Kabiyesi Kidnapped: Olorí Oba Imope ní ẹbí kábíyèsí kò ní N200M tíáwọ́n ajínigbé ń béèrè

Oba Tajudeen Omotayo

Oríṣun àwòrán, Oba Tajudeen Omotayo

Oju Ọlọrun laa n wo nitori ipa wa ko ka iye owo ti wọn ni ka mu wa kawọn to le tu Kabiyesi silẹ.

Ọrọ ti Olori Omotayo Adesola fọ lesi ree nigba ti akọroyin BBC Yoruba tun pe wọn lori ago lati mọ boya wọn gburo Kabiyesi.

Lati ọjọ Abamẹta lawọn ajinigbepawo ti gbe Kabiiyesi ti wọn si ni ki mọlẹbi wọn mu igba miliọnu Naira wa.

''Wọn pe wa laarọ yi ti wọn si ni ṣe a ti ri owo naa. Mo sọ fun wọn pe ko tii pe''

Olori ni iporuru ọkan ti de ba awọn mọlẹbi bayi nitori awọn ko mọ iru ipo ti Kabiyesi wa.

Nigba taa beere lọwọ wọn boya wọn ti gburo awọn ọlọpaa lori iṣẹlẹ yi, wọn ni awọn ọlọpaa wa kaakiri ilu ṣugbọn awọn ko le sọ boya wọn ti ri awọn ajinigbe naa.

Nigba ti BBC Yoruba ba agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun Abimbola Oyeyemi sọrọ kẹyin, o ni awọn ikọ ọtẹlẹmuye n gbiyanju lati ṣawari Kabiyesi

Lẹnu lọọlọ yi, iwa ijinigbe ti wa gbilẹ ni Naijiria ti ko si fẹ yọ apa kankan lorileede naa silẹ.

A ò ní N200M tí Ajinigbé ń bèrè fún o, ẹ gbá wá o! Olorí Ọba Imope tí wọ́n jígbé da ọ̀rọ̀ bolẹ̀ fún BBC

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Olori Omotayo Adesola, Oba Tajudeen Omotayo ilu Imope tawọn afurasi ajinigbe Fulani gbe lọjọ Abamẹta ti rawọ ẹbẹ sawọn ajinigbe naa pe ki wọn fiye denu, ki wọn tu kabiyesi silẹ.

Olori Adesola ni ẹbi kabiyesi ko ni igba miliọnu naira tawọn ajinigbepawo n beere fun ki wọn to le tu kabiyesi silẹ.

Olori ṣalaye fun BBC Yoruba pe awọn ajinigbe naa fi foonu kabiyesi pe lati ba ẹbi sọrọ.

''Awọn ajinigbe naa n sọ ede Pidgin oyinbo pẹlu kabiyesi, ohun ti kabiyesi sọ ni pe ki a lọ wa owo nla wa kawọn ajinigbe le fi wọn silẹ.

Nigba ti mo beere pe elo ni ki a lọ wa, kabiyesi ni bii igba miliọnu naira ni o,'' Olori lo sọ bẹẹ.

Olori ṣalaye pe ''a o lowo kankan o, ki wọn ṣaanu wa, ati pe awọn ọmọ kabiyesi ṣi kere.''

''Awọn ọlọpaa sọ fun wa pe awọn ajinigbe naa ṣi wa pẹlu kabiyesi ninu igbo lagbegbe Imope, wọn o tii kuro lagbegbe.

Koda awọn ajinigbe ọhun yinbọn mọ ọkan lara awọn ọlọde to bẹ sinu igbo ti wọn gbe kabiyesi lọ lẹsẹ.

Ẹni naa wa nile iwosan nibi to ti n gba itọju lọwọ bayii,'' Olori ṣalaye.

Olori naa tun ke pe ijọba ipinlẹ Ogun lati ṣe iranwọ lori ati gba ominira lọwọ awọn ajinigbe.

Bakan naa. ọkan lara ẹbi kabiyesi, Jide Abiodun Adebanjo naa rawọn ẹbẹ sawọn janduku ajinigbe naa wi pe ki wọn fi kabiyesi silẹ.

Ọgbẹni Adebanjo ni ko si ibi ti ẹbi kabiyesi ti fẹ ri ọgọrun tabi igba miliọnu naira.

Ọgbẹni Adebanjo ni ẹbẹ naa ni ẹbi kabiyesi n bẹ pe ki awọn ajinigbe ọhun mu owo naa walẹ.

Ajínigbé jí Oba Imope gbé ní Ogun, wọ́n pa olódẹ tó fẹ dóòlà Kábíyèsí, N200M ni wọ́n ń béèrè

Awọn ajinigbepawo ti tun ṣoro pẹlu bi wọn ti ṣe ji ọba alade mii gbe nilẹ Yoruba.

Lọjọ Abamẹta ni wọn ji Oba Tajudeen Omotayo, Oba tilẹ Imope gbe lagbegbe ijẹbu Igbo ni ipinlẹ Ogun.

Ẹkunrẹrẹ iroyin nipa iṣẹlẹ naa ko tii tẹwa lọwọ ṣugbọn awọn to sunmọ oriade naa ni nkan bi ago mọkanla lo gbera kuro laafin la ti lọ si Ijebu Ode ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.

Awọn ajinigbepawo naa la gbọ pe wọn da Ori Ade ọhun lọna ni agbegbe Okeeri ni Imope ti wọn si ji Kabiyesi gbe lọ.

Wọn fi ọkọ ti Ọba gbe jade silẹ loju ọna.

Mọlẹbi Oba ọhun kan to ba BBC sọrọ ni lẹyin igba tawọn ajinigbe naa gbe ọba sa lọ, wọn kan si iyawo rẹ lati mu igba miliọnu Naira wa lowo idoola.

Lẹyin idunadura wọn lawọn yoo gba ọgọrun miliọnu Naira.

Àkọlé fídíò,

Gẹ́gẹ́ bí àṣà, mo ti mọ̀ tipẹ́ pé mo máa jẹ ọba Akinghare II - Oba Oloyede

Bẹẹ la tun gbọ pe awọn ọlọde kan yabo igbo to yi ilu naa ka lati doola Ọba.

Ababọ rẹ nipe awọn ajinigbe yi yinbọn pa ọkan lara awọn ọdẹ ọhun.

Titi di ba ṣe n ṣakojọ iroyin yi, wọn ko ti ri ọba naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun Ararakunrin Abimbola Oyeyemi fidi iṣẹlẹ yi mulẹ fun BBC to si ni ikọ ọtẹlẹ́muyẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa.

Nipa ti pe awọn ajinigbe yi pa ọlọde kan Oyeyemi ni oun ko mọ si.

Bẹẹ naa lo sọ pe awọmn ko ti gburo pe awọn ajinigbe naa beere owo idoola lọdọ mọlẹbi.