfa lo kan farapa nibi iṣẹlẹ naa.

Lara wọn si ni ọlọpaa meji, agunbanirọ kan, ati araalu mẹta wa.

O ṣalaye pe gbogbo wọn ti n gba itọju nileewosan gbogboogbo to wa ni Ikọle-Ekiti.

Bakan naa lo sọ pe ọwọ ti tẹ afurasi mẹta lori iṣẹlẹ naa.

O ni "Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ekiti n fi da awọn araalu loju pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ri daju pe awọn to lọwọ si iṣẹlẹ naa foju wina ofin. O si tun rọ gbogbo eniyan lati fi ọkan balẹ."

Fayemi ba mọlẹbi kẹdun, o ni awọn to huiwa yi ko ni lọ laijiya

Ẹwẹ Gomina Kayode Fayemi ninu ọrọ tirẹ nipa iṣẹlẹ yi sọ pe ijọba yoo ri pe gbogbo awọn to mọ si ipaniyan yi yoo foju wina ofin.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ Yinka Oyebode fi sita, o ni ijọba ba mọlẹbi awọn to farapa ati awọn to ku kẹdun.

Asofin agba to n ṣoju Ekiti ni ẹkun Guusu ipinlẹ naa Senator Biodun Olujimi sọ pe ori lo ko oun yọ nibi iṣẹlẹ yi.

Olujimi to jẹ ọmọ Omuo Ekiti sọ pe ọpẹlọpẹ awọn alatilẹyin loun fi moribọ nigba tawọn agbebọn ṣigun bo awọn oludibo ni ibudo idibo rẹ to wa ni ward 7,Unit 007.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Biodun Olujimi

Atundi ibo yi to waye lọjọ Abamẹta jẹ eleyi ti INEC ṣeto lati dibo yan ẹlomii ti yoo gba ipo aṣofin oloogbe Juwa Adegbuyi ti ẹgbẹ oṣelu APC to di ipo naa mu tẹlẹ.

Ko ju wakati meji ti wọn bẹrẹ idibo tawọn agbegbọn ṣigun de tọrọ si di boo lọ o yago mi ni Omuo.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju botilẹ jẹ wi pe awọn ẹgbẹ oṣelu PDP n naka aleebu si ẹgbẹ APC pe awọn janduku wọn lo wa da idibo naa ru.