Sunday Igboho: Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà dá èsì padà sí Sunday Igboho tó kó ọmọ ogun sí àhámọ́

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Defence Headquatres,Sunday Igboho

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijniria ti da esi pada si iwa ti gbajugbaja ajafẹtọ ẹya Yoruba, Sunday Adeyemo ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho hu si awọn ọmọ ogun kan.

Wọn fi atẹjade kan sita eyi ti adele oludari ileeṣẹ ologun alaabo, Brigadier General BE Onyeuko fọwọ si pe awọn ri fidio to gbalẹ kan lori ayelujara ati kaakiri awọn ileeṣẹ iroyin to ni Sunday Igboho mu awọn Sọja si ahamọ torii pe o ni wn n ṣe alami lori oun.

Ṣaaju ni Sunday Igboho ni ọwọ oun tẹ awọn eeyan mẹrẹẹrin naa lori ẹsun pe wọn n sọ oun lọwọ lẹsẹ kiri ni deede aago kan ọsan ọjọ Ẹti.

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Àkọlé fídíò,

Ogbomoso Quitdruplets: Ọ̀kan nínú àwọn ìbarùn-ún jáde láyé lọ́jọ́ karùn-ún

Afurasi Sọja ni ileeṣẹ ologun pe awọn ọmọ ogun ti ọwọ sunday Igboho tẹ yii ninu atẹjade wọn leyi ti wọn ṣalaye pe ninu fidio naa, wọn fi ẹsun kan wọn pe ijọba lo ran wọn lati lọ ṣe alami layika ile Sunday Igboho to wa ni agbegbe Soka ni Ibadan, ipinlẹ Oyo.

Bakan naa, wọn ṣapejuwe sunday Igboho gẹgẹ bii "ẹni to n pe ara rẹ ni ajijagbara ilẹ Yoruba" pe o fẹsun kan pe gbogbo ohun tawọn afurasi Sọja naa n ṣe ni atilẹyin ijọba apapọ eyi to jẹ nitori ọrọ rẹ to sọ pe iran Yoruba kii ṣe ara orilẹede Naijiria mọ.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Defence Headquartres

Oríṣun àwòrán, Nigerian Defence Headquartres

Ẹwẹ, atẹjade naa sọ pe ileeṣẹ ologun ko raye biba Sunday Igboho tabi awọn isọngbe rẹ ṣe fa ki n fa ọrọ kankan ṣugbọn o kan ṣe pataki lati jẹ ki awọn eeyan mọ iha ti awọn kọ si iṣẹlẹ yii gangan.

Adele oludari ileeṣẹ ogun naa ni awọn fẹ fi hande pe ileeṣẹ ogun Naijiria mọ iṣẹ wọn de oju ami pẹlu oniruuru ipo to yẹ lati ri i pe aabo to daju wa ni orilẹede Naijiria tori naa ikọ ologun ko lee fi ara wọn wọlẹ

de bi pe iru Sunday Igboho to jẹ afurasi kaakiri ilu.

Bakan naa wọn jẹ ko di mimọ pe ileeṣẹ ologun ni ofin ti wọn n tẹle ninu ṣiṣe iṣẹ wọn ati to n tọ awọn oṣiṣẹ wọn sọna "torinaa ko ṣeeṣe ki ọmọ ogun to wa lẹnu iṣẹ to yẹ ki wọn maa ṣe lati hu iru iwa ti Sunday Igboho atawọn eeyan rẹ n fẹsun kan pe wọn hu".

Ṣé Sọjà wa lẹni tí Sunday Igboho gbámú ní tóòtọ?

Fun idi eyi ni ileeṣẹ ologun ṣe ni "ki alaye wa lee ye yin daadaa lori ọrọ yii lai ṣe iyemeji, "ibẹrẹ iwadi taa ṣe fihan pe ọkan lara afurasi sọja naa kii ṣe ọmọ ogun Naijiria, o kan dibọn bii ologun ni".

Ẹwẹ, wọn ni oṣoju mi koro ti awọn nigbagbọ ninu ẹ ti tu aṣiri fawọn pe awọn isọngbe Sunday Igboho gbá tẹle awọn kan lẹyin nigba ti ọkada to gbe ẹni to n dibọn ọhun ati ologun kan kọlu wọn.

Lẹsẹkẹsẹ ni wọn mu awọn mejeeji ti wọn si ko wọn lọ si "ile ti wọn pe ni ti sunday Igboho" ni Soka ṣaaju Toll gate Ibadan, nibẹ si ni wọn ti fi orukọ awn to n ṣe alami pe wọn".

Awọn ologun ni iwadii ṣi n tẹsiwaju labẹ akoso ileeṣẹ ogun oriilẹ ati ti oju ofurufu lati tu aṣiri ohun to ṣẹlẹ gangan lọjọ naa.

Ni wọn ba fi ikilọ sita pe ki awọn eeyan tabi ẹgbẹ jawọ ninu tita epo si aṣọ ala ileeṣẹ ologun Naijiria nipa wiwọ wọn lọna kan tabi omiran sinu awọn ọrọ pẹpẹpẹ ti ko kan wọn tori irinajo oṣelu ti wọn tori awọn ko ni fi aaye gba iru iwa bẹẹ rara ati rara. Bakan naa, wọn ni ẹnikẹni lee pin iroyin ti a kọ yii kaakiri awọn oju opo ayelujara wọn ki gbogbo agbaye le mọ.